Ẹ̀rọ tó lè máa fẹnu kò ọ́ lẹ́nu tí olólùfẹ́ rẹ bá jìnà réré sí ọ rèé

Onimọ ẹrọ kan ni China ti ṣagbekale ẹrọ to le maa fẹnuko eeyan lénu ti ololufẹ irufẹ ẹni bẹẹ ba jina rere si ibi to wa.

Ẹrọ ọhun ni wọn pero rẹ lasiko ti ajakalẹ arun Corona mi gbogbo agbaye titi, eyiti ko si faye gba awọn eeyan lati ri ara wọn nitori ofin igbele.

Eroja ‘silicon’ ni wọn fi ṣe ẹrọ naa, eyii ti yoo fẹnu ko eeyan lẹnu, ti yoo si fi ranṣẹ si ololufẹ irufẹ ẹni bẹẹ ninu aapu.

Ọgbẹni Zhao Jianbo, to da ẹrọ ọhun naa silẹ sọ pe yoo tubọ jẹ ki awọn ololufẹ le fi ọkan tan ara wọn.

O ni “ Ẹrọ naa dara pupọ, yoo fun awọn ololufẹ lanfani lati fi ọkan tan ara wọn.”

“Niṣe lo da bi ẹrọ WeChat tabi ẹrọ ibaraẹnisọrọ ti kii jẹ ki awọn eeyan jina sira wọn.”

Ẹgbẹrun mẹta eeyan lo ti ra ẹrọ naa laarin ọsẹ meji ti wọn ṣefilọlẹ rẹ ninu oṣu Kini.

Wo fidio oke yii fun ẹkunrẹrẹ.