Ilé ẹjọ́ gbé ìdájọ́ kalẹ̀ lórí bí CBN ṣe ń fi Arabic kọ nǹkan sí ara owó Naira

Ile ẹjọ giga ti ijọba apapọ to wa nipinlẹ Eko, ti dajọ lori ẹjọ to ni ko da banki apapọ Naijiria, CBN, lẹkun fifi ede Arabic kọ nnkan si ara owo Naira.

Agbẹjọro kan, Malcolm Omirhobo, lo pe ẹjọ naa lọdun 2020, pẹlu awijare pe fifi Arabic kọ nnkan si owo lara n tọka si Naijiria gẹgẹ bii orile-ede ẹlẹsin Islam.

O ni eyi tako ofin to ni orile-ede naa kii ṣe ti ẹlẹsin kan ṣoṣo.

Ṣugbọn ninu idajọ to ṣe lọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Keje, ọdun 2024, Onidajọ Yellin Bogoro, sọ pe Omirhobo kuna lati fidirẹ mulẹ pe, erongba CBN jẹ ọna lati sọ Naijiria di ti ẹsin Islam.

Ninu awijare rẹ, Ọgbẹni Omirhobo ṣalaye pe oun ko mọ nnkan ti ede Arabic to wa lara awọn owo ti Naijiria n na tumọ si.

O ni ki ile ẹjọ paṣẹ fun banki CBN lati parọ ede naa si Gẹẹsi, tabi si eyikeyi ninu ede Hausa, Igbo tabi Yoruba.

Agbẹjọro Omirhobo fẹ ki ile ẹjọ da CBN lẹkun lati maa buwọlu, tẹ tabi pin owo Naira ti wọn fi Arabic kọ nnkan si lara.

Sugbọn CBN pe ẹjọ tako o.

Agbẹjọro banki naa, Abiola Lawal, sọ fun ile ẹjọ pe, ede Arabic and to wa lara awọn owo naa ko tii fi igba kankan dunkooko mọ iduro Naijiria gẹgẹ bii orile-ede ti kii ṣe ti ẹlẹsin kan.

"Ede Arabic to wa lara owo Naira ko tumọ si ọrọ ẹsin kankan tabi tọka si ibaṣepọ pẹlu ilẹ Arab.

"Ijọba amunisin fi ede Arabic kọ nnkan si ara owo Naira, fun anfaani awọn ọmọ Naijiria ti ko mọ iwe ka, nitori pe iru awọn eeyan bẹẹ lo pọ ju lasiko ti wọn pa owo Naijiria da si Naira dipo Pọnhun to n na tẹlẹ.

Ile ẹjọ ti da ẹjọ naa nu bayii nitori pe Omirhobo 'kuna lati fidi awijare rẹ mulẹ pẹlu ẹri".