You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Kí ló fà á tí Owa ìlú Igbajo fi pé méjì èyí tó fa rògbòdìyàn lẹ́yìn ìpapòdà Ọba Famodun?
Ni ọjọ Kẹrinlelogun osu Kọkanla ọdun 2022 ni Ọba Famodun gba ọpa asẹ gẹgẹ bi Ọwa ti ilu Igbajọ.
Eyi waye ni o ku ọjọ diẹ ti gomina ana nipinlẹ Osun, Adegboyega Oyetola yoo kuro lori aga gẹgẹ bi gomina, to si gbe ọpa asẹ le Oba Famodun lọwọ gẹgẹ bi Ọba ti iluu Igbajọ.
Sugbọn kete ti wọn bura wọle fun Gomina Ademola Adeleke, ni o yọ Ọba Adegboyega Famodun gẹgẹ bi Ọwa ti iluu Igbajọ to si yan Ọba miran ti orukọ rẹ n jẹ Ọba Ademola Makinde rọpo rẹ.
Ẹbi ati awọn eekan iluu Igbajọ ko fara mọ igbesẹ ti Gomina Ademola Adeleke gbe, eyi lo mu ki wọn gba ile ẹjọ giga ti ẹka rẹ wa ni iluu ile-Ifẹ lọ, ti ile ẹjọ naa si ni ki wọn da Ọba Famodun pada si ori apere awọn baba nla rẹ ni Ọgbọn ọjọ osu Kinni ọdun 2025.
Ṣaaju ki Oba Famodun to jade laye ni ile ẹjọ ti paṣẹ pe ki wọn da Ọba Famodun pada ni ipo ọba, gẹgẹ bi Ọwa ti iluu Igbajọ.
Ọba Famodun, lasiko aye rẹ, tẹle asẹ ti ile ẹjọ gbe kalẹ pe ko pada si ipo Ọba gẹgẹ bi Ọwa ti iluu Igbajọ. Sugbọn ti gomina Adeleke fariga pe ko si ohun to jọ bẹ rara.
Gẹgẹ bi a se gbọ pe Ọba Famodun ko fi aafin silẹ fun Ọba Ademola Makinde ti Gomina Adeleke yan gẹgẹ bi Ọwa ti iluu Igbajọ.
Sugbọn ara ko rọ okun ara ko rọ adiẹ Ọba Famodun lati igba naa titi di asiko ti ọlọjọ de ni ọjọ Kejidinlọgbọn osu Kọọkanla ọdun 2025 ti a wa yii.
Ninu ọrọ rẹ, Ọmọọba Adekunle Famodun, to jẹ akọwe ẹbi Famodun, se apejuwe Ọba Adegboyega Famodun gẹgẹ bi ẹni to ni ifẹ to si tun jẹ adari rere larin iluu ati larin ẹbi lapapọ.
O tẹsiwaju pe itan ko ni gbagbe gomina to fi Ọba Adegboyega Famodun jẹ ọba ati gomina to ni ko kuro lori apere lialia.
Ọwa tí ìlú Igbajo l'Osun, Ọba Famodun wàjà
Ọwa ti iluu Igbajọ Ọba Adegboyega Famodun, ẹni to ti fi igba kan jẹ alaga ẹgbẹ oselu APC, ẹka ti ipinlẹ Osun ti waja.
Ọmọ Ọba Adekunle Famodun, ẹni to jẹ akọwe fun ẹbi Ọba Adegboyega Famodun lo fi atẹjade sita lati kede iku Ọba Famodun, ẹni ti o jade laye ni ọjọ Ẹti, ọjọ Kejidinlọgbọn oṣu Kọkanla yii.
Eni ọdun mẹtadinlaadọrun ni Ọba Famodun ko to jade laye.
Rògbòdìyàn bẹ́ sílẹ̀ lẹ́yìn tí Ọwa ti ìlú Igbajo l'Osun wàjà, gómìnà Adeleke kéde kónílé-ó-gbélé
Gomina ipinlẹ Osun, Ademola Adeleke ti kede konile-o-gbele niluu Igbajo.
Kolapo Alimi, to jẹ kọmiṣọna fun eto iroyin nipinlẹ naa lo fi atẹjade ọhun sita lowurọ ọjọ kinni, oṣu Kejila, ọsun 2025 ti a wa yii.
Kolapo sọ pe idi ti ofin konile-o-gbele yii fi waye ni iluu Igbajo to wa ni ijọba ibilẹ Boluwaduro nipinlẹ Osun, ko sẹyin bi awọn ọdọ ilu naa se n fa wahala lati alẹ ọjọ Aiku titi di owurọ ọjọ Aje.
Eleyi lo mu ki gomina Adeleke gbe ikede naa sita lati owurọ ọjọ kinni, oṣu Kejila yii, ti gomina Adeleke si da awọn agbofinro si iluu Igbajo ati agbegbe to yii ka.
Kolapo tun tẹsiwaju pe bi ẹnikẹni ba ru ofin naa ki awọn agbofinro fi iru imu ẹni bẹẹ ko ata ofin ni kiakia.
Gomina Adeleke ni oun ko ni fi aaye gba ẹnikẹni to ba fẹ da omi alaafia ipinlẹ Osun ati ilu Igbajo ru.
Gomina ni ki gbogbo olugbe ilu Igbajo ati agbegbe rẹ tẹle ofin isede oni wakati mẹrinlelogun ojojumọ to bẹrẹ yii.
Adeleke sọ pe bo ti lẹ jẹ pe iku ọmọba Adegboyega Famodun ba awọn lojiji to si jẹ adanu nla fun ipinlẹ Osun, ko yẹ ko tun si wahala ti ẹnikẹni yoo tun maa da silẹ rara.
O ni ijọba oun ko ni kawọ gbera lati fi aaye gba iwa ibajẹ ni ipinlẹ Osun rara.
Gomnia Adeleke sọ mfiwaju si pe gẹgẹ bi oun ṣe jẹ olori ẹsọ alaabo ni ipinlẹ Osun oun kede isede konile-o-gbele titi alaafia yoo fi jọba ni ilu Igbajo ati agbegbe rẹ.
Gomina Ademola Adeleke ba awọn ẹbi kẹdun
Ninu atẹjade kan ti Olawale Rasheed to jẹ agbẹnusọ fun gomina Adeleke fi lede, Gomina Ademola Adeleko ba awọn ẹbi ati ẹgbẹ oselu APC kẹdun isipo pada Oba Adegboyega Famodun.
Gomina Adeleke si gba ni adura pe ki Ọlọrun ko fun ẹbi ati ẹgbẹ oselu APC ni okun ati le gbe isẹlẹ naa.
Rasheed, ni gomina Adeleke ti mọ ologbe Famodun tipẹ gẹgẹ bi oloselu to fara mọ ẹbi Adeleke igba ti o wa ni orileẹde Amẹrika. bẹẹ ni gomina Adeleke se apejuwe ologbe Famodun gẹgẹ bi ẹni to ti ni ipa nla ninu oselu to si ti mu itẹsiwaju ba ipinlẹ Osun.
Nigba ti gomina Adeleke de si orilẹde Naijira lonii lo fi ọrọ ibanikẹdun ransẹ si iluu Igbajọ ati gbogbo awọn ti iku ologbe Famodun kan wi pe, ki Ọlọrun ko fun gbogbo wọn ni ọkan ti wọn yoo fi le gba iku ologbe gẹgẹ bi amuwa Ọlọrun.