Ààrẹ tuntun ní Liberia fẹ́rẹ̀ dákú níbi ètò ìbúra rẹ̀

Aarẹ tuntun lorilẹede Liberia, Joseph Boakai ko le ba wọn pari ayẹyẹ ibura wọle si ipo to waye fun un lọjọ Aje.

Koda, Aarẹ Boakai ko le pari ọrọ apilẹkọ rẹ akọkọ to n ka nibi ayẹyẹ naa gẹgẹbi aarẹ tuntun fun orilẹede Liberia ki wọn to di i mu nigba ti o dabi ẹni pe oyi n kọ ọ.

Nibi eto iburawọle ti wọn ṣe fun un ni ilu Monrovia tii ṣe olu ilu orilẹede Liberia, aarẹ tuntun naa ti n sọrọ fun bii ọgbọ iṣẹju ki awọn amugbalẹgbẹ rẹ to ṣakiyesi pe ati sọ ọrọ n di iṣoro fun un.

Awọn amugbalẹgbẹ rẹ atawọn ẹṣọ alabo rẹ ni wọn sare rọgba yii ka ti wọn si gbe e kuro ile ‘Capitol Building’ to jẹ ile igbimọ aṣofin apapọ orilẹede naa nibi ti eto naa ti n waye.

Wọn ni lati ṣẹwe le eto naa lẹyẹ o ṣọka ni.

Iroyin to n lọ kaakiri ṣaaju eto iburawọle naa ni pe ilera Aarẹ Boakai, ẹni ọdun mọkandinlọgọrin naa ku diẹ kaa to.

N o ta ireti araalu ji – Aarẹ tuntun lorilẹede Liberia

Amọṣa ninu iwọnba ọrọ to le sọ ki oyi to bẹrẹ si nii kọ nibi eto naa, Aarẹ, Boakai ni afojusun iṣejọba oun ni lati ji ireti araalu ninu ijọba ati idagbasoke orilẹede naa.

“Eto idibo ti pari, ipinya labẹ ẹgbẹ oṣelu gbọdọ yago fun ilọsiwaju orilẹede Liberia.

“Bi awọn ọmọ orilẹede Liberia ṣe duro ṣinṣin ti ibo wọn fihan pe ko si aye ko maa lọ bii ti tẹlẹ mọ.

“Mo wa lati tun ina ireti araalu da.”

Lara awọn eekan ilu to wa nibi eto ibura naa ni aarẹ to n fipo silẹ lorilẹede Liberia, George Weah atawọn eekan lati oke okun.

Lara wọn ni aarẹ orilẹede Ghana, Nana Akufo-Addo ati aṣoju ijọba orilẹede Amẹrika ni ajọ iṣọkan agbaye, Linda Thomas-Greenfield.