Wo nǹkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa abẹ́rẹ́ àjẹsára àìsàn ibà tí Cameroon fi lọ́lẹ̀

Orilẹede Cameroon ti se ifilọlẹ abẹrẹ ajẹsara ti yoo ma a dena aisan iba ninu agọ ara.

Abẹrẹ naa, ni akọkọ iru rẹ l'agbaye, o si wa fun idoola ẹmi awọn ọmọde ni ilẹ Afrika.

Ajọ eleto ilera lagbaye,WHO, buwọlu abẹrẹ ajẹsara RTS,S, eyi ti ileeṣẹ to n ṣe oogun GSK gbe kalẹ lati fi koju bi aisan iba se n ba awọn ọmọde finra ni awọn agbegbe kan.

Orilẹede Cameroon ni orilẹede akọkọ ti yoo pese abẹrẹ ajẹsara naa fun araalu lẹyin ipolongo aṣeyọri to ti waye ni Kenya, Ghana ati Malawi.

O to milọnu meji ọmọde ti wọn ti gba abẹrẹ ajẹsara yii ni Ghana, Kenya ati Malawi lasiko ipolongo abẹrẹ ajẹsara RTS,S.

Gbigba abẹrẹ ajẹsara naa yoo bẹrẹ ni Ọjọ Aje, ti awọn eleto ilera si sapejuwe igbesẹ yii gẹgẹ bi eyi ti yoo mu iginyanju lati mu adikun ba bi aisan se n ba awọn ọmọde finra rọnu nilẹ Adulawọ.

O to orilẹede ogun ti awọn naa lero lati bẹrẹ gbigba abẹrẹ RTS,S fun araalu wọn ki ọdun to pari .

GSK ni oun ni anfani lati pese abẹrẹ ajẹsara milọnu marundinlogun lọdọdun.

Awọn nnkan to yẹ ko mọ nipa abẹrẹ ajẹsara yii

Igbesẹ abẹrẹ ajẹsara jẹ igbesẹ iponlogo akọkọ fun araalu ni ilẹ Afrika.

Abẹrẹ ajẹsara ti wọn gbe de orilẹede Cameroon ni orukọ n jẹ RTS,S tabi Mosquirix to ti ọwọ ileeṣẹ GSK wa.

Ajọ eleto ilera agbaye ti buwọlu lilo abẹrẹ ajẹsara yii, to si wa fun lilo fun ọmọde bẹrẹ lati ọmọ oṣu marun un.

Bakan ni ipele ipolongo abẹrẹ ajẹsara yii waye ni orilẹede Ghana, Kenya ati Malawi.