You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ìdí rèé tí Tinubu yóò fi lulẹ̀ nínú ìbò ààrẹ ọdún 2027 - Aregbesola
Gomina ipinlẹ Osun tẹlẹ, Rauf Aregbesola, ti sọ pe ko si ani-ani wi pe Aarẹ Bola Tinubu yoo lulẹ ninu ibo aarẹ ọdun 2027.
Aregbesola fidi ọrọ yii mulẹ nigba to n bawọn akọroyin sọrọ nibi ayẹyẹ ṣiṣi ọfiisi ẹgbẹ oṣelu ADC niluu Ilorin nipinlẹ Kwara lọjọ Abamẹta ọjọ kejidinlogun oṣu Kẹwaa yii.
Gomina ipinlẹ Osun tẹlẹ ni ẹgbẹ oṣelu ADC lo maa jawe olubori ninu ibo aarẹ orilẹede Naijiria lọdun 2027.
Aregbesola to jẹ akọwe ẹgbẹ oṣelu ADC sọ pe ''ti o ba da ẹgbẹ oṣelu APC loju wi pe loootọ ni wọn fẹsẹ mulẹ daadaa, wọn o ni maa dunkoko mawọn ẹgbẹ oṣelu alatako kaakiri.
Ni ṣe ni ẹgbẹ oṣelu APC n halẹ mawọn ọmọ ẹgbẹ wa nipinlẹ Eko, Kebbi, Kaduna ati kaakiri orilẹede Naijiria.
Awọn gan an gan an mọ pe awọn o fẹsẹ mulẹ to bawọn ṣe n pe ara awọn, bi bẹẹ kọọ, wọn o ba maa fara balẹ ṣe nnkan.
Amọ, ohun yowu ti wọn ba ṣe, ẹgbẹ ADC lo maa wọle ibo aarẹ ati ibo gomina lawọn ipinlẹ ninu eto idibo gbogbogbo ọdun 2027,'' Aregbesola lo sọ bẹẹ.
Lori ọrọ awọn gomina to n darapọ mọ ẹgbẹ APC, Aregbe ni ọta araalu lawọn gomina to n ṣe eleyii, ati wi pe awọn araalu naa mọ bẹẹ.
O ni awọn gomina yii ti mọ pe araalu ko fẹ awọn mọ tẹlẹ lo jẹ ki wọn maa huwa ti ko tẹ araalu lọrun.
Bakan naa ni gomina ipinlẹ Kwara tẹlẹ, Abdulfatai Ahmed, toun naa wa nibi ayẹyẹ ṣiṣi ọfiisi ẹgbẹ ADC niluu Ilorin sọ pe ADC ṣetan lati gba ipo adari orilẹede Naijiria lọdun 2027.
Ọgbẹni Ahmed ni omi tuntun ti ru ẹja tuntun ti wọ ọ lagbo oṣelu orilẹede Naijiria.
Gomina ipinlẹ Kwara tẹlẹ wa sọ pe ẹgbẹ oṣelu ADC ti wa ni igbaradi lati gba ipo iṣejọba orilẹede Naijiria lọdun 2027.