You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ìdí tí ìjọba àpapọ̀ ṣe ń gbé Nnamdi Kanu lọ sílé ẹjọ́ tó ga jùlọ rèé
- Author, Faoziyah Saanu-Olomoda
- Role, Broadcast Journalist
Ìjọba àpapọ̀ ti gba ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà láti fihàn wí pé ìdájọ́ tí ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn gbé kalẹ̀ lọ́jọ́ Kẹtàlá, oṣù Kẹwàá ọdún 2022 pé kí olórí ajìjàgbára tó ń pè fún ìdásílẹ̀ orílẹ̀ èdè Biafra, Nnamdi Kanu máa lọ sílé láyọ̀ àti àláfíà.
ìjọba àpapọ̀ ń béèrè pé kí ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ gbé ìdájọ́ ti ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn tì sí ẹ̀gbẹ́ kan, kí wọ́n sì gbà kí ilé ẹjọ́ ṣe ìgbẹ́jọ́ Kanu lórí àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n kàn-án.
Nínú ìwé ìpẹ̀jọ́ tí iléeṣẹ́ ètò ìdájọ́ kọ ránṣẹ́ sí ilé ẹjọ́ lọ́jọ́ Kejìdínlógún, ní kí ilé ẹjọ́ gbà kí Kanu ní àhámọ́ ná títí ìgbẹ́jọ́ rẹ̀ yóò fi parí pẹ̀lú ilé ejọ́ tó ga jùlọ.
Olùpẹjọ́ fún ìjọba àpapọ̀, Mohammed Abubakar nínú ìwé ìpẹjọ́ náà sọ wí pé ìdí mẹ́fà ni àwọn fi ń pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn lórí ìdájọ́ náà.
Kí ni ìdí tí ìjọba àpapọ̀ fi gbé Kanu lọ sí ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ?
Ìjọba àpapọ̀ nínú ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn tí wọ́n pè ní ìdájọ́ ọjọ́ Kẹtàlá tí ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn fi dá Kanu láre kò tẹ́ àwọn lọ́rùn.
Wọ́n ní àwọn ní ìgbàgbọ́ pé àwọn ẹjọ́ ṣì wà lórí ọ̀rọ̀ Kanu èyí tí ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ le bá àwọn dá sí.
Ìdí mìíràn tí ìjọba ṣe ní àwọn ń fẹ́ kí Kanu wà ní àhámọ́ ni pé Nnamdi Kanu le sá kúrò ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà tí wọ́n bá tu sílẹ̀ kí ilé ẹjọ́ tó parí ẹjọ́ rẹ̀.
Wọ́n ní nítorí Kanu ní ìwé ìgbélùú United Kingdom, ó le sá kúrò ní Nàìjíríà nígbà tó bá wù ú àti pé ìgbà àkọ́kọ́ kọ́ nìyí tí yóò sá kúrò ní Nàìjíríà lásìkò tí ìgbẹ́jọ́ rẹ̀ ṣì wà ní ilé ẹjọ́.
Bákan náà ni wọ́n ní àwọn ìdí pàtàkì kan tí àwọn fi ń bèèrè fún ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn lórí ẹjọ́ Nnamdi Kanu. Fun ìdí èyí kí ilé ẹjọ́ gba àwọn láyé láti fi Kanu sí àhámọ́.
Ilé-ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn ti kọ́kọ́ fòntẹ̀ lu ìtúsílẹ̀ Nnamdi Kanu saájú
Ẹ o ranti pe ni ọjọ Kẹtàlá ni a mu iroyin wa pe Ile ẹjọ kotẹmilọrun nilu Abuja ti ni ki wọn tu olori ikọ ajijagbara IPOB Nnamdi silẹ pe ko maa lọ sile lalaafia.
Adajọ ẹlẹni mẹta to gbẹjọ kotẹmilọrun to gbe wa sile ẹjọ ni ko lẹjọ lati dahun mọ nitori ile ẹjọ giga ko laṣẹ lati gbẹjọ rẹ.
Adajọ ni ọna ti ko tọ ni wọn fi gbe Kanu wọ Naijiria lati orileede Kenya ati pe wọn ko tẹle ilana to bofin mu nipa gbigbe daran wọ orileede rẹ pada.
Tori eyi, adajọ ni ko lẹjọ kankan ro ti wọn si wọgile gbogbo ẹsun ti wọn fi kan an. Idajọ yi n waye lẹyin agbẹjọro agba to n ṣoju Kanu,Mike Ozekhome bẹ ile ẹjọ pe ki wọn wgile awọn ẹsun meje to ku ti wọn fi kan Kanu ninu mẹẹdogun ti ile ẹjọ giga ti ṣaaju wọgile mẹjọ ninu rẹ.
Ṣaaju, adajọ Jummai Hannatu Saki wọgile iwe ti wọn mu wa pe ki wọn tete gbọ ẹjọ Kanu pẹlu alaye pe ọjọ ti re kọja lori rẹ.
Bẹẹ naa lo fi igbẹjọ beeli rẹ sẹgbẹ kan titi igba ti wọn yoo fi gbẹjọ kotẹmilọrun . Ijọba Naijiria lo gbew Kanu lọsi ile ẹjọ lori ẹsun to da lori iditẹgbajọba,iyapa lọtọ ati pe o jẹ ọmọ ẹgbẹ IPOB ti wọn ti fofin de pe ikọ agbesunmọmi ni.
Amọ ṣa losu Karun un, adajọ Binta Nyako ti ile ẹjọ giga Abuja wọgile mẹjọ ninu awọn ẹsun ti wọn fi kan an Kanu.
Ile ẹjọ giga ti o wa ni Abuja wọgile igbẹjọ beeli ti awọn agbẹjọro rẹ muwa nigba naa.
Nnamdi Kanu ṣì lẹ́jọ́ láti jẹ́ o, ilé ẹjọ́ kò ní kò jẹ̀bi ìdìtẹ̀gbàjọba - Ìjọba àpapọ̀
Lẹ́yìn tí ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn gbé ìdájọ́ rẹ̀ kalẹ̀ ni ìjọba àpapọ̀ fi ohun léde.
Ìjọba àpapọ̀ ti ní olorí ikọ̀ ajìjàgbara fún ìdásílẹ̀ orílẹ̀ èdè Biafra, IPOB, Nnamdi Kanu ṣì ní ẹjọ́ láti jẹ́ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn ti pa gbogbo ẹ̀sùn tí ìjọba kà si lọ́rùn rẹ́.
Mínísítà fétò ìdájọ́ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, Abubakar Malami ló sọ bẹ́ẹ̀ nínú àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ rẹ̀, Umar Jibrilu Gwandu fi léde lọ́jọ́bọ̀.
Malami ní ohun tí àwọn adájọ́ gbé ìdájọ́ kalẹ̀ lé lórí ni bí ìjọba ṣe gbé Kanu wá sí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà láti wá jẹ́jọ́ kìí ṣe wí pé kò jẹ̀bi ìdìtẹ̀gbàjọba tí wọ́n fi kàn-án.
Ó ní gbogbo ẹ̀sùn tó wà lọ́rùn Kanu lórí bó ṣe sá kúrò ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà láti má kojú ìgbẹ́jọ́ nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ fún un ní ìdáǹdè ṣì wà lọ́rùn rẹ̀ tí yóò sì kojú ìgbẹ́jọ́ wọn.
Bákan náà ló fi kún un pé àwọn máa ṣàgbéyẹ̀wò ìdájọ́ náà daada láti mọ́ ìgbésẹ̀ òfin tó kàn láti gbé ọ̀rọ̀ náà gbà tí àwọn yóò sì fi ohun tí àwọn bá fẹnukò lórí léde fún gbogbo ọmọ Nàìjíríà.
Malami tẹ̀síwájú pé ìjọba àpapọ̀ ní yóò jíròrò lórí ọ̀nà tí wọ́n yóò gbé ìgbẹ́jọ́ náà gbà láìpẹ́.
Àwọn ẹ̀sùn tí ìjọba kà sí Nnamdi lọ́rùn
Ẹ̀sùn mẹ́ẹ̀dógún ni ìjọba àpapọ̀ kàsí Nnamdi Kanu lọ́rùn léyìí tó dá lórí ìdìtẹ̀gbàjọba.
Ṣùgbọ́n nínú oṣù Karùn-ún ọdún 2022 ni adájọ́ Binta Nyako ti ilé ẹjọ́ gíga ìlú Abuja dín àwọn ẹ̀sùn náà kù di méje.
Àwọn ẹ̀sùn méje tó kù ni ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn dànù lọ́jọ́ Kẹtàlá, oṣù Kẹwàá, ọdún 2022.