UK àti USA ti fi ìkìlọ̀ síta nípa àwọn ẹ̀lẹ́wọ̀n tó sálọ ní Kuje

UK àti USA kìlọ̀ nípa ìpínlẹ̀ tí àwọn eèyàn wọn lè rìnsí ní Nàìjíríà.

Iléeṣẹ́ to n fún àwọn arinrinajo ni físà iwe irinna lorilẹede Amerika ati ni United Kingom ti sọrọ nipa iṣẹlẹ Kuje ni Abuja.

Embásì Amerika ati ti United kingods to wa ni Naijiria ti kilọ fun awọn ọmọ orilẹ-ede mejeeji to n gbe ni Naijiria pe ki wọn ṣọra ṣe lasiko yii.

Wọn tun ni pe ki wọn tẹẹ jẹjẹ ni adugbo ti onikaluku n gbe.

Koda, wọn ni ki wọn maa rin pẹlu kaadi idanimọ wọn nibi gbogbo ki ẹnikẹni ma lọ ṣi wọn mu.

Won tun kilọ pe ki koowa tun ayẹwo ṣe fun awọn oṣiṣẹ alaabo wọn.

Won tun ni pe ki wọn maa tun ero won pa lori akoko irinajo wọn.

Saaju ni United Kingdom ti kolọ fun awọn ọmọ orilẹ-ede wọn pe ki wọn ṣọra lilọ si ipinlẹ mọkandinlogun ni Naijiria.

Awọn ipinlé naa ni Yobe, Borno, Adamawa, Gombe, Kaduna, Katsina, Zamfara, Delta, Bayelsa, Rivers, Akwa Ibom ati Cross River.

Bakan naa ni wọn tun kilo pe irinajo to ba se koko nikan ni ki wọn rin lọ si awọn ipinlẹ bii Bauchi, Kano, Jigawa, Niger, Sokoto, Kogi, ati Abia.

Wọ́n ti ṣí aṣọ lójú eégún àwọn ọmọ Boko Haram tó sá kúrò ní Kuje

Ọmọ ẹgbẹ́ Boko Haram 68 ni orúkọ tiléeṣẹ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n fi síta báyìí kí ará ìlú lè dá wọn mọ̀

Ileeṣẹ ijọba Naijiria to n moujto ọrọ ọgab ẹwọn ti ṣi aṣọ loju eegun awọn ọmọ ikọ Boko Haram ti wọn sa kuro ni ọgba ẹwon Kuje lẹ́yìn ìkọlu to mu ẹmi awọn eeyan lọ.

Orukọ awọn mejidinlaadọrin ni wọn fi sita pẹlu aworan idanimọ wọn.

Laarin awón elẹ\on 879 to sa kuro lalẹ ọjọ Iṣẹgun to kọja yii ni agbenusọ ileeṣẹ ijoba, Umar Abubakar sọrọ lori wọn fun BBC.

Umar sọ pe ọwọ ti tẹ oji le nirinwo o le mẹta ninu wọn pada ti wọn si ti pada si ọgba ẹwọn bayii.

Ati pe wọn si n wa awọn to ku pelu gbogbo ọna to ba yẹ.

Akowe agba ileeṣẹ ijọba apapọ naa, Shuahib Belgore salaye pe awọn oniṣẹ ibi Boko haram lo ṣiṣẹ naa.

Ni bayii awọn aworan ati orukọ wọn naa lo ti jade bayii.

Ikọ̀ agbẹ́sùnmọ̀mí ISWAP ní àwọn ló wà ní ìdí ìkọlú sí ọgbà ẹ̀wọ̀n Kuje

Ikọ agbesunmọmi ti Islamic State West Africa (ISWAP) ti kede pe awọn lo wa ni idi ikọlu to waye ni ọjọ Iṣẹgun ni ọgba ẹwọn Kuje ni ilu Abuja.

Ninu fiido ti ẹgbẹ agbesunmọmi naa fi sita ni wọn ti ṣafihan bi awọn ẹlẹwọn naa ṣe n sa kuro ninu ọgba ẹwọn ti awọn agbesunmọmi naa si n ke ‘Allahu Akbar’.

Iswap lo jẹ ọkan lara igun Boko Haram to yapa, ti wọn si ti n dunkoko ni iha Ariwa orilẹede Naijiria fun bi ọdun mẹwa bayii.

Ni ilẹ Afrika to fi mọ Lake chad ni ikọ ISWAP n tiraka lati gbajọba ni ibẹ pẹlu ifọwọsowọpọ ẹgbẹ agbẹsunmọmi Islamic State ni agbaye.

Ọgọgọrun awọn ẹlẹwọn ni awọn to ṣekọlu naa tu silẹ lasiko ikọlu ọhun.

Ọkan lara awọn oṣiṣẹ ọgba ẹwọn naa ni ẹlẹwọn to le ni irinwo (443) ni wọn ti ri pada ti awọn eniyan to wa ninu ọgba ẹwọn naa to le ni irinwo ọhun si ti salọ.

Nibayii, o kere tan ọmọ ẹgbẹ ikọ Boko Haram to le ni ọgọta ni wọn n wa bayii lẹyin ikọlu ọhun to ṣeeṣe ko niiṣe pẹlu titu awọn eniyan wọn silẹ ni ọgba ẹwọn naa.

Amọ ninu fidio ti ikọ agbesunmọmi naa fi sita ni wọn ti fi idi rẹ mulẹ pe awọn gan an lo wa ni idi ikọlu naa.

Iwadii fihan pe niṣe ni awọn agbesunmọmi naa yin ado oloro lu irin to wọle sinu ọg̣ba ẹwọn naa ti wọn fi raye wọle si ibẹ.

Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọgba ẹwọn ni Naijiria , Umar Abubakar ni oṣiṣẹ Ajọ eleto aabo NSCDC kan, Inspector Illyasu Abraham , agbesunmọmi mẹta ati ẹlẹwọn mẹrin lo ku ninu ikọlu naa.

Ikọlu ọhun waye lẹyin wakati diẹ ti awọn agbebọn ṣe ikọlu si ọkọ aarẹ Muhammadu Buhari to n lọ si Daura, to gbe awọn ẹṣọ alaabo ati awọn akọroyin aarẹ.