You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Àwọn mọ̀lẹ́bí ọkùnri tí ọlọ́pàá ṣekúpa lásìkò ìwọ́de ìlú le bèrè ìdájọ́ òdodo
Awọn mọlẹbi ọkunrin ẹni ọdun mẹrinlelogun kan, Abubakar Adam Abdullahi, ti n bere fun idajọ ododo bayii leyin ti wọn ni ọlọpaa ṣekupa a lasiko iwọde ilu le to waye nipinlẹ Kaduna.
Ileeṣe ọlọpaa ti sọ pe oun ko mọ nnkankan nipa iku rẹ nigba ti agbẹnusọ gomina Kaduna ni oun ko gbọ nipa iku ọkunrin naa rara.
Amọ ṣa, ajọ Amnesty International ti sọ pe eeyan mẹta ni wọn ṣekupa lasiko iwọde naa, bo tilẹ jẹ pe ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria ko sọ ohunkohun nipa rẹ.
Nigba to n ba BBC sọrọ lorukọ mọlẹbi wọn, ibatan Abubakar, Ismail sọ pe ọlọpaa gangan lo yinbọn fun Abubakar ni igba aya, eyii to yọri si iku rẹ nilẹ iwosan Yusuf Dantsoho.
Ismail ni “idajọ ododo ni ohun ti a fẹ.”
Lati igba ti iwọde naa ti bẹrẹ, a gbọ pe ọlọpaa ti ṣekupa, o kere tan, eeyan meje, nigba ti wọn fi ṣikun ofin mu eeyan 700.
Ṣaaju ni ijọba Aarẹ Bola Tinubu ti kọkọ kilọ lodi si iwọde naa ṣugbọn awọn eeyan kọti ikun si ikilọ Aarẹ.
Abubakar ni abigbẹyin awọn ọmọ iya mẹrinla, ọdọ awọn obi rẹ lo si n gbe niluu Kaduna, iṣe aranṣọ lo si yan laayo.
Amọ ọwọngogo to gbode ni Naijiria lo mu ko darapọ mọ awọn oluwọde.
Ismail sọ pe “gẹgẹ bi aranṣọ, iye owo ti wọn n ta awọn ohun to fi n ranṣọ ti gbowo lori, bakan naa ni iye owo ounjẹ, owo ile ati bẹẹ bẹe lọ.”
Fidio bi Abubakar ṣe jade laye ṣafihan bi awọn ọdọ kan ṣe n pariwo le ọlọpaa lori ki wọn to fẹsẹ fẹ.
Ismail sọ pe ibi ti wọn ti ṣekupa Abubakara ko jina si ọọfisi gomina Uba Sani.
Awọn iroyin kan sọ pe Abubakar sọ fun awọn ọrẹ rẹ pe o ti rẹ oun, oun si fẹ maa pada sile, amọ lẹyin akoko diẹ ni ọlọpaa ṣina ibọn fun wọn.
Fidio iku rẹ ṣafihan bi ọdọkunrin naa ṣe ṣubu silẹ nigba ti ọlọpaa yinbọn fun.
Agbẹnusọ ijọba ipinlẹ naa sọ pe awọn ko gbagbọ pe ẹnikẹni ku lasiko iwọde ọhun nitori pe ohun ti ọlọpaa sọ niyẹn, amọ ọrọ ọlọpaa naa tako ọrọ ajo Amnesty International.
Wayi o, Ismail ti ṣeleri pe oun ko ni sinmi titi ti mọlẹbi oun yoo fi ri ifajọ ododo gba lori iku aburo oun.