Falcons wọ ìpele Round of 16 ní ìdíje ife ẹ̀yẹ àgbáyé lẹ́yìn ọ̀mì 0-0 pẹ̀lú Ireland

Awọn agbabọọlu NAijiria n yọ mọ ara wọn

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ikọ agbabọọlu obinrin agba fun Naijiria, Super Falcons ti moribọ wọ ipele keji idije ife ẹyẹ agbaye fawọn obinrin, eyi to n lọ lọw lorilẹede Australia ati New Zealan.

Ọmi olodo ni Falcons ta pẹlu akẹgbẹ rẹ latorilẹede Ireland.

Bi o tilẹ jẹ wi pe ọpọ anfani lo sodo fun Super Falcons lati bori ifẹsẹwọnsẹ naa, ṣugbọn akitiyan aṣọle Ireland ko jẹ ki wọn ni aṣeyọri kankan.

Pẹlu esi ifẹsẹwọnsẹ naa, ikọ Super Falcons lo wa ni ipo keji ni ipin B idije naa lẹyin ti Australia bori Canada pẹlu goolu mẹrin si odo.

Super Falcons yoo maa koju ẹni to ba leke ipin D laarin England, Denmark ati China.

Australia yoo maa koju ẹni to ba ṣe ipo keji ni ipin naa.

Wo bí ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ Super Falcons Nàìjíríà àti republic of Ireland ṣe ń lọ sí
Aworan agbabọọlu NAijiria ati Ireland

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ikọ agbabọọlu obinrin agba orilẹede Naijiria, Super Falcons ti bẹrẹ si ni waako pẹlu awọn akẹgbẹ wọn lati orilẹede Ireland.

Super falcons nilo ọmi ninu ifẹsẹwọnsẹ yii lati tẹsiwaju si ipele ikeji idije ife ẹyẹ agbaue to n lọ lọwọ ni orilẹede Australia ati New Zealand.

Agogo mọkanla owurọ ni ifẹsẹwọnsẹ naa bẹrẹ.

Aṣọ alawọ ewe ni ikọ Falcons wọ ti awọn Ireland si wọ aṣọ alawọ funfun.

Bi Falcons ba bori ifẹsẹwọnsẹ naa, a jẹ wi pe awọn lo bori ipin wọn to jẹ ipin B.

Awọn agbabọọlu igun mejeeji

Naijiria :

Nnadozie, Plumptre, Ohale, Payne, Oshoala, Ucheibe, Kanu, Demehin,Ajibade, Ayinde, Alozie.

Awọn Arọpo:

Oluehi, Balogun, Ogbonna, Ebi, Onumonu, Oparanozie, Monday, Ordega, Echegini, Imuran, Okoronkwo.

Republic of Ireland:

Brosnan, Payne, Fahey, Louise Quinn, Connolly, McCabe (c), Littlejohn, O'Sullivan, Agg, Farrelly, Carusa.

Awọn arọpo:

Moloney, Walsh, O'Riordan, Mustaki, Caldwell, Barrett, O'Gorman, Lucy Quinn, Larkin, Sheva, Grant, Atkinson.