Wọ́n fẹ̀sùn kan Israel pé wọ́n ń pète ogun nípa ìṣekúpa ọmọdé

- Author, Isobel Yeung, Josh Baker and Sara Obeidat
- Role, BBC News
Ni ọsan ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu kọkanla ọdun to kọja, ọpọ awọn ọmọde ọkunrin Palestinian bọ sori titi ni agbegbe West Bank, nibi ti wọn ti n ṣe ere.
Ko pe isẹju aya, meji laarin wọn subu silẹ lẹyin ti wọn gboro ibọn lati ọwọ awọn ọmọ ogun Israel- Basil, 15 ati ọmọ ọdun mẹjọ Adam.
Ninu iwadi sini ikọ ologun Israel ni West Bank, BBC ṣe afihan ohun to waye lọjọ ti awọn ọmọdekunrin meji naa ku.
Ẹrọ ibaraẹnisọrọ, ẹrọ CCTV, iroyin nipa irinṣẹ awọn ologun Israel, ijẹri awọn oṣojumikoro ati iwadii to lagbara nibi ti iṣẹlẹ naa ti waye ati kiko awọn ẹri mi jọ fihan pe itẹ oju ọmọ niyan waye.
Ẹri ti ri ti jẹ ki Ben Saul, oṣiṣe UN lori ẹtọ ọmọ niyan ni iku Adam jẹ ki iku ogun to si lodi sofin.
Agbofinro mii, Dr Lawrence Hill- Cawthrone naa bu atẹlu igbesẹ naa.
Ileeṣẹ ologun Israel ni ohun to so mọ iku naa ni awọn ti n ṣe iwadi nipa sugbọn wọn ni awọn lo eronja ohun ija lati koju awọn idunkoko tabi fi mu awọn eeyan kan lẹyin ti awọn ti gbogbo igbesẹ alafia.
Pẹlu bi rogbodiyan ṣe bẹ silẹ ni West Bank ninu oṣu ti Hamas ṣe ikọlu si Israell ati ọjọ keje oṣu kẹwaa, BBC tun ṣawari ẹri bi awọn ṣe yawọ ile awọn eeyan Palestine.
Ẹri fihan bi wọn ṣe n fi ibọn dunkoko awọn eeyan ti wọn si ni ki kuro ni agbegbe naa lọ si ilu to wa ni tosi, Jordan.
Fọnran kan to jade lọjọ kọkandilọgbọn oṣu kọkanla ṣafihan Basil to duro si ẹgbẹ sọọbu kan. Nigba ti awọn ọmọ ologun Israel de, awọn sọọbu bẹrẹ si ni jẹ titi pa ni kiakia ni Jenin, ilu kan ni West Bank= agbegbe Palestine, ti ko ki n ṣe awọn Hamas lo n dari rẹ bi ti Gaza.
Awọn oṣojumikoro ni awọn n gboro ibọn ti awọn ọmọ ologun n yin ni aba Jeinn.
Adam, eeyan to fẹran lati ma gba bọọlu, to si fẹran Lionel Messi pupọ, duro si ẹgbẹ ẹgbọn rẹ Baha, 14. O to ọmọdekunrin mẹsan an to wa ni titi naa, ti gbogbo si han ninu ẹrọ CCTV to ṣafihan ohun to sẹlẹ lẹyin igba naa.

Ni iwọn ẹgbẹrun mita sẹyin, awọn igbimọ awọn ọmọ ologun pẹlu ọkọ onibo to jẹ ti Israel ya si ẹgbẹ kan, to si n tọ ọdọ awọn ọmọ naa wa, ti ibẹru boju si ba. Ọpọ awọn ọdọmọdekunrin naa bẹrẹ si ni ma kuro.
Ni asiko yii, fọnran ẹrọ ibaraẹnisọrọ fihan pe ilẹkun iwaju ti ọkọ awọn ọmọ ogun Israel si. Basil sa si oju titi, nigba ti Adam wa ni iwọn mita meji ni waju awọn ọmọ ologun, to si n sa lọ.
O to oro ibọn mejila to dun jade.
Nigba ti a n ṣe ayẹwo agbegbe, BBC ri ọta ibọn to wa lati ọna kan. Ọta ibọn mẹrin ba opo onirin kan, meji ba sọọbu.
Ayẹwo awọn eleto ilera ti o tẹ BBC lọwọ fihan pe meji ninu ọta naa ba Basil ni igba aya.
Ọta ibọn mii ba ọmọ ọdun mẹjọ Adam ni ẹyin ori bi o ṣe n salọ; ẹgbọn rẹ Baha gbiyanju lati fa kuro , ti o si n pe fun iranlọwọ.

Sugbọn o ti pẹ ju. Baha ni Adam ati ọrẹ rẹ Basil ku niwaju oun.
"Mo wa ni ẹru; N ko ti ẹ ro ti ara mi mọ. Mo igbiyanju lati ba sọrọ. Mo bẹrẹ si ni sọ pe, 'Adam, Adam!' Sugbọn ẹmi ti n bọ lara rẹ nitori ko da mi lohun." Baha sọ fun BBC pẹlu omije.
Sugbọn ki ibọn to ba, Basil ni a ri pe o n ru nnkan mọ ọwọ. A ko le sọ nnkan to jẹ. Nigba to ya Ileeṣẹ ologun safihan awọn fọnran iṣẹlẹ naa, eyi o safihan ado oloro.
Ẹri lati iwadii wa nini iṣẹlẹ naa ni a apin fun awọn akọsẹmọsẹ, awọn agbejọro to n ja fetọ ọmọniyan, awọn onimọ nipa ẹsun ogun ati awọn onimọ igbesunami, pẹlu eeyan lati ajọ agbaye, ti wọn si fi esi wọn jade.
Awọn onimọ naa fẹnuko pe iṣẹlẹ naa ni wọn gbọdọ ṣe iwadii, ti awọn si tun pinnu itako ofin agbaye ni eyi.
Ben Saul, oṣisẹ UN ni awọn ibeere kan ti wọn lati bi boya wọn le lo yinbọn lu Basil ni ilana ofin, to ba jẹ pe o mu ado oloro lọwọ.
"Fun Adam, eyi fihan pe o jẹ itako ofin ajọ agbaye to ni wọn ko gbọdọ kọlu araalu lasko ogun," Saul salaye.
Dr Lawrence Hill-Cawthorne ni "Awọn ologun yii wa ninu ọkọ ologun. To ba jẹ pe idunkoko wa gan, o yẹ ki wọn pada, ki wọn si pada wa mu awọn afurasi naa yatọ si pe wọn joju ija kọ wọn, eyi to tako ofin agbaye.

Ileeṣẹ ologun ni awọn afurasi kan lo ti n gbiyanju lati ju ado oloro si ibudo wọn, ti wọn si fẹ ijamba fun wọn. "Awọn ọmọ ologun fesi pada pẹlu ina, ti wọn si mu awọn kan balẹ." Ileeṣẹ ologun ṣalaye.
Sugbọn gẹgẹ bi fọnran ti a ri pẹlu awọn oṣojumikoro, ko da bi pe Adam ni ohun ija lọwọ, to si n sa ere nigba ti ibọn ba lẹyin ori.
Ileeṣẹ ologun ni ohun to sọ mọ iku Adam ati Basil ni awọn n gbe yẹwo lọwọ, ti awọn si n ṣe irufẹ rẹ fun gbogbo iku awọn ọmọde in West Bank.
Sugbọn awọn ọmọ ologun Israel tẹlẹ to wo ẹri BBC sọ pe awọn gbagbọ pe ofin Israel yoo ba bobo awọn ologun to wa ni ipo yii.
Ọmọ ologun tẹlẹ to siṣẹ ni West Bank lati ọdunm 2018 si 2020 ni ko ṣeeṣe ki wọn gbe awọn ọmọ ologun lọ si ile ẹjọ nitori wọn ṣekupa ọmọ Palestine paapa lori iru iṣẹlẹ to ṣẹlẹ si Adam.
Awọn iwadii lati ọdọ ẹgbẹ kan to ja fẹtọ ni Israel, Yesh Din daba pe ni ida kan ninu ada awọn ẹsun ti awọn fi kan awọn ologun Israel lo ri iadajọ.
Fọnran ikọlu Hamas lọjọ keje oṣu kẹwaa, ni bi o le ni ẹgbẹrun kan eeyan to padanu ẹmi wọn, ti o le ni igba ni wọn si mu ni ẹẹru, eyi to ya agbaye lẹnu.
Lati igba naa, agbaye ti n mọ bi oju ṣe n lọ ni Gaza, nibi ti o le ẹgbẹrun lọna ọgbọn ti jade laye gẹgẹ bii ileeṣẹ eleto ilera ṣe kede..
Sibẹsibẹ, ileeṣẹ ologun Israel ti yawọ awọn agbegbe West Bank, eyi ti jẹ ikọlu to lagbara si awọn ọmọde ju.
Apapọ ọmọde 124 ni wọn ṣekupa ni ọdun 2023, gẹgẹ bi UNICEF ṣe sọ- 85 ninu wọn ni wọn pa ninu ikọlu ọjọ keje oṣu kẹwaa
Ni ọdun 2024, ọmọde Palestine mẹrindinlogoji ni awọn ologun Israel ti ṣekupa.
Nigba to jẹ pe wọn ko ka West Bank mọ awọn agbegbe ogun, ko si ikọlu waye nibẹ, gẹgẹ bi ofin ajọ agbaye ṣe gbe kalẹ.

Wọn ni awọn sọ ede si awọn afurasi naa ni ede Arabic ati Hebrew, ko di pe wọn kọju ija si wọn, ti wọn awọn ohun ija oloro bi tajutaju, ki wọn fun wọn ni ibọn lẹsẹ, ni ipari ki wọn to ṣekupa wọn.
Ileeṣẹ eleto ilera Palestine fun BBC ni anfani lati wo iwe akọsilẹ awọn omode 112,ti meji laarin wọn jẹ ọmọ ọdun mẹtadinlogun, ti awọn ologun Israel ṣekupa bẹrẹ lati oṣu kini ọdun 2023 si ọdun 2024.
A ko le sọ ohun to fa idi ti wọn sina bolẹ ati pe o ṣeese ko jẹ pe o ti tọ ni pe awọn kan lara awọn afurasi naa n gbiyanju lati gba ẹmi awọn ologun naa.
Sugbọn iwadi wa fihan pe ida mejidinlọgọrun ni egbo ni apa oke lara wọn, nibi ọta ibọn ti ma sisẹ ju, to tumọ si pe awọn ologun le ma yinbọn fun awọn ọmọde yin lati pa wọn.
Eyi lo fa ibeere pe boya awọn ologun yii n tẹlẹ ofin iokọlu si est Bank ati bi o ṣe yẹ ki wọn lo ohunija.

Iwọnba ọsẹ marun un ni West Bank ṣayẹwo ipa ileeṣẹ ologun, a ri awọn ẹri nipa awọn iṣẹlẹ to n waye to si n bere awọn ibeere nla nipa ileeṣẹ ologun.
A fi oju gan ni ikọlu oni wakati marunlaadọta ti awọn ologun Israel ni Tulkarm ninu oṣu kinni ọdun 2024, ti wọn lepa awọn ikọ agbebọn ti wọn n pe ni 'The Resistance'.
Ẹyi ọrẹyin ni awọn araalu Palestine sọ fun wa pe awọn ologun n dunkoko mọ awọn, ti wọn si sọ fun awọn pe ki ma lọ si orilẹede Jordan. Ileeṣẹ ologun ni awọn yoo ṣe iwadii lori ẹsun naa.
Haytham, ọmọ ọdun mejila to jẹ ọmọ ilẹ Canada-Palestine ni ọbẹ ni awọn ologun naa fi n dunkoko mọ ohun, ẹsun ti ẹgbọn rẹ ati baba ti lẹyin pe o ti tọ ni.

Bakan naa ni awọn iṣẹlẹ pe awọn ologun n ya wọ ile eeyan, ti wọn si n ba ọpọ nnkan to dukia wọn jẹ pọ gab.
Dr Eitan Diamond, agbẹjọro nla ni Jerusalem ni biba awọn dukia jẹ jẹ ohun ti ko ba ofin mu.
Ẹsun idunkoko mọ ọmọde pẹlu ọbẹ ni Tulkarm ati awọn yooku ti o ṣeese ko ti tako ofin ajọ agbaye.
Bakan naa ni awọn fẹsun kan ologun pe awọn ṣekupa afurasi to da bi pe o gbe ado oloro lọwọ, ti wọn si tun tọ si lara lẹyin to gba ẹmi rẹ, wọ ni ilẹ gẹgẹ bii oṣojumikoro ṣe sọ.
Wọn fi awọn aworan BBC. A ri apa ẹjẹ, aṣọ ati awọn nnkan ti wọn fi de oku naa ninu aworan nigna ti de ibẹ fun iwadii.














