Akọ́nimọ̀ọ́gbà tẹ́lẹ̀ fún ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Nàìjíríà, Broderick-Imasuen jáde láyé

Sebastine Broderick-Imasuen

Oríṣun àwòrán, Others

Akọnímọ̀ọ́gbá Sebastine Broderick-Imasuen tó ṣaájú ikọ̀ Golden Eaglet lọ sí ìdíje ife ẹ̀yẹ àgbáyé lọ́dún 1985 ti jáde láyé.

Ohun ní ó ṣáájú ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Nàìjíríà tí wọ́n fi gba ife ẹ̀yẹ àgbàyé lọ́dún 1985, èyí tó jẹ́ ìgbà àkọ́kọ́ tí ilẹ̀ Adúláwọ̀ yóò gba ife ẹ̀yẹ náà.

Ṣáájú ni Broderick-Imasuen ti wà ní ilé ìwòsàn olùkọ́ni ti ilé ẹ̀kọ́ gíga University of Benin ní ìpínlẹ̀ Edo fún ọdún níbi tó ti ń gba ìtọ́jú.

Ní oṣù Kejìlá ọdún 2022 ni Broderick-Imasuen, ẹni ọdún 85 ti bẹ̀rẹ̀ sí ní ba àìsàn rọpárọsẹ̀ fínra, tọ sì ń gba ìtọ́jú ní ilé ìwòsàn náà kí ó tó mí èémí ìkẹyìn.

Ọ̀kan lára àwọn agbabọ́ọ̀lù tí Broderick-Imasuen kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ níbi ìdíje ife ẹ̀yẹ àgbáyé ọdún 1989 ní Scotland, Bamidele Oguntuashe ló kọ́kọ́ fi ìròyìn ikú akọ́nimọ̀ọ́gbá náà léde.

Alága ẹgbẹ́ àwọn agbábọ́ọ̀lù Nàìjíríà, Harrison Jalla náà fìdsí ikú Broderick-Imasuen múlẹ̀ lórí ẹ̀rọ WhatsApp.

Jalla ní àwọn ẹbí Broderick-Imasuen ló sọ fún òun pé akọ́nimọ̀ọ́gbá náà ti jáde láyé lẹ́yìn tó ti wà ní ẹsẹ̀ kan ayé ẹsẹ̀ kan ọ̀run ní ilé ìwòsàn láti bí osù málòó kan sẹ́yìn.

Ó ní àìsàn ìtọ̀ ṣúgà àti rọpárọsẹ̀ ló pa Broderick-Imasuen.

Olóògbè Sebastine Broderick-Imasuen wà lára àwọn agbábọ́ọ̀lù tó ṣojú Nàìjíríà níbi ìdíje Òlímpìkì tó wáyé ní Mexico lọ́dún 1968.

Bákan náà ló gbajúmọ̀ fún jíjẹ góòlù gan níbi ìdíje Challenge Cup níbi Bendel Insurance lọ́dún 1972.

Gẹ́gẹ́ bí akọ́nimọ̀ọ́gbá, Broderick-Imasuen ṣaájú àwọn akọ́nimọ̀ọ́gbá míì bíi Bala Shamaki àti Christian Chukwu láti gba ife ẹ̀yẹ ní China lọ́dún 1985.

Lẹ́yìn náà ló tún ṣaájú ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù lọ sí Canada lọ́dún 1987 tí wọ́n sì dé ipele tó kẹ́yìn níbi ìdíje náà ṣùgbọ́n tí wọ́n pàdánù sọ́wọ́ Soviet-Union.

Ní ọdún 1956 ni Broderick-Imasuen bẹ̀rẹ̀ gbígba bọ́ọ̀lù nígbà tó wà gẹ́gẹ́ bí akẹ́kọ̀ọ́.