Ẹ bá wa sọ̀rọ̀, ààyè ṣì wà fún ìjíròrò - Àwọn Gómìnà 'G5'

Awọn gomina marun un lati inu ẹgbẹ oṣelu PDP ti wọn pe ara wọn ni G5 sẹpade pọ pẹlu awọn igun ẹgbẹ oṣelu ọhun ni ipinlẹ Eko ṣaaju eto idibo ti yoo waye lọdun 2023.

Ipada alatilẹkunmọriṣe naa lo waye ni ile igbakeji alaga ẹgbẹ tẹlẹ, Oloye Bode George, ti wọn si kede pe awọn ti ni orukọ tuntun fun ajọse awọn gomina naa, eyi ti wọn pe ni ‘Integrity Group’.

Bakan naa ni awọn gomina ọhun ṣalaye pe aye si wa fun ijiroro ti yoo fi opin si gbogbo rogbodiyan to n waye lọwọ ninu ẹgbẹ oṣelu naa.

Gomina tẹlẹ nipinlẹ Plateau, Jonah Jang ba awọn akọroyin sọrọ pe igun ẹgbẹ yii ti fi aye silẹ fun ijiroro ti yoo fi opin si rogbodiyan inu ẹgbẹ naa.

“A wa ti a wa ni ipade yii ti ṣetan lati duro lori esi ipade wa ni Port Harcourt. A tun wa sọ lẹẹkan sii pe aye wa fun ijiroro to mu alaafia wa ninu ẹgbẹ oṣelu wa.”

Gbogbo awọn agba ẹgbẹ lo ti wa lẹyin- Makinde

Gomina Seyi Makinde ti ipinlẹ Oyo ṣalaye pe awọn gomina G5 ni wọn le waju ninu ifẹhonuhan naa ti wọn si ri itẹwọgba lọwọ awọn agba ati olori ẹgbẹ oṣelu PDP.

“G5 jẹ igun ẹgbẹ PDP to nifẹ si ilọsiwaju ẹgbẹ. Ẹ ri wa, awa gomina marun-un to n ṣe ijọba lọwọ, ti a si n lewaju ninu bibeere ohun to yẹ, ti awọn agba ati adari si wa pẹlu wa ninu ija yii.

“A wa si ibi bayi laarọ yii lati yanana gbogbo laasigbo ẹgbẹ oṣelu wa ati bi nnkan yoo ṣe wa ninu eto idibo to n bọ.

Awọn to wa nibi ipade pẹlu wọn ni gomina ana nipinlẹ Ekiti, Ayo Fayose, gomina ana nipinlẹ Cross River, Donald Duke ati gomina ana nipinlẹ Plateau, Jonah Jang.

Awọn yooku ni Taofeek Arapaja, Oloye Dan Orbih, Sẹnẹtọ Olaka Nwogu, Sẹnẹtọ Mao Ohuabunwa, Sẹnẹtọ Nasif Suleiman ati awọn ekan mii

Kini G5 n bere lọwọ ẹgbẹ oṣelu PDP?

Awọn gomina marun-un ọhun to pe ara n ni G5, Nyesom Wike ti Rivers, Seyi Makinde ti ipinlẹ Ọyọ, Samuel Ortom lati ipinlẹ Benue, Okezie Ikpeazu ti Abia, ati Ifeanyi Ugwuayi ti Enugu ni ki Iyorchi Ayu to jẹ alaga ẹgbẹ naa fi ipo si gẹgẹ bii alaga ẹgbẹ PDP.

Eyi kọ ṣẹyin bi oludije ṣipo aarẹ ẹgbẹ naa, Atiku Abubakar ati alaga ẹgbẹ se wa latikun orilẹede kan naa.

Ṣugbọn, Ayu fi apa janu pe oun yoo pari saa oun gẹgẹ bi alaga ẹgbẹ naa.

Eleyi lo mu ariyanjiyan ati awuyewuye wa wi pe awọn ẹgbẹ G5 nja fun etọ.