Iléẹ̀kọ́ ṣí padà ní ìpínlẹ̀ Eko ní Ọjọ́ Aje

Ijọba ipinlẹ Eko ti paṣẹ ki gbogbo ileẹkọ ṣi pada ni Ọjọ Aje, Ọjọ Karun un, Oṣu Kẹsan an, ọdun 2022 fun saa ọdun 2022 si 2023.

Ninu atẹjade ti ajọ to n risi eto ẹkọ to munadoko nipinlẹ Eko, Abiola Seriki-Ayeni lo fi ọrọ naa lede.

O ni aṣẹ naa ti gba ontẹ ni ọwọ kọmiṣọnna fun eto ẹkọ nipinlẹ Eko, Folaṣade Adefisayo.

‘’Gbogbo ileẹkọ yatọ si fasiti ni ki wọn wọle pada ni ipinlẹ Eko fun saa kini ni Ọjọ Aje, Oṣu Kẹsan an, ọdun 2022.’’

‘’A ki awọn akẹkọọ ati olukọ pada si ileẹkọ wọn to fi mọ awọn ti yoo pada si ileẹkọ ti wọn n gbe ninu ibẹ’’

Bakan naa ni kọmiṣọnna eto ẹkọ naa ni awọn paṣẹ ki wọn wọle pada naa ki eto ẹkọ saa naa ba le lọ ni irọwọ-rọṣẹ, ki ipinlẹ Eko si jẹ awokọṣe laarin awọn ipinlẹ.

Kọmiṣọnna naa rọ awọn akẹkọọ ati olukọ lati mu eto aabo wọn ni ọkunkundun, ki wọn si tẹle gbogbo aṣẹ to rọmọ eto ilera.