"Àtúnṣe wáyà tó da nẹ́tíwọ́ọ̀kì fóònù àti kọ̀mpútà yín rú yóò tó ọ̀sẹ̀ méjì’’

Ileeṣẹ MainOne to n ri si waya to n mu nẹtiwọọki wa fun lilo foonu ati ẹrọ kọmputa ti sọ pe waya to ja ni isalẹ okun ti gbogbo nẹtiwọọki fi daru yoo to ọsẹ meji lati ṣe atunṣe rẹ.

Ileeṣẹ MainOne sọrọ yii ninu atẹjade kan to fi sita lori ibi ti ọrọ de duro lori akitiyan rẹ lati wa ojutuu si iṣoro nẹtiwọọki to daru lati Ọjọbọ ọsẹ yii.

Ileeṣẹ naa sọ ninu atẹjade naa pe igbesẹ akọkọ ni lati wa ọkọ oju-omi ti yoo ko gbogbo eroja fun atunṣe waya to ja naa lọ si ibi ti o ti ja.

Ileeṣẹ MainOne sọ ninu atẹjade ọhun pe ‘’iṣẹ atunṣe yii yoo to ọsẹ kan tabi meji ki o to le pari nitori o ṣeeṣe ki ọkọ oju-omi lo to ọsẹ mẹta gan an lati ko gbogbo awọn eroja ti wọn nilo fun atunṣe naa lati ilẹ Yuroopu wa si apa iwọ oorun ilẹ Africa nibi ti waya ọhun ti ja ni isalẹ omi.’’

Bakan naa ni ileeṣẹ naa tun ṣalaye pe awọn nnkan to maa n ba waya nẹtiwọọki yii jẹ labẹ omi.

Ileeṣẹ naa ni ‘’awọn to maa n pa ẹja maa n ṣakoba fun waya to wa ni isalẹ omi yii.

Bakan naa, ilẹ riri tabi didaku ẹrọ nẹtiwọọki maa n faa ki waya yii ja labẹ omi.

Amọ, pẹlu bi ibi ti waya yii ti ja ṣe jina sori ilẹ si, ko daju wi pe awọn apẹja lo ṣe okunfa waya to ja ọhun.

Iwadii ti a ti ṣe lori waya to ja naa fihan pe nnkan mii lo ṣe okunfa waya to ja yii, amọ, a o mọ ohun to ṣelẹ gaan an ti wọn ba gbe waya naa jade tan.’’

Ẹwẹ, ileeṣẹ foonu ibaraẹnisọrọ, MTN ti ṣalaye pe waya mẹrin ọtọtọ ti orukọ wọn n jẹ WACS, ACE, SAT3 ati MainOne lo ja ni isalẹ omi.

Orilẹede South Africa, Nigeria, Ivory Coast, Liberia, Ghana ati Burkina Faso wa lara awọn orilẹede ti waya to ja yii n ṣakoba fun nẹtiwọọki foonu ati kọmputa wọn.