Mo bẹ̀bẹ̀ gba iṣẹ́ yìí ni, N kò sì lè sọ pé kò tẹ́ mi lọ́rùn mọ́- Tinubu

Aarẹ Bọla Ahmẹd Tinubu ti ṣe ilẹri ọtun fun ẹgbẹ ọmọ Yoruba nni, Afẹnifẹri lati tun orileede Naijiria ṣe, ko si padabọ sipo to yẹ nipa aisi ojusaaju ni gbogbo ẹka.

O ni fifi ara jin lati lewaju Naijiria lọ sibi aṣeyọri eto ọrọ aje ati igbe aye to ṣee fi yangan lo jẹ oun logun kọja ohunkohun.

Tinubu lo ṣe ileri yii lasiko abẹwo to ṣe lọ sọdọ awọn olori ẹgbẹ naa ni ile Alagba Reuben Fasoranti to wa niluu Akurẹ, ipinlẹ Ondo l’Ọjọru, ọsẹ yii.

Nibẹ lo ti ṣeleri pe Naijiria yoo la asiko ipenija eto ọrọ aje yii koja, nitori pe lẹyin ohun gbogbo, ayọ ni yoo pada ja si.

“Naijiria yoo la ipenija eto ọrọ aje to wa ninu ẹ lasiko yii ja. Ina yoo tan lẹyin gbogbo rogbodiyan.

Mo bẹbẹ gba iṣẹ yii ni, mi o si le sọ pe ko tẹ mi lọrun.

Mo gba gbogbo ohun to n ṣẹlẹ yii mọra.

“Gbogbo ohun to yẹ ka ṣe ni a n ṣe lati tẹle ilana agbaye.

Si awọn ayanilowo wa, a ko tii ṣe kọja aaye, a ko si nii kọja aaye wa.

Gbogbo ọna ti a mọ la n tọ lati rii pe Naijiria de ibi aṣeyọri rẹ.

“Ipenija eto ọrọ aje ti a n la kọja latigba ti mo ti gba ijọba ko jẹ tuntun si mi.

Gẹgẹ bi gomina tẹlẹ nipinlẹ Eko, mo koju awọn iṣoro to jọ eyi, ti awọn eeyan si pe ipe lati kọwe fipo silẹ.

“Ṣugbọn nipasẹ ọkan akikanju ati igbesẹ to yẹ, ipinlẹ Eko gun oke agba si ipo karun ti eto ọrọ aje wọn n ṣe daadaa nilẹ Afrika.

“A ni lati rọra lo awọn ohun ti a ni pẹlu ọgbon ati imọ lati mu idagbasoke ba eto ọrọ aje wa.

“Mo gbe apoti, mo si ṣe ipolongo lati sin Naijiria nipa ifẹ Naijiria, wọn araalu si dibo fun mi.

Awọn kan sọ pe mi o le pe nile ẹjo Tribuna, wọn si bẹrẹ sii sọ oriṣiriṣi, koda nigba ti a wa nile ẹjọ, mo tun ṣi ni afojusun lati kọju si ibi ti mo n lọ.

“A ko le gba ki wọn jẹ eto ọrọ aje wa run.

A ko le pa eto ọrọ aje wa fun awọn ajẹnirun. Mo ti ipinnu lọkan ara mi lati ṣatunṣe eto iṣuna wa, ati lati fopin si iwa imọ-ti-ara-ẹni nikan.”

Akọwe agba ijọba orileede yii nigba kan ri, Alagba Olu Falae nigba to n gba ẹnu Alagba Fasoranti sọrọ, o gbe oriyin fun Aarẹ Tinubu lori akitiyan rẹ si itẹsiwaju Naijiria, bẹẹ lo ṣeleri lati ṣatilẹyin fun ijọba rẹ.

“O ti mu awọn ileri rẹ ṣẹ lati pada wa sibi, nibi ti a ti gbadura fun ẹ, eyi tumọ si wi pe ẹni ti kii yẹ adehun, to si maa n duro lori ọrọ rẹ ni ẹ.

“Loni, asia wa lo n gbe dani.

Wọn mọ wa fun iwa ọmọluabi, ẹni to kaju oṣuwọn, otitọ ati akikanju.

Awọn ipa ti o ti ko ti fi han daju o mọ pataki ori ohun ti a duro le lori, eyi ti yoo sọ fawọn ọmọ Naijiria pe ijọba to dara ṣee ṣe.”

Àbájáde ìpàdé Ààrẹ Tinubu àti àwọn olórí ẹgbẹ́ Afenifere rèé nípa ìnira tí aráàlú ń kojú

Ààrẹ Bola Tinubu ti ṣe àbẹwò sì adari ẹgbẹ Afenifere, Pa Reuben Fasoranti fún igbà akọkọ lẹyìn ti o di ààrẹ orilẹede Naijiria

Àbẹwò ọhun waye ni ilu Akure ni ọjọ kejidinlogbon oṣù keji ni ilé adari ẹgbẹ naa.

Ipade naa to wayẹ ni atilekun mori pelu adari Afenifere ati awọn agba-gba ẹgbẹ naa bi Bashorun Sehinde Arogbofa, Akọwe ìjọba àpapọ̀ tẹlẹ Oba Olú Falae

Lẹyìn wákàtí kan ti ipade naa bẹrẹ, ààrẹ Tinubu gbera kuro ni ilé adari ẹgbẹ Afenifere.

Kini Tinubu ati awọn agbaagba ilẹ Yoruba sọ

Agbẹnusọ fún ẹgbẹ Afenifere Ogbeni Jare Àjàyí sọ pẹ awọn ẹgbẹ Afenifere ba ààrẹ Tinubu sọrọ lórí atunto orileede Naijiria ni ẹka òṣèlú, ọrọ ajé, ìbarà eni gbepọ ati awọn ẹka miran.

Laara awọn nnkan ti ẹgbẹ Afenifere bẹrẹ fún nipa atunto orileede Naijiria ni ki awọn agbegbe lẹtọ sì ànfàní lori awọn ọun alumọni ti ìjọba ba ri l'agbegbe wọn

" Gẹgẹ bi o ṣe wa bayi, awọn agbegbe ti orileede Naijiria tin ri epo rọbi lo ni ànfàní sì awọn owo kan sùgbọ́n eleyi ko gbọdọ̀ wa fún epo rọbi nikan, awọn àgbègbè ti ohun alumọni ilẹ̀ wa naa lẹtọ lati maa gba awọn owo kan naa lowo ìjọba gege bi ẹtọ."

Ogbeni Jare Àjàyí tun sọ pe ààrẹ Tinubu fi daa Pa Fasoranti ati awọn agba Afenifere loju pe ìnira ti awọn ọmọ Nàìjíríà n koju lọwọ yóò di ohun afiseyin teegun n fiṣo.

O ni "Ààrẹ sọ fun wa pe : ṣe ni mo gbàdúrà lati di ààrẹ orilẹede Naijiria . Mo kọrin, mo si jo si. Gbogbo idojukọ yi ni mo ti gbaradi fún. Gẹgẹ bi mo ṣe ṣe ni ilu Eko ti o fi di ipinlẹ ti ọrọ ajé rẹ ni idagbasoke julọ ni ilẹ Africa mo fé fi ipinlẹ to muna doko silẹ fún atunto"

Àjàyí sọ pẹ ààrẹ Tinubu gbe iwe moyege ti INEC fún wa hàn adari ẹgbẹ Afenifere.

Gomina ipinlẹ Ondo Lucky Aiyedatiwa ati Gomina ana dokita Olusegun Mimiko wa lara awọn to peju sibi ìpàdé naa.

Bola Tinubu yóò balẹ̀ sí ìpínlẹ̀ Ondo lónìí fún àbẹ̀wò

Aarẹ Naijiria, Bola Ahmed Tinubu yoo ṣabẹwo si ipinlẹ Ondo lonii, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Keji, ọdun 2024.

A gbọ pe eredi abẹwo naa ko ṣẹyin ibanikẹdun si mọlẹbi goomina ana ni ipinlẹ ọhun to di oloogbe, Arakunrin Oluwarotimi Akeredolu.

Iroyin ni gomina Lucky Aiyedatiwa ni yoo gbalejo Tinubu ni papakọ ofurufu to wa niluu Akure.

Lasiko abẹwo naa ni Tinubu yoo tun ṣabẹwo si aṣaaju ẹgbẹ ọmọ Yoruba, Pa Reuben Fasoranti, nile rẹ to wa niluu AKure.

Ti ẹ ko ba gbagbe, ilu Owo, nibi ti wọn ti bi Akeredolu ni awọn mọlẹbi rẹ wa bayii lẹyin to wọ kaa ilẹ sun.

Akeredolu jade laye lọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kejila, ọdun 2023 lẹyin arun jẹjẹrẹ to kọluu ṣaaju.

Wọn si ti sin oku rẹ niluu Owo lọjọ Ẹti to kọja, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Keji, ọdun 2023.

Fọfọ ni ile ijọsin ti eto isinku naa ti waye ladugbo Imola, niluu Owo kun.

Ọpọ ọmọ ilu Owo, oloṣelu, ẹbi ati ọrẹ oloogbe naa lo peju sibi eto isinku ọhun.

Lara awọn aṣaaju ilu to wa nibẹ ni igbakeji Aarẹ Naijiria, Kashim Shettima, gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde, gomina ipinlẹ Ọsun, Ademola Adeleke, gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu ati gomina ipinlẹ Ogun, Dapo Abiodun.

Awọn mii to tun wa nibẹ ni gomina ipinlẹ Ondo tẹlẹ, Olusegun Mimiko, gomina ipinlẹ Ọsun ana, Gboyega Oyetola, atawọn eeyan jankan ilu mii.