You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Wo ewu tó wà nínú fífipá fún ọmọdé lóúnjẹ, pẹ̀lú bí o ṣe lè pa ọmọ
Ẹni ti oju rẹ ko ri ọran ri ni wọn lo n fi ọmọ orogún rẹ lọkọ. Oun nikan kọ ṣaa, ẹni to n fipa fun ọmọ lounjẹ nipa rirọ ọmọ naa n wa wahala pẹlu, nitori iwa naa le fa iku ọmọ.
Adura gbogbo abiyamọ ni pe ki wọn ri ọmọ wo dagba, kawọn ọmọ oun si ṣe rere niṣoju wọn.
Ṣugbọn iṣẹ ti awọn obi mi-in n ṣe ko fun wọn lasiko lati duro tọju ọmọ nile.
Eyi lo fa a ti wọn fi n gbe ọmọ lọ sile awọn alágbàwò (Nanny) tabi awọn ileewe ti wọn yoo ti maa ba wọn wo o titi ti wọn aa fi tibi iṣẹ de.
Lọdọ awọn alagbawo ta a mọ si ‘nani’ yii, awọn mi-in a maa fi ounjẹ rọ ọmọ pẹlu tulaasi.
Aisan ti ọmọde mi-in ko ni ko too kuro lọwọ iya rẹ ni yoo gbe de lati ile alagbawo ti wọn gbe e lọ.
Ọmọ-ọdọ ni iya mi-in gba lati maa ba a mojuto ọmọ nitori iṣẹ, àrà to ba si wu ọmọ ọdọ ni yoo fi ọmọ naa da nigba to ba fẹẹ fun un lounjẹ.
Bẹẹ lawọn iya kan wa ti wọn ko ṣiṣẹ to gba asiko, ṣugbọn nitori aijẹun ọmọ wọn, wọn aa maa fi ounjẹ rọ ọmọ.
Eyi to le mu ki ounjẹ gba ibo-mi-in ki ọmọ naa si ku.
Naní rí ẹ̀wọ̀n ọdún márùn-ún he nítorí ikú ọmọ tó fipá fún lóúnjẹ
Ẹni ọdun mẹrindinlọgọta (56) ni Clara Yanyi-Ampah nigba to gbadajọ ẹwọn ọdun marun-un ni 2021.
Ko sohun to jẹ ki iya naa fi agbalagba ara ṣẹwọn ju pe o fipa fun ọmọ oṣu mọkanla lounjẹ, ọmọ naa si ku latari eyi.
Ileewe Happy blommers to wa ni Accra, ni Ghana, ni Clara ti n ba wọn ṣiṣẹ alagbatọ.
Kamẹra lo ṣafihan ibi to ti di ọwọ ọmọ naa mu sẹyin to si n fun un lounjẹ lati inu ife imumi.
Bi Clara ṣe n fipa rọ ọmọ naa lounjẹ lọmọ yii n ke, o si n tiraka lati bọ lọwọ ai-le-mi daadaa to n koju ati ounjẹ to n fi agidi wọ ẹnu rẹ lọ.
Lojiji ni ọmọ naa ko mira mọ, ko ke mọ bẹẹ ni ko gba ounjẹ ti alagbatọ rẹ n fun un .
Bẹẹ lọmọ naa si ṣe ku mọ ọ lọwọ.
Awọn alaṣẹ ileewe naa sọ pe ofin wa nileewe awọn, wọn ni ṣibi lo yẹ ki Clara fi fun ọmọ lounjẹ, ki i ṣe kọọbu ti ko ni i ṣe ṣe odiwọn.
Ko si gbọdọ jẹ pẹlu ipa pẹlu.
Wọn fi kun un pe awọn kọ lawọn tilẹ ni kọọbu to fi fun ọmọ lounjẹ, wọn ni Clara lo mọ ibi to ti ri i.
Àyẹ̀wò fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pẹ fífipá fún ọmọ náà lóúnjẹ ló pa á
Lẹyin iku ọmọ oṣu mọkanla yii ni ayẹwo waye, dokita si fidi ẹ mulẹ pe ai-le-mi daadaa latari ounjẹ to n wọle si i lara lo pa a.
Ayẹwo oku yii sọ pe ọpọlọpọ ounjẹ ni wọn ba ninu ẹdọforo ọmọ oṣu mọkanla ọhun.
O ni awọn ounjẹ ti nani fipa fun un lo di ọna to n gba mi to fi ja si iku.
Bo tilẹ jẹ pe nani loun ko jẹbi, sibẹ, ile-ẹjọ da a lẹbi iṣeṣi-paniyan, o si gbadajọ ẹwọn ọdun marun-un pẹlu iṣẹ aṣekara.
Ewu ń bẹ nípa fífi ipá fún ọmọ lóúnjẹ- Dokita Grant
Dokita kan, Jenny Grant, ṣalaye ohun to maa n ṣẹlẹ lagọ ara ọmọde nigba ti a ba n fipa fun wọn lounjẹ.
O ni ounjẹ ati atẹgun ni ọna ti wọn n gba titi ti wọn yoo fi de opin ọna ọfun.
“ Lẹyin ọfun, ohun ti a mọ si ‘trachea lo n gbe atẹgun, nigba ti eyi ti a n pe ni ‘’oesophagus’’ n gbe ounjẹ.
‘’Bi eeyan ṣe n gbe ounjẹ mì, o yẹ ki atẹgun kan maa ba a lọ.
‘’Eeyan o le gbe ounjẹ mí ko si tun maa mí lasiko kan naa. Ọmọde naa yoo ni lati se eemi rẹ bo ṣe n gbe ounjẹ mi ni.
“ Nigba ti ọmọ kekere ko si le se eemi, awọn ounjẹ to fipa wọle yoo gba inu ẹdọforo rẹ lọ ni.
‘’Bi eyi ba ṣẹlẹ, ti ọmọ ko le hukọ ki awọn ounjẹ naa jade sita, iku ni.
Kí lohun tí o lè ṣe tí ọmọ rẹ yòò fi maa gba oúnjẹ láì lo ipá
Maa gbe ounjẹ fun un pẹlu awọn nnkan ijẹun alawọ to rẹwa, to fa ni mọra.
Awọn ọmọde fẹran aworan to rẹwa, o si le mu ọkan wọn fa mọ ọ ounjẹ inu rẹ.
Bi ọmọ ba n hukọ leralera lasiko ti o n fun un lounjẹ, dawọ ounjẹ naa duro ki o si beere itọju lati ọdọ dokita.
Bi eemi ọmọ ba n sare ju, to pọju bo ṣe yẹ lọ, aya le maa dun un. Tete gbe e lọ sileewosan.
Lakootan, bi ọmọ rẹ ko ba jẹun daadaa, tọ dokita awọn ọmọde lọ.
Ma ṣe gbe igbesẹ to le fa iku ọmọ tabi da wahala si gbogbo mọlẹbi lọrun.