Tinubu, Buhari, Obi ránṣẹ́ ìbánikẹ́dùn sí ẹbí mínísítà tẹ́lẹ̀ rí Ogbonnaya Onu tó d’olóògbé

Aarẹ Bola Tinubu ti ranṣẹ ibanikẹdun si ẹbi minisita tẹlẹ ri ni ileeṣẹ ijọba to n ri si ọrọ sayẹnsi, imọ ijinlẹ ati ọgbọn inu, Oloye Ogbonnaya Onu to jade laye l’Ọjọbọ, ọjọ kọkanla oṣu Kẹrin ọdun 2024 yii.

Onu to jẹ minisita lasiko ijọba Aarẹ Muhammadu Buhari ni gomina ijọba awarawa akọkọ ni ipinlẹ Abia.

Onu to kọwe fipo minisita silẹ lati kopa ninu ibo aarẹ abẹle ẹgbẹ oṣelu APC ni ẹbi rẹ kede wi pe o ku si ile iwosan kan niluu Abuja.

Ninu atẹjade kan ti oludamọran aarẹ lori ọrọ iroyin, Ajuri Ngelale fi sita, Tinubu ṣapejuwe oloogbe gẹgẹ bi ọmọwe, akọṣẹmọṣẹ onimọ-ẹrọ to dantọ, ẹni apọnle ti ko fi iṣẹ ṣere rara.

Tinubu sọ pe Oloye Onu gbagbọ ninu iṣokan, alaafia ati ilọsiwaju Naijiria eyi ti o lepa titi ti ọlọjọ fi de.

Bakan naa ni aarẹ kẹdun pẹlu awọn ọrẹ ati akẹgbẹ Oloye Onu, awọn eeyan ipinlẹ Ebonyi ati Abia to fi mọ gbogbo ọmọ Naijiria patapata.

Buhari kẹdun Onu

Aarẹ Naijiria tẹlẹ ri, Buhari naa n ṣedaro Onu to ṣiṣẹ gẹgẹ bi minisita lasiko ijọba rẹ.

Ninu atẹjade kan ti Garba Shehu ti i ṣe oludamọran lori ọrọ iroyin si aarẹ ana fi sita, Buhari ṣapejuwe Onu gẹgẹ bi ọlọpọlọ pipe ati akọṣẹmọsẹ to gbọrọgọjigẹ.

Buhari tun ranṣẹ ikẹdun si alaga apapọ APC lori iku Oloye Onu.

Ẹgbẹ oṣelu APC naa n kẹdun oloogbe, igbakeji akọwe ẹgbẹ naa, Ọgbẹni Chidi Duru ni ọkunrin abiwapẹlẹ to ni afojusun ni Oloye Onu.

O ni Onu ti sa ere eje rẹ tan, o ṣi ti lọ ba Eledua to da a saye, Ọgbẹni Duru wa gbadura pe ki Eledumare tẹ ẹ si afẹfẹ rere.

Obi ranṣẹ ibanikẹdun si ẹbi Onu

Oludije sipo aarẹ fẹgbẹ oṣelu LP, Peter Obi naa ti ranṣẹ ibanikẹdun si ẹbi minisita tẹlẹ ri to di oloogbe.

Obi ṣapejuwe iku Onu gẹgẹ bi ohun to ba ni lọkan jẹ.

O ni adanu nla ni iku Onu jẹ fun orilẹede Naijiria, papaa julọ iran Igbo.

Obi ni Onu ki i ṣegbe lẹyin ẹnikan, o ṣi jẹ ogbontarigi akọṣẹmọsẹ onimọ-ẹrọ.

Gomina ipinlẹ Abia ṣedaro Onu

Gomina ipinlẹ Abia, Ọmọwe Alex Otti ni pẹlu ibanujẹ ni oun fi gba iroyin iku Oloye Onu.

Ọmọwe Otti ni adanu nla ni iku Onu jẹ fun ipinlẹ Abia, Ebonyi, iran Igbo ati orileẹde Naijiria lapapọ.

O ni Onu jẹ ọkan lara awọn ọmọ Naijiria to nifẹ orilẹede wọn dọkan.

Gomina Otti wa ṣeleri wi pe ijọba oun yoo ṣe imọyi fun Onu nipa titẹsiwaju lati ri pe awọn ipinlẹ Abia n jẹ anfani ijọba.

Orji Uzor Kalu sọ nipa oloogbe Onu

Gomina ipinlẹ Abia tẹlẹ ri, Orji Uzor Kalu, naa ṣapejuwe Onu gẹgẹ bi ẹni to maa n lepa alaafia ati ilọsiwaju Naijiria.

Kalu ni Onu ṣe iranwọ fun ọpọlọpọ eeyan nigba aye rẹ, eyi ti yoo jẹ ki iku rẹ dun ọpọ eeyan.

Kalu sọ pe adanu nla ni iku Onu jẹ fun ẹya Ndigbo ati Naijiria lapapọ.

‘’Gbajugbaja oloṣelu ni Onu jẹ, alaanu eeyan to ni ifẹ orilẹede rẹ lọkan si ni.

Onu ṣiṣẹ takuntakun ni oniruuru ẹka ijọba, awọn nnkan ribiribi to ṣe la o fi maa ṣe iranti rẹ,’’ Kalu lo sọ bẹẹ.