You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Mọ̀ síi nípa àbá fún ìdásílẹ̀ ìpínlẹ̀ Ibadan àti Oyo tuntun
Aba fun idasilẹ ipinlẹ Oyo tuntun, pẹlu ilu Ọyọ gẹgẹbi olu ilu rẹ ni wọ ti ka fun igba keji bayii ni ile igbimọ aṣojuṣofin Naijiria.
Họnọrebu Adeniyi Adeyemi to n ṣoju fun ẹkun ati awọn mẹfa mii se onigbọwọ fun ni ki wọn sọ awọn agbegbe yooku ni ipinlẹ Ibadan, eyi ti yoo sọ ilu ibadan ni olu ilu fun.
Ninu alaye rẹ, Hon Adeyemi ni aba yii ko jẹ tuntun ni ile igbimọ aṣofin, to si ranti pe aba yii ni wọn ti kọkọ buwọlu ni ile igbimọ aṣofin mejeeji sugbọn ileeṣẹ Aarẹ to wa ni ijọba lasiko naa ko buwọlu kkii ijọba ologun to gba ijọba.
Awọn ijọba ibilẹ ti yoo wa labẹ ipinlẹ Oyo tuntun yii ni ijọba ibilẹ, Afijio, Atiba, Atisbo, Ogo Oluwa, Irepo, Iseyin, Itesiwaju, Iwajowa, Kajola, Ori Ire, Olorunsogo, Oorelope, Ila oorun Oyo, iwọ oorun Oyo, Ila oorun Saki, iwọ oorun Saki, Surelere, Ariwa Ogbomoso, Guusu Ogbomoso.
Wọnyi ni awọn ijọba ibilẹ ti yoo wa ni abẹ ipinlẹ ibadan tuntun; Akinyele, Egbeda, Ariwa Ibadan, Guusu ila oorun Ibadan, Ariwa ila oorun Ibadan, Ariwa iwọ oorun Ibadan, Lagelu, Oluyole, Ona Ara, Ido, ila Oorun Ibarapa, Aarin gbogbo ila oorun Ibarapa ati Ariwa Ibarapa.
Ki ni ofin sọ nipa idasilẹ ipinlẹ tuntun?
Ile ofin orilẹede Naijiria faye gba idasilẹ ipinlẹ tuntun ti awọn igbeṣe ba ti le jẹ gbigbe.
Ile igbimọ aṣofin orilẹede yoo buiwọlu idasilẹ ipinlẹ ti awọn aṣofin ile igbimọ aṣofin toto ida mẹta ba pe fun idasilẹ naa.
Awọn aṣofin yii ni wọn yoo wa lati ilẹ igbimọ aṣofin agba ati kekere, ile igbimọ aṣofin ipinlẹ ati awọn aṣofin ni ijọba ibilẹ.
Bakan naa ni wọn yoo pe se awọn ijọba ibilẹ ti yoo wa labẹ ipinlẹ pẹlu iwe aṣẹ lati ọwọ ọmọ ile igbimọ aṣofin nipinlẹ
Ki lo ti sẹlẹ saaju?
Adeyemi ṣalaye pe ile igbimọ aṣofin ni ọdun 1983 ti kọkọ buwọlu idasilẹ ipinlẹ Oyo tuntun, eyi ti ilu Oyo yoo jẹ olu ilu fun.
Bakan naa ni o ni ipade apero orilẹede Naijiria, eyi ti o waye ni ọdun 2014 naa gba aba naa wọle pe ki wọn da ipinlẹ Oyo tuntun silẹ.
“O wa nini iwe ipade pe ki wọn pin ipinlẹ Oyo si meji nitori bi o ṣe jẹ ọkan ninu awọn ipinlẹ to tobi ju lorilẹede Naijiria.
“Idasilẹ ipinlẹ yii ni gbogbo elo lati jẹ ọkan ninu awọn ipinlẹ ti yoo le da duro.