"Inú mi dùn pé èmi ni obìnrin tó ya ‘tattoo’ sára jùlọ ni gbogbo àgbáyé"

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Obinrin to ya tattoo to pọ ju si ara rẹ lagbaye, Esperance Fuerzina, ti sọ pe ohun iwuri ni awọn aworan naa, to wa ni ara oun, jẹ fun oun.

Esperance Fuerzina ti gba ami ẹyẹ Guinness World Records gẹgẹ bii ẹni to ya aworan si ara rẹ julọ lagbaye.

Yatọ si aworan to ya si awọ ara rẹ, Esperance Fuerzina tun ya tattoo si ahọn ati erigi rẹ.

Ida 99.98% ara Esperance Fuerzina lo ti ya tattoo si, o si ni oun sẹsẹ bẹrẹ ni

Nigba to n sọrọ lori eredi to fi ya aworan to pọ to bẹẹ, Esperance Fuerzina ni “mo fẹran ki n maa ya nnkan si ara mi, eyii to jẹ awọn ohun iranti ti yoo maa tẹle mi kiri.”

Lọwọ yi, ida 99.98% ara obinrin naa lo ti ya tattoo si.

Bo tilẹ jẹ pe awọn kan le maa ri aworan naa pe o ti pọ ju, Fuerzina ti sọ pe oun ṣẹṣẹ bẹrẹ ni.

Wo fidio oke yii fun ẹkunrẹrẹ iroyin nipa tatoo ti ya Esperance Fuerzina sawọ ara rẹ.