You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Àwọn ajínigbé jí ìyàwó àti ọmọ méjì aṣòfin Ìpínlẹ̀ Kwara gbé lọ
Awọn agbebọn kan lọjọ Aje ji iyawo ati ọmọ meji ọmọ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Kwara. Lawal Ayanshola Soliu gbe lọ.
Iṣẹlẹ naa lo waye ni agbegbe Shao to jẹ agbegbe Aṣofin naa nijọba ibilẹ Moro ni dede ago kan lorun.
Lawal ẹni to n soju ẹkun idibo Ipaiye/Malete/Olooru ti ìjọba ibilẹ Moro ni ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Kwara labẹ asia ẹgbẹ oselu APC.
Ibi tí awọn agbebọn naa wa ni ko ti di mimọ.
Ọkan lara awọn agbebọn naa to ba awọn mọlẹbi sọrọ ni oun ko ti de ibi tí awọn yooku oun wa lati sọrọ nipa iye owo ti wọn yoo gba fun itusilẹ.
Agbẹnusọ fun ileeṣẹ Ọlọpaa, Ajayi Okasanmi fìdí iṣẹlẹ naa mulẹ.
Okasanmi ni awọn ko ti le sọ bi iṣẹlẹ naa se waye sugbọn iwadi ti bẹrẹ