Òfin tó de ẹran dídà fìdí múlẹ̀ l‘Oyo, darandaran tó da ẹran wọnú oko wọ gàù, ọwọ́ tẹ àwọn màálù kan, ọ̀pọ̀ darandaran sá lọ

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Omi tuntun ti ru, ẹja tuntun si ti wọ inu rẹ nidi agbekalẹ ati amusẹ ofin nipinlẹ Oyo, paapaa, ofin to de ẹran dida kiri igboro.

Bi ẹ ko ba gbagbe, yoo to ọdun mẹta bayii ti ijọba Oyo kede pe o ti di eewọ fun awọn darandaran lati maa da ẹran kiri oju popo yika ipinlẹ naa.

Bi o tilẹ jẹ pe ofin naa ko fi bẹẹ fidi mulẹ tẹlẹ amọ ayipada nla ti de bayii pẹlu agbekalẹ ajọ kan ti yoo maa ri si amusẹ ofin naa yika ipinlẹ Oyo.

Koda, kootu alagbeka gan ti wa eyi ti adajọfẹhinti, Aderonke Aderemi ko sodi, ti yoo maa se idajọ oju ẹsẹ fawọn eeyan to ba lugbadi ofin ọhun.

Ajọ to n ri si ifidimulẹ ofin n'ipinlẹ Ọyọ naa si ti bẹrẹ isẹ lọgan.

"Ìjọba fi kele ofin gbe darandaran to da maalu wọ oko ti wọn gbin ẹgẹ si ni Iseyin"

Ajọ to n ri si ifidimulẹ ofin n'ipinlẹ Ọyọ, (Oyo State Rule of Law Enforcement Authority') ti fi kele ofin gbe darandaran kan, ti o da maalu wọ oko ti wọn gbin ẹgẹ si lori ilẹ ẹka ijọba 'Ogun-Osun River Basin Development Authority' to n bẹ ni Nikko, niluu Isẹyin, ipinlẹ Ọyọ.

Alukoro ajọ OYRLEA to mu darandaran naa l'opin ọsẹ, Opeyemi Ogunniyi, ṣe alaye ọrọ ninu atẹjade kan ti wọn fi ṣọwọ si awọn oniroyin niluu Ibadan wi pe awọn akẹgbẹ darandaran naa sa lọ pẹlu awọn maalu wọn.

Atẹjade naa tọka rẹ siwaju sii wi pe ajọ OYRLEA ri maalu meloo kan mu, pẹlu atọkun wọn ti orukọ rẹ n jẹ Alhaji Amosa.

Lẹyin ti agbẹ kan lati agbegbe naa wa fi ẹjọ sun nipa awọn to n fi ẹran jẹ oko yii ni ajọ to n fi idi ofin mulẹ n'ipinlẹ Ọyọ, OYRLEA ran awọn aṣoju rẹ lọ si ibi iṣẹlẹ naa.

Lara wọn ni alakoso ọrọ ayika fun ajọ naa, DCP Ojomo, adari awọn oṣiṣẹ fun ajọ OYRLEA, Arabinrin I.E. Akinbode ati awọn oṣiṣẹ mii.

"Awọn agbẹ dunnu si agbekalẹ ajọ OYRLEA ati ipenija ti wọn n koju lọwọ awọn darandaran ati akoba to n se sawọn ere oko wọn"

Atẹjade naa ṣe alaye siwaju sii wi pe awọn oṣiṣẹ ajọ OYRLEA ba awọn maalu to n jẹ oko ẹgẹ lọwọ lasiko ti wọn de agbegbe naa.

Lẹyin eleyii ni wọn gbe afurasi darandaran lọ si ile ẹjọ ti wọn si ko awọn maalu naa lọ si ẹka ileeṣẹ ijọba ipinlẹ Ọyọ to n mojuto nnkan ọgbin ati ọsin.

Lasiko ti ajọ naa n ṣe iṣẹ wọn lọwọ ni awọn agbẹ kan to n bẹ ni ayika naa jade sita lati ṣe alaye ọrọ lori awọn ipenija ti wọn n koju lọwọ awọn darandaran ati bi o ṣe n ko ba awọn ere oko wọn.

Wọn fi idunnu wọn han lori idasilẹ ajọ OYRLEA nitori yoo mu wọn bọ lọwọ wahala awọn darandaran.

Arakunrin AbdulRazak Akadi to sọrọ lorukọ ẹgbẹ awọn agbẹ to n bẹ ni agbegbe naa ṣe alaye wi pe awọn darandaran lo n jẹ ere gbogbo iṣẹ ti awọn n ṣe saaju asiko yii nitori awọn kii ri nnkan kan to ni itumọ mu jade ninu iṣẹ oko ti wọn n ṣe.

Ajọ wo lo n jẹ OYRLEA, ki si ni ojuṣe wọn?

Ninu oṣu kẹjọ ọdun 2024 ni ijọba ipinlẹ Ọyọ ṣe ifilọlẹ ajọ 'Oyo State Rule of Law Enforcement Authority' lati riidaju wi pe gbogbo olugbe ipinlẹ naa lo n tẹle ilana ofin, paapaa julọ fun amojuto awọn darandaran ati igbokegbodo ọkọ.

Erongba ijọba ipinlẹ Ọyọ ni pe ajọ OYRLEA yoo fi idi ofin mulẹ nipasẹ ajọṣepọ pẹlu awọn ẹka ileeṣẹ ijọba to ku.

Ninu fọnran kan ti ijọba ipinlẹ Ọyọ fi lede laipẹ yii, alaga ajọ naa Adajọfẹyinti, Justice Aderonkẹ Aderẹmi ṣe alaye wi pe lara awọn nnkan to jẹ ajọ naa logun ni amojuto igbokegbodo ọkọ, gbigbogun ti awọn darandaran to n da maalu wọn oko oloko ati awọn to n da ẹran ni ayika ibi ti awọn eeyan n gbe ati amojuọtọ ọrọ ayika to fi mọ awọn ohun ọsin bii ewurẹ, adiyẹ ati ẹlẹdẹ.

Aderẹmi ni ẹni to ba fẹ sin nnkan ọsin layika ibi ti awọn eeyan n gbe gbọdọ kọkọ lọ gba iwe aṣẹ lọwọ ẹka ileeṣẹ ijọba to n ri si ọrọ nnkan ọgbin ati nnkan ọsin ki wọn to gbe igbesẹ naa.

O ni, "Awọn ofin yii wa, ẹ ma ṣe da ẹran mọ laarin ilu ati laarin awọn oko wa. Ẹnikẹni ti a ba mu, o di ile ẹjọ. Ẹ jẹ ki wọn mọ bẹẹ o."

"Ṣe ẹ wa rii, kii wa ṣe ẹran nikan o, awọn ti wọn n sin adiyẹ naa, wọn wa lara rẹ o. Bi adiyẹ ba kuro ni ile tiyin, ti o wa lọ sọ ile onile di ibi ti yoo maa sun si, ti yoo tun maa yagbẹ si, a a muu yin o."

Ofin naa ko si yọ ọsin aja naa silẹ nitori ajọ naa koro oju si awọn aja to n bu awọn aladugbo jẹ nitori awọn olowo wọn ko mojuto wọn.

Bakan naa ni alaga ajọ naa rọ awọn araalu lati maa fi ọrọ to ajọ naa leti ti wọn ba ri ẹnikẹni to n ru ofin ni ayika wọn.

Awọn nọmba ti ajọ naa fi sita ni:

07061605529

08115200398.