Ìṣẹ̀ṣe Day: Emir Ilorin àti Wole Soyinka tahùn síra wọn

Emir ti ilu Ilorin, Ibrahim Sulu Gambari ati Ọgbọn Wole Soyinka ni wọn ti tahun si arawọn lori bi ọdun Isẹse ko se waye niluu Ilorin.

Soyinka, ẹni to kọwe si Emir ti Ilu Ilorin, to si bu ẹnu atẹlu bi wọn se wọgile sise ọdun Isese ti Yeye Osun fẹ gbe kalẹ.

Ninu iwe to fi ransẹ si Ọba alade naa, Soyinka ni o se ni laanu pe Ilu Ilorin ko fi aye gba awọn ẹlẹsin miiran, eyi to ni ko bojumu, to si tun ni ko tọna bi Emir se kede pe ki ọdun Isese naa maa waye.

"Itẹjuọmọniyan ni ki wọn ma fun eeyan ni anfani lati kopa ninu ẹsin tabi ajọdun to ba fẹ.

'"Ọdọdun ni ọdun Awẹ Ramadan n waye lorilẹede Naijiria, ti awọn eeyan si n kora wọn jọ, lai di igbagbọ ẹnikẹni lọwọ.

"N ko ri gbọ ri pe awọn ẹlẹsin miiran kominu lori pe pipa ẹran agbo jẹ ohun ti ko ni itẹwọgba,

"Oni kaluku lo di igbagbọ rẹ mu."

Soyinka wa rọ Emir lati se atunse si isẹlẹ naa, ki wọn si jẹ ki alaafia jọba laarin awọn ẹlẹsin.

"Ẹ pe Yeye Ajasikemi Olokun Omolara si aarin yin, ẹ jẹ ki alaafia jọba.

"A mọ itan ilu Ilorin sugbọn iyẹni ni ọrọ bayii. Ẹ maa se ohun ti yoo tabuku si iran Yoruba.

"Alaafia ati ibọwọ fun gbogbo ẹsin lo yẹ ki a dimu."

Tori ki Ija maa bẹ silẹ ni a se wọgile ọdun Isẹsẹ- Emir Ilorin

Emir ti ilu Ilorin, Ibrahim Sulu Gambari ninu esi rẹ si lẹka Ọjọgbọn Wole Soyinka, o fesi pe awọn wogile ọdun Isẹse nilu Ilorin nitori ki ija ma ba le bẹ silẹ niluu Ilorin.

Ninu atẹjade ti agbẹnusọ Ọba, AbdulAzeez Arowona buwọlu fun awọn akọroyin niluu Ilorin, Emir salaye pe igbesẹ oun lati wogile ọdun naa lo jẹ ọna kan soso lati gbegi dana ja ẹsin lorilẹede Naijiria.

O ni;

"Ọjọgbọn Soyinka gbagbe pe ko si ẹnikẹni to fẹran ogun

"A gbe igbesẹ yii lati ma jẹ ki ija bẹ silẹ ati pe ko ni daara pe ki a duro pe ki ija naa waye nitori ohun ti yoo da silẹ le kọja agbara wa ni a fi ọgbọn se.

"Irufẹ igbasẹ yii se dandan lati fun alaafin laye ni agbegbe wa.

Emir tẹsiwaju pe Yeye Ajesikemi ti n gbe niluu Ilorin lia si wahala ti ti to fi fẹ gbe igbsẹ to ju agbara rẹ lọ.

"Isẹlẹ yii le da ija silẹ ni awọn apa ibo miiran lorilẹede Naijiria.

"Awọn ajoji nipinlẹ Kwara fẹran ilu nitori pe alaafia jọba.

"Yeye Ajesikemi naa fidi rẹ mulẹ pe oun ti n gbe ni Ilu Ilorin, ayi fi igba to gbe igbesẹ to ju agbara rẹ lọ."