You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
PDP fi ìwé ẹ̀rí yíyọ kúrò nínú ẹgbẹ́ ránṣẹ́ sí Wike, Fayose àti àwọn yòókù
Ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party ti fi iwe ẹri, eyi to fọwọ osi juwe ile fun Minisita fun olu ilu Naijiria, Nyesome Wike, Gomina ipinlẹ Ekiti nigba kan ri, Ayodele Fayose ati awọn yooku ti wọn yọ kuro ninu ẹgbẹ lasiko ipade apero ẹgbẹ naa to waye niluu Ibadan nipinlẹ Oyo.
Gẹgẹ bii o ṣe wa ninu atẹjade kan ti PDP fi lede loju opo ayelujara X wọn, iwe ẹri naa ni wọn fi sita lọjọ keji oṣu kọkanla ọdun 2025 niluu Abuja, nibi ti adele alaga ẹgbẹ naa, Umar Damagum ti gbe agbara fun alaga tuntun, Sẹnetọ Kabiru Turaki.
Bẹẹ ba gbagbe, ẹgbẹ oṣelu PDP, lọjọ Kẹrindinlogun oṣu Kọkanla lasiko ipade apero, fọwọ osi juwe ile fun Wike ati awọn yooku lori ẹsun pe wọn n ditẹ mọ ẹgbẹ oṣelu PDP.
Nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ, Turaki ni awọn ṣe atunyẹwo igbesẹ ti awọn gbe lasiko ipade apero lori lile awọn ọmọ ẹgbẹ kan lọ.
O ni, "A mọ pe ofin orilẹede Naijiria ko faye gba ki eeyan ṣe ẹgbẹ oṣelu meji, idi ree ti a fi mu rọrun fun wọn pe ki wọn kuro ninu ẹgbẹ oṣelu wa.
"Ni bayii, wọn ki n ṣe ọmọ ẹgbẹ wa mọ, ti igun olori ẹgbẹ wa, si ti fọwọ osi juwe ile fun wọn, ti a si tun pinnu pe ka fun wọn ni iwe ẹri.
"Bakan naa, ti wọn ba lọ si ẹgbẹ oṣelu miiran ni Naijiria, wọn yoo ni anfani lati fi iwe ]eri wọn han pe awọn ki n ṣe ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP mọ, ti awọn ẹgbẹ oṣelu naa ko si ni ma ṣe iye meji pe boya wọn si wa ninu ẹgbẹ oṣelu PDP."
Gẹgẹ bii o ṣe ṣalaye, awọn iwe ẹri yii ni awọn ti fi ranṣẹ si onikaluku ti ọrọ kan; Nyesom Wike, Gomina ipinlẹ Ekiti nigba kan ri, Ayodele Fayose; Sẹnetọ Samuel Anyanwu; Umaru Bature; Kamarudeen Ajibade (SAN); Abdurahman Muhammad; Sẹnetọ Mao Ohuabunwa; Austin Nwachukwu; Abraham Amah Nnanna; George Turna; ati Oloye Dan Orbih.
Turaki ni igbesẹ yii ṣe koko lati fi to awọn ọmọ Naijiria ati paapa ajọ INEC leti lori ipo ti onikaluku wa lasiko yii
O ni ileeṣẹ ọlọpaa, ajọ DSS, ajọ NSCDC ati awọn ikọ agbofinro yooku ni lati mọ pe awọn eeyan ti wọn darukọ yii ko si ninu ẹgbẹ wọn mọ
"A ti fun wọn ni iwe ẹri, ti a si ti fi ransẹ si wọn nibi ki ti wọn ba wa."
Turaki fikun pe lọwọ yii, ẹgbẹ oṣelu PDP n ṣe gbogbo atunṣe to nilo lati pada si ipo oke tente to wa tẹlẹ, ti yoo si gba awọn ọmọ Naijiria silẹ lọwọ ijọba to n mu inira wa si ilu.
Ta ni Kabiru Tanimu Turaki tí wọ́n yàn bíi alága ẹgbẹ́ òṣèlú PDP
Ní ọjọ́ Kẹta, oṣù Kẹrin ọdún 1957 ni wọ́n bí Kabiru Tanimu Turaki tó di alága ẹgbẹ́ òṣèlú PDP.
Ó kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìmọ̀ òfin ní ilé ẹ̀kọ́ University of Jos, tó sì kẹ́kọ̀ọ́ jáde lọ́dún 198, tí wọ́n sì pè é gẹ́gẹ́ bí aṣòfin lọ́dún 1986.
Ọdún 2002 ló di amòfin àgbà, tó sì di alága iléeṣẹ́ amòfin rẹ̀, KT Turaki & Co. lọ́dún kan náà.
Ó ṣe mínísítà fún àkànṣe iṣẹ́ lábẹ́ ìṣèjọba Ààrẹ Goodluck Jonathan láàárín ọdún 2013 sí 2015.
Bákan náà ló tún ṣe aṣojú mínísítà fọ́rọ̀ iṣẹ́, tó sì tún ṣe alága ìgbìmọ̀ tó ń pè fún àlááfíà ní ẹkùn àríwá Nàìjíríà.
Kó tó di alága ẹgbẹ́ òṣèlú PDP, ó díje dupò ààrẹ lọ́dún 2018 ṣùgbọ́n tí kò rí ipò náà, tó sì ṣe alága fáwọn mínísítà tẹ́lẹ̀ rí lẹ́gbẹ́ PDP.