You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Wo bí o ṣe le dènà kí MTN, Glo, Airtel àti 9mobile gbégi lé síìmù rẹ nítorí ọ̀rọ̀ NIN
O kere tan, ogoji miliọnu ọmọ Naijiria ti wọn ko tii so nọmba foonu pọ mọ kaadi idanimọ NIN wọn ni wọn ti ja kuro lórí ila ipe bayii.
Ọjọ kejidinlogbon, oṣu Keji, ọdun 2024, ni ajọ NCC to n mojuto eto ibaraẹnisọrọ ni Naijiria sọ fawọn ileeṣẹ ẹrọ ibanisọrọ pe awọn onibara gbọdọ so nọmba foonu pọ mọ ti NIN wọn.
Awọn eeyan to kuna lati ṣe bẹẹ l'awọn ileeṣẹ ẹrọ ibanisọrọ ti ja danu bayii loju opo ipe lopin ọsẹ to kọja, gẹgẹ bi aṣẹ ti ajọ NCC fun wọn.
Bi iye awọn eeyan naa ṣe wa to ogoji miliọnu bayii lo ya ọpọ eeyan lẹnu tori bii miliọnu mejila eeyan ni a gbọ tẹlẹ wi pe igbesẹ yii yoo ṣakoba fun.
Oṣu Kejila, ọdun 2023 ni ajọ NCC paṣẹ fun awọn ileeṣẹ ẹrọ ibanisọrọ wi pe ki wọn ja ẹnikẹni ti ko ba so nọmba foonu rẹ pọ mọ NIN lẹyin ọjọ kejidinlogbon oṣu Keji, ọdun 2024.
Ṣaaju ni ọga agba lori ọrọ to n lọ ni ajọ NCC, Reuben Mouka kede pe ajọ naa ko ni sun gbedeke naa siwaju.
Alaga ajọ ALTON to n ri si ọrọ awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ ẹrọ ibanisọrọ, Gbenga Adebayo ṣalaye pe awọn eeyan ti wọn ti ja kuro lori ila ipe pe ogoji miliọnu nitori ọpọ ninu wọn ni ko tiẹ tii forukọ silẹ fun kaadi idanimọ NIN rara.
Ki wa lo lee ṣe?
Akọṣẹmọṣẹ ọhun ni ohun ti ẹni ti ọrọ yii ba kan le ṣe ni ko kọkọ lọ si ọfiisi ileeṣẹ ibaraẹnisọrọ eyi ti o n lo.
Bakan naa lo ni ajọ Telcos tii ṣe apapọ gbogbo awọn ileeṣẹ kii fẹ ki siimu eeyan kankan di gbegi le tori ko pe wn.
"O maa n jẹ ka padanu owo ati ere to n wọle ni".
O wa ṣalaye pe awọn awọn ileeṣẹ ibaraẹnisọrọ nilo onibara to pọ gidi.
Lati ma si jẹ ki wọn padanu onibara, wọn n tẹsiwaju lati rọ awọn eeyan ki wọn wa si ọfiisi wọn.
Murtala Muhammed to jẹ adari ajọ NIMC ti Masalacin Murtala ni Kano naa fi aridaju ọrọ yii han.
O sọ fun BBC pe: "Bi wọn ba gbegi le siimu rẹ, lọ taara si ọfiisi ileeṣẹ siimu naa lati sọ fun wọn.
Ileeṣẹ Telco naa yoo fun ni iwe ti yoo mu lọ si ajọ NIMC lati ibẹ ni wọn yoo ti gbe ọrọ rẹ lori lọdọ ikọ to n bojuto akọsilẹ wọn".
Ohun to o nilo lati forukọ silẹ
To o ba ti fẹ forukọ NIN rẹ silẹ lorii foonu rẹ ohun too nilo niyii:
- Nọmba foonu rẹ
- Orukọ rẹ lẹkunrẹrẹ
- Nọmba NIN rẹ (eyi too le yẹwo nipa lilo *346#)
- Atẹjiṣẹ Email rẹ
- Ọjọ ibi rẹ
To o ba fẹ́ so NIN pọ mọ Nọmba MTN
- Lọ si oju opo ti NIN ṣi fun onibara lati ṣe e https://mtnonline.com/nin/
- Oo nilo fọọmu ti oo kọ orukọ rẹ si
- Kọ nọmba MTN rẹ sibẹ
- Kọ NIN rẹ sibẹ
- Kọ adirẹsi Email rẹ
- Tẹ bọtini ti wọn kọ SUBMIT si
- Bakan naa o le tẹ nọmba *785#
- Ẹrọ foonu rẹ yoo beere pe ko kọ nọmba idanimọ NIN rẹ ko si tẹ ẹ jiṣẹ.Yoo sọ fun o pe o ti pegede nigba to ba fi ranṣẹ tan.
To o ba fẹ́ so NIN pọ mọ NọmbaGLO
- Kọ ọrọ Update NIN (fi alafo si) NIN (alafo) Orukọ rẹ akọkọ (alafo) ati orukọ baba rẹ si nọmba 109.
- Too ba fẹ́ so NIN pọ mọ NọmbaAirtel
- Igbesẹ naa lọ bayi nipa titẹ *121*1#
- Kọ nọmba idanimọ NIN rẹ
- Lẹyin naa wa ri atẹjiṣẹ pe o ti yege
- Too ba fẹ́ so NIN pọ mọ Nọmba 9 Mobile rẹ
- Kan si oju opo https://9mobile.com.ng/nin
- Tẹ aaye alawọ ewe ti wọn kọ ọrọ 'verify and link your NIN now'
Ẹgbẹ awọn onibara ileeṣẹ ẹrọ ibanisọrọ morile ile ẹjọ
Aare ẹgbẹ awọn onibara ileeṣẹ ẹrọ ibanisọrọ, Adeolu Ogunbanjo ti sọ pe awọn yoo gbe ọrọ naa lọ si ile ẹjọ.
Ogunbanjo rọ ajọ NCC lati fawọn eeyan ni oṣu kan sii ki wọn le ni anfaani lati so nọmba foonu pọ mọ NIN wọn.
Nínú ifọrọwanilẹnuwo ti o ṣe pẹlu iwe iroyin Punch, Ogunbanjo ni "ti NCC ba kọ lati fawon eeyan di ipari oṣu Kẹta yii , a jẹ wi pe a o gbe wọn lọ si ile ẹjọ lori ọrọ naa.
Ọdun 2020 ni ijọba apapọ ṣe agbekalẹ eto naa pe ki araalu so nọmba NIN pọ mọ ti foonu wọn lati ṣe iranwọ fawọn ẹṣọ eleto aabo ti wọn ba fẹ mu ọdaran.
Amọ, ọpọ ọmọ Naijiria lo ti kọminu lori bi awọn agbofinro ko tii maa lo anfaani siso nọmba foonu pọ mọ NIN, paapaa bi awọn ajinigbe ṣe n fi foonu beere owo itusile lọwọ ẹbi awọn ti wọn ji gbe.
Ojilerugba le mẹrin miliọnu eeyan lo ni nọmba foonu ni Naijiria gẹgẹ bi ajọ NCC ṣe sọ.
Agbẹnusọ ajọ NIMC to n ri si kaadi idanimọ NIN, Kayode Adegoke ṣalaye pe mílíọ̀nù mẹrinlelọgọrun ninu wọn lo tii forukọ silẹ fún NIN.