Ọ̀pọ̀ ogun ló dìde sí mi àmọ́ mo gbá Èṣù lójú – Olorì Naomi

Woli Naomi Silekunola, olori tẹlẹ fun Ooni tí ile ifẹ, Oba Adeyeye Ogunwusi ti ni oun gba eesu lẹsẹ loju ninu irinajo aye rẹ.

Olori tẹlẹ ọhun lo sọ eleyi yii lasiko to n ki ara rẹ ku ọjọbi ọgbọn ọdun lori opo ayelujara Instagram lọjọ Satide, to si sapejuwe ọjọọbi naa gẹgẹ bii ọrẹ ọfẹ Ọlọrun.

O tẹsiwaju pe ọdun mọkandinlọgbọn sẹyin ni oun ti n gba ra di fun ojọbi naa ati ọjọ iwaju.

"Irinajo yii rẹwa pupọ, n ko gbagbọ pe o ti pe akasọ kẹta, Ọlọrun dara simi."

"Akasọ ọdun mewaa ni igba mẹta yii ko waye laisi pe aye dan mi wo sugbọn pẹlu ọrẹ ọfẹ Ọlọrun mo gba Satani lẹsẹ loju, n jẹ ko ki n ṣe aanu Ọlọrun bi?

"Mo ranti gbogbo nnkan ti mo ṣe sẹyin, ọdun mọkandinlọgbọn sẹyin ni mo fi gbaradi fun asiko yii ati ọjọ ọla."

Naomi ni ọdun tuntun yii, oun yoo tẹra mọ ṣiṣe iranlọwọ fun awọn eeyan ju ti tẹlẹ lọ.

Ni iparí, Naomi ranṣẹ ikini si awọn mọlẹbi ati awọn ololufẹ rẹ fun bi wọn ṣe duro ti oun lasiko iṣoro.