You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Oluomo àtàwọn méjì míì fojú ba ilé ẹjọ́ lórí ẹ̀sùn lílu ₦2.5b ní pońpó
Olori ile igibimọ aṣofi ipinlẹ Ogun ti wọn yọ nipo, Olakunle Oluomo, atawọn meji mii ti foju bale ẹjọ niluu Abeoukuta.
Ajọ to n gbogun ti iwa ajẹbamuni Naijiria, EFCC, lo gbe Oluomo lọ sile ẹjọ giga kan to wa ni Oke Mosan, niluu Abeokuta, lori ẹsun lilu owo ti iye rẹ to biliọnu meji abọ naira ni ponpo.
Oluomo toun ati Dayo Samuel, to fi mọ Adeyemo Adedeji ni wọn jọ n jẹjọ ọhun.
EFCC ni awọn afurasi naa wu iwa ọdaran naa lasiko ti Oluomo jẹ olori ile aṣofin ipinlẹ lọdun 2022.
Ọmọ ile mejidinlogun ninu mẹrindinlọgbọn lo tọwọ bọwe pe ki wọn yọ Oluomo bii jiga kuro nipo olori ile igbimọ aṣofin ọhun.
Lara ẹsun ti wọn fi kan an ni aṣilo ipo, iwa tani yoo mu mi ati kikọ ẹyin awọn ọmọ ile sira wọn.
Amọ oun furan rẹ ti gba ile ẹjọ lọ bayii lati pe iyọnipo rẹ ọhun nija.
Lọjọ Aje ni awọn afurasi mẹtẹta lọ kawọ pọn rojọ niwaju adajọ O.O Okeke ṣugbọn agbẹjọro EFCC ko yọju sile ẹjọ.
Wayi o, wọn ti wa sun igbẹjọ naa si ọjọ kọkandilọgbọn oṣu Keji, ati ọjọ kinni, oṣu Kẹta, ọdun 2024 yii.
Oluomo mórílé iléẹjọ́ láti tako ìyọnípò rẹ̀
Abẹnugan ile igbimọ aṣofin ti wọn ṣẹṣẹ yọ nipo nipinlẹ Ogun, Kunle Oluomo ti ni oun yoo lọ sile ẹjọ lati tako bi wọn ṣe yọ oun nipo.
Lọjọ Isẹgun ọsẹ yii ni ọmọ awọn aṣofin mẹrindinlogun ninu awọn mẹrindinlọgbọn ti igbakeji abẹnugan tẹlẹ ri ọhun Bolanle Ajayi, lẹyin lati gba ipo abẹnugan, ti wọn si yọ Oluomo gẹgẹ bi olori ile.
Nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ ni ile rẹ niluu Abeokuta, Oluomo ni oun ṣi ni olori ile igbimọ aṣofin nipinlẹ Ogun, to si ni oun ko gba pe wọn yọ oun nipo.
Gẹgẹ bi o ṣe sọ, o ni awọn ọmọ ile mẹrindinlogun to yọ oun nipo ko tẹle ilana ofin to rọ mọ yiyọ eeyan nipo.
Oluomo, ẹni to n ṣoju ẹkun ijọba ibilẹ Ifo 1 ni oun ti kan si Ile ẹjọ giga lati da si ọrọ naa, boya o ba ofin mu lati yọ oun nipo ni ilana ti wọn gba naa.
“Mo ti gbe ọrọ nipa yiyọ mi nipo bii olori ile lọ si ileẹjọ giga ipinlẹ Ogun lati bere boya awọn ọmọ ile igbimọ yii ni aṣẹ lati yọ mi nipo ni ilana ti ko ba ofin mu.
“Nnkan ti emi n sọ ni pe ṣe o waye ni ilana to ba ofin mu. Ko ki n ṣe pe ki ogun eeyan buwọlu iwe, ọrọ yii nipa ofin ni. Ti eeyan mẹtadinlọgbọn pẹlu emi ba buwọlu iwe , iyẹn ko ni ka ma tẹle ilana ti ofin gbe kalẹ.
“Ibuwọlu lai tẹle ofin ko ni itumọ. N ko tako iye eeyan to buwọlu iyọnipo yii sugbọn wọn gbọdọ tẹle ilana ti ofin gbe kalẹ.
BBC NEWS YORUBA gbọ pe lẹyin ti idajọ ti pari lori eto idibo gomina, ti awọn aṣofin si ti buwọlu eto iṣuna ọdun 2024, awọn aṣofin ọhun ri asiko to dara lati mu erongba wọn ṣẹ nipa yiyọ Oluọmọ.
Lara awọn ẹsun ti wọn fi kan Oluọmọ ni dida ọwọ ru, aini afojusun, igberaga, adari ti ko dara, aini otitọ, ṣiṣe owo kumọkumọ, ati kikọju awọn aṣofin sira wọn.