Wó kókó ohun mẹ́rìndínlógún tí Tinubu yóò ṣé tó bá di Ààrẹ

    • Author, Akinlabi Afolabi
    • Role, Broadcast Journalist

Lọjọ ẹti ni oludije sipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC, Bola Ahmed Tinubu ti kede awọn erongba to ni lọkan fawọn ọmọ Naijiria, ti wọn ba yan gẹgẹ bi aarẹ lọdun 2023.

Tinubu sisọ loju ọrọ naa nibi ayẹyẹ ifilọlẹ iwe ileri ohun to fẹ se lori aleefa ti wọn ba yan sipo aarẹ eyi to waye niluu Abuja.

Aarẹ Muhammdu Buhari ati awọn agbaọjẹ ẹgbẹ oṣelu APC si lo wa nibi ayẹyẹ ifilọlẹ iwe ileri ipolongo ibo naa.

Aarẹ Muhammadu Buhari, ẹni to jẹ olori igbimọ ipologo fun Tinubu lo si fi iwe naa, ‘Nigeria Improvement Plan’ lọlẹ.

Ti ẹ ba gbagbe, awọn ẹgbẹ oṣelu yoku bi PDP ati Labour Party naa ti ṣe ifilọlẹ ileri ipologo wọn.

Awọn ifilọlẹ ileri ibo naa si lo n waye saaju eto idibo ti yoo waye ninu osu keji ọdun to n bọ.

Nǹkan mẹ́rindínlógún tí mó fẹ́ ṣe fún Nàìjíríà rèé - Tinubu

Ètò Àbò:

Tinubu fi eto abo saaju ninu iwe ọhun, to si tun gbe oriyin fun iṣejọba Aarẹ Buhari lori kikoju awọn ipenija eto abo lorilẹede Naijiria.

O ni wọn gbiyanju ti wọn.

“Ijọba to wa lode ti gbe igbesẹ to yẹ lori eto abo nigba ti wọn gba ijọba. Wọn mu awọn agbebọn naa lẹyin ti wọn fẹ gba isakoso orilẹede Naijiria.“

Tinubu ni “ A yoo gbe igbesẹ ni kiakia lati yanju awọn ipenija eto abo pẹlu awọn igbesẹ wọn yii:

  • Ayipada si awọn ọmọ ologun ati isẹ wọn ni sise
  • Atunse si ibanisọrọ wọn pẹlu irinsẹ igbalode
  • Afikun agbaraawọn ọmọ ologun
  • Owo oṣu to gbonbọ ati igbaye gbadun
  • Sise idina fun awọn ẹgbẹ agbebọn to fẹ lo igbo ṣe iwa ọdaran
  • Gbigbọ ikilọ lati awọn ẹsọ abo igberiko

Ọ̀rọ̀ Ajé:

Gẹgẹ bi Tinubu ṣe sọ, eto ọgbin ni igi lẹyin ọgba ọrọ aje orilẹede Naijiria, to si ni isẹ ko ni duro lori rẹ

Bakan an, Tinubu ni oun gba pe o ṣe koko ka mojuto bi imọ ẹrọ ṣe n pọsi lorilẹede Naijiria.

“A ni lati mojuto awọn ọdọ wa.

Awọn ni ọjọ ọla orilẹede yii. Awọn ọdọ to wa laarin ọmọ ọdun mẹẹdogun si marundinlogoji lo pọju lorilẹede Naijiria.

Awọn igbesẹ ti a ma gbe si ree:

  • Atunṣe owo osuna orilẹede yii
  • Igbesẹ lori owo orile gbigba
  • Gbigbogun ti iwa ibajẹ laarin awọn osisẹ ijọba ati sise
  • Idasilẹ bi ijọba yoo sẹ ma nawo
  • Sise idaduro lori bi orilẹede Naijiria ṣe n yawo lati oke okun, lati fi bu eyi owo naira wa

Eto ọgbin:

Oludije fun ẹgbẹ oṣelu APC ni lẹka eto ọgbin, oun yoo pese anfani fun orilẹede Naijiria , paapa julọ awọn ọdọ.

Bakan naa lo ni oun yoo tun ṣe afikun si ọrọ aje ati bi a se n gbara le epo bẹnitiro nikan.

“Awọn agbẹ orilẹede Naijiria jẹ ọkan lara akanda ẹda ni agbaye.”

Awọn igbesẹ ti a ma gbe re:

  •  Itọju awọn ohun ọgbin
  • Idasoke ni awọn abule
  • Ifọwọsowọpọ pẹlu awọn agbẹ
  • Idasoke awọn ohun ọgbin lasiko ẹrun
  • Erongba lati pese ilẹ ati atunṣe awọn ilẹ naa fun ọgbin sise

Ìpèsè iná mọ̀nàmọ́ná

Lori ọrọ ina mọnamọna, Tinubu ni orilẹede Naijiria ni agbara lati pese 12,00MW ina mọnamọna.

Sugbọn o ni a ko ni anfani lati pese ju 8,000MW, kawọn si pin 4,000MW fun awọn araalu.

“Ọrọ aje wa ni ida duro nitori bi a ṣe kuna lati pese ati pin ina mọnamọna daada.”

O salaye siwaju nipa awọn igbesẹ ti oun ma gbe si niyi: 

  • Sise idaduro fun sisan owo san fun awọn ti ko ni ẹro to n wọn ina mọnamọna
  • Gbe igbimọ kale lori ina pinpin
  • Riri ina mọnamọna lia fa efin ti yoo ṣe ijamba
  • Sise iranwo fun awọn ba fẹ gba ẹro to n wọn ina mọnamọna
  • Ina mọnamọan ni awọn igberiko
  • Atunṣe si ẹka ina mọnamọna

Ẹkà èpò rọbi:

Tinubu salaye pe itan orilẹede Naijiria fihan pe epo rọbi nikan ko le tan isoro ọrọ aje ile wa sugbọn wọn ṣe koko ninu idagbasoke ọrọ aje.

  • Awọn igbesẹ ti a ma gbe:
  • Afikun si bi a ṣe pese epo rọbi
  • Mimu igbeaye dẹru fun awọn olugbe agbegbe epo rọbi
  • Riri pe epo rọbi kaari
  • Atunse pẹlu ibaṣepọ awọn to n dari

Àwọn nǹkan mìíràn tí ìwé ìpolongo náà sọ̀rọ̀ nípa rẹ:

Bola Ahmed Tinubu wa ṣe ileri pe ti wọn dibo yan oun gẹgẹ bi aarẹ lọdun 2023, oun yoo ripe awọn ṣe ohun to tọ ati ohun yẹ lati mu idasoke ba ilọsiwaju orilẹede Naijiria. O wa darukọ awọn ẹka miiran ti yoo yasi toba di aarẹ:

  •  Ẹka irina
  •  Ẹto Ẹkọ
  • Ẹka ere idaraya ati asa
  • Fifun awọn ọdọ ni idanilẹkọ ati owo iranwọ
  • Ẹka to n risi ọrọ obinrin
  • Awọn isẹ akanṣe
  • Ẹka ofin
  • Amujutọ ilẹ wa
  • Ẹka o n risi ọrọ ilẹ okere