You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Fídíò ṣàfihàn bí àwọn ọ̀dọ́ ṣe ń lùwẹ̀ẹ́ nílé Ààre lẹ́yìn tí wọ́n yabò ọ́, wo bí ààrẹ ṣe fẹ́ kọ̀wé fipò sílè torí èyí
Aarẹ orilẹede Sri Lanka, Gotabaya Rajapaksa ti kede pe oun yoo kọ iwe fi ipo silẹ.
Aarẹ Rajapaksa gbe igbesẹ yii lẹyin ti awọn araalu ni ọgọọrọ ṣe ifẹhọnuhan yabo ile rẹ.
Bakan naa ni awọn afẹhọnuhan naa da ina sun ile olootu ijọba.
Awọn afẹhọnuhan naa ti wọn yabo ibẹ ni ẹgbẹgbẹrun wọn fi ẹsun kan Aarẹ Rajapaksa pe asilo owo ijọba lo mu ki oro aje orilẹede naa dẹnu kọlẹ.
Igba akọkọ kọ ni yii ti awọn araalu yoo maa fi ẹhọnuhan tako bi ijọba ṣe n ṣe ọrọ aje wọn
Kii ṣe igba akọkọ ni yii ti awọn araalu yoo maa fi ẹhọnuhan tako bi ijọba ṣe n ṣe ọrọ aje orilẹede naa, ti wọn si n fi apa janu.
Amọ Abẹnugan ile aṣofin orilẹede naa to kede ni aarẹ yoo fi ipo silẹ ni Ọjọ Kẹtala, Oṣu Keje, ọdun yii, ti olootu ijọba naa si ti gba lati fi ipo silẹ.
O ni aarẹ gbe igbesẹ naa ki alaafia le jọba, ti oun yoo si gbe ijọba silẹ ni irọwọrọsẹ.
Bakan naa ni wọn kesi awọn araalu naa lati bọ ọwọ fun ofin orilẹede naa.
Were ti awọn araalu gbọ eyi ni wọn bẹrẹ si ni fo fun ayọ kaakiri orilẹede naa pẹlu fere lorisirisi.
Aarẹ orilẹede Amerika, Joe Biden naa ti kesi awọn alaṣẹ orilẹede Sri Lanka lati ri pe wọn wa atunṣe si eto ọrọ aje wọn to dẹnukọlẹ ni kiakia.