Èèyàn mọ́kànlá kú nínú bààlúù tó jábọ́ ní Kenya

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

O kere tan, eeyan mọkanla lo ti padanu ẹmi wọn ninu ijamba baaluu kan to waye lonii nitosi òkun orilẹede Kenya.

Awọn alaṣẹ baaluu naa sọ pe awọn arinrinajo ọmọ ilẹ Europe mẹwaa ati awakọ baaluu toun jẹ ọmọ Kenya ni wọn ba iṣẹlẹ naa lọ.

Gẹgẹ bi awọn alaṣẹ ileeṣẹ ọlọkọ ofurufu Kenya, KenyaCivil Aviation Authority (KCAA) ṣe wi, lati etikun igbafẹ Diani to gbajumọ pupọ ni ọkọ ofurufu naa ti n bọ.

Ibudo iṣere Maasai Mara ni wọn ni o n lọ to fi jabọ .

Bakan naa ni ileeṣẹ ọlọkọ ofurufu Mombasa Air Safari, sọ pe ọmọ ilẹ Hungary mẹjọ, Germany meji ati awakọ ofurufu naa to jẹ ọmọ Kenya lo ku ninu ijamba naa.

Kọmiṣanna agbegbe Kwale ni Kenya, Stephen Orinde, sọ fun BBC pe nnkan bii kilomita mẹwaa si Kwale ni baaluu naa jabọ si .

O ni iwadii ṣi n lọ lori ohun to fa jija ti baaluu yii ja, ṣugbọn o ṣee ṣe ko jẹ oju ọjọ ni ko daa.

"Oju ọjọ ko fi bẹẹ daa nibi lasiko yii. Lati aarọ kutu ni ojo ti n rọ, kurukuru si bo oju ọjọ, ṣugbọn a ko ti i fidi ẹ mulẹ.

Tẹ o ba gbagbe, loṣu Kẹjọ, ọkọ baaluu kan to jẹ ti awọn ajọ

ẹlẹyinju aanu Amref, jabọ si agbegbe kan nigberiko Kenya lẹyin Nairobi ti i ṣe olu ilu.

Eeyan mẹfa lo ku ninu iṣẹlẹ naa, awọn meji si farapa.