You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ìlẹ̀kùn kan ni kò padé tán, tí Kìnìún fi jáde dojú kọ obìnrin tó fẹ́ fun ní oúnjẹ - Fásitì OAU
Awọn alasẹ ile ẹkọ Fasiti Obafemi Awolowo, ti sọ kọkọrọ si gbagede ọgba ẹranko to wa ni ọgba ile ẹkọ naa lẹyin ti kiniun, ẹni ọdun mẹsan an ṣekupa ẹni to n tọju rẹ.
BBC Yoruba kan si ile Ẹkọ Fasiti Obafemi Awolowo niluu Ile-ife, lati mọ ohun to waye nipa isẹlẹ laabi to ṣẹlẹ si Ologbe Olabode Olawuyi ẹni ti Kininu pa ní ọjọ Aje ọjọ Kọkandinlogun osu Keji Ọdún 2024.
Nigba to n ba akọroyin BBC sọrọ, Alukoro Fasiti Obafemi Awolowo nilu Ile-ife Abiodun Olarewaju sọ wi pe Isẹlẹ naa jẹ ibanujẹ ọkan fun gbogbo osisẹ ati akẹkọọ Fasiti naa.
Ilẹkun kan lọ́gbà ẹranko ni ko tii tan, lakoko ti wọn n fun Kiniun naa lounjẹ, tó fi ráyè jáde láti jà
O ni Iku oniku ní Ologbe Olabode Olawuyi gba ku.
Alukoro naa tun tesiwaju ninu ọrọ wi pe, Ologbe Olabode Olawuyi ki se oun ni Kiniun naa doju ija kọ.
Arabinrin kan to jẹ osisẹ inu ọgba ẹranko ni Kininu naa doju ija kọ.
Eyi lo mu ki Ologbe Olabode Olawuyi tiraka lati gba Arabinrin naa silẹ lọwọ Kininu naa.
Loju ẹsẹ ni Kininu naa pa oju da si Ologbe Olabode Olawuyi to si pa patapata.
Alukoro Abiodun tun sọ wi pe, Ologbe Olabode Olawuyi ti lo Ogun Ọdun nibi isẹ, bẹẹ naa si ni o ti lo ọdun mẹwaa nibi ti wọn n ti se itọju awọn ẹranko naa.
Lotitọ awọn mejeji ko ṣẹṣẹ maa fun Kininu naa lounjẹ sugbọn, ilẹkun kan ni ko tii tan, lakoko ti wọn fun Kininu naa lounjẹ.
Abiodun Olarewaju tun sọ wi pe, awọn n duro de ẹbí Ologbe Olabode Olawuyi lati mu ọjọ ti wọn yoo se eto isinku Ologbe naa.
BBC Yoruba tun tesiwaju lati ba Ẹbi Ologbe Olabode Olawuyi kẹdun ati lati gba ọrọ lẹnu wọn.
Sugbọn, wọn ko fi aye silẹ fun ohunkohun rara. Oju ija ni wọn gbe pade wa.