You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Mi ò ní gbà kí ọlọ́jà kankan fi ayé ni aráàlù lára nítorí ọ̀wọ́ngógó oúnjẹ – Èwí Ado Ekiti
Latari ọwọn gogo ounjẹ niNaijiria, Ewi ti ilu Ado-Ekiti, Oba Rufus Adeyemo Adejugbe ti bẹrẹ si n ṣabojuto iye owo ounjẹ kaakiri inu ilu Ado-Ekiti.
Ewi sọ pe erongba oun ni lati rii pe awọn ọlọja n ta ounẹ ni iye owo ti ko pọ ju ere lọ.
Omosio ti ilu Ado-Ekiti, Oloye Opeyemi Abiola lo dari awọn aṣoju awọn oloye lati ri pe aṣẹ Ọba ilu Ado-Ekiti mulẹ lori ọwọn gogo ounjẹ to lọ soke lainidii ninu ọja Okesha ati ọja Bisi, ni ilu Ado-Ekiti.
Gẹgẹ bi oloye Abiola ṣe sọ, Kabiyesi Ewi ti ilu Ado-Ekiti gbe igbesẹ akọni naa latari owo ounjẹ to lọ soke bi ọpọ awọn olutaja ṣe mu nkan le fun awọn olugbe ilu Ado Ekiti.
Oloye naa kilọ fawọn oniṣowo ati awọn to n ta ounjẹ pe ki wọn ma ṣe ro ti afikun owo epo bẹntiroolu maa ta ọja ni iye owo ti o wu wọn ti o si n mu inira ba awọn araalu.
Oloye Abiola tesiwaju ninu ọrọ rẹ pe ọwọngogo ounjẹ ni ilu Ado-Ekiti ko ṣẹyin bi awọn olutaja ati olutunta ṣe mọọmọ gbe owo le ori ọja bi o se wu wọn, eyii lo mu ki Kabiyesi ran awọn oloye rẹ sita lati dẹkun iwa ibajẹ tita ounjẹ ni iye owo ti o ju iye ti o yẹ ki wọn maa taa lọ.
O ni “Awọn ọlọja kan sọ pe nnkan ti awọn ra ni ọja oko ni awọn n ta ninu ọja ṣugbọn a mọ pe ko ri bẹẹ.
“Wọn le sọ ohunkohun ti wọn ba fẹ sọ, gbogbo ohun ti mo mọ ni pe a fẹ ki awọn eniyan gbadun afẹfẹ ti o dara ti ipinlẹ yii.
“A ko fẹ awọn idiyele ọwọngogo ti o pọju awọn ọja ounjẹ.”
Oloye Abiola ni lati ọjọ ọja to n bọ, ti wọn ba ri ẹnikẹni ti o n ta ọja ni ọwọngogo, ilu yoo gba ọja rẹ ti awọn yoo si ko gbogbo ẹru ọja irufẹ ẹni bẹẹ lọ aafin Ewi Ado-Ekiti.
Awọn olutaja ninu ọja fi idi rẹ mulẹ pe ohun ti awọn ra lati ọja oko ni awọn ninu ọja kaakiri lai gbe owo le ori Ọja rara.
Arabinrin Bello Yemisi, to jẹ oniṣowo iṣu sọ fun BBC News Yoruba pe idojukọ ati iye owo ti wọn fi n ko iṣu lati Abuja de ilu Ado-Ekiti lo mu ki owo iṣu gbowolori diẹ, ti oun si n ta ni owo ti ko gunpa.
Yemisi wa parọwa si ijoba ipinlẹ ati apapọ lati wa nkan ṣe si ọrọ owo epo bẹntiroolu to mu gbogbo nnkan wọn gogo ni Naijiria.
Onisowo miran to n ta ẹfọ, Victoria Adedeji naa ṣalaye idojukọ rẹ lori bi awọn oloko ko ṣe fẹ ta ọja mọ fun awọn to n tun ta, ti wọn si n gbe wa ta funra wọn ninu ọja lomu ki wọn maa ta fun awọn lowo nla lati ọdọ awọn oloko funra ra wọn.
Oniṣowo elubọ kan Suliyat Arowolo rawọ ẹbẹ si awọn oloye lati je ki ohun ko ọja elubọ ohun pada si ile to ri owo ti wọn ni koun taa ko le pe oju owo toun raa.
Ọpo lara awọn to n ra ọja ninu ọja Okesa Ado-Ekiti gboriyin fun Ọba Ewi Ado fun igbesẹ akọni lati mu igbe aye irọrun ba awọn olugbe Ado lati rii pe iye owo ti wọn n ounjẹ dinku.
Omolola Adejugbe, ọkan lara awọn araalu ṣalaye pe igbese Ewi ti ilu Ado Ekiti dara pupọ lati mu igbe aye irọrun ba awọn mẹkunnu, onile ati alejo ni ilu Ado to si parọwa si awọn olori ilu ni Naijiria lati ṣe bakanna.