Àwọn àkẹ́kọ̀ọ́ ilé-ẹ̀kọ́ girama mẹ́fà tí wọ́n lọ́wọ́ nínú ikú olùkọ́ wọn rí ẹ̀wọ̀n he

Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ mẹ́fà tí wọ́n lọ́wọ́ nínú ikú olùkọ́ wọn kan ní orílẹ̀ èdè France ti rí ẹ̀wọ̀n he.

Ní ọdún 2020 ní ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé ní orílẹ̀ èdè France níbi tí àwọn kan ti gé orí olùkọ́, Samuel Paty fẹ́sùn wí pé ó fi àwòrán ẹ̀fẹ̀ Ànọ́bì hàn ní yàrá ìkẹ́kọ̀ọ́.

Ní ìwájú ilé ẹ̀kọ́ tó ti ń ṣiṣẹ́ olùkọ́ ni wọ́n pa Paty sí.

Ilé ẹjọ́ ní ọ̀kan lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà jẹ̀bi pé ó parọ́ nǹkan tó ṣẹlẹ̀ ní kíláàsì gan-an, tí wọ́n sì ní àwọn yòókù jẹ̀bi ẹ̀sùn pé wọ́n tọ́ka Paty sí ẹni tó pa á.

Ẹ̀wọ̀n oṣù mẹ́rìnlá sí ọdún méjì ni ilé ẹjọ́ dá àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà.

Ọ̀kan lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà tó jẹ́ obìnrin ni wọ́n ní ó sọ fún àwọn òbí rẹ̀ pé Paty lé gbogbo àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó jẹ́ mùsùlùmí kúrò ní yàrá ìkẹ́kọ̀ọ́ kó tó fi àwòrán náà hàn.

Àmọ́ ìwádìí ní ọmọbìnrin náà kò sí ní kíláàsì lọ́jọ́ tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé tí ilé ẹjọ́ sì ní ó jẹ̀bi irọ́ pípa àti pé ó sọ àwọn nǹkan tó da omi àláfíà rú.

Àwọm márùn-ún yòókù, tí ọjọ́ orí wọn wà láàárín ọdún mẹ́rìnlá sí mẹ́ẹ̀dógún lásìkò tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé, ni ilé ẹjọ́ ní wọ́n jẹ̀bi pé wọ́n fi olùkọ́ náà sínú ewu.

Ẹni tó ṣekúpa olùkọ́ náà, Abdoullakh Anzorov, ọmọ ọdún méjìdínlógún ni àwọn ọlọ́pàá yìbọn pa lásìkò ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

Akẹ́kọ̀ọ́ ilé-ẹ̀kọ́ girama mẹ́fà f’ojú ba ilé-ẹjọ́ fẹ́sùn ṣíṣekúpa olùkọ́ wọn

Ṣaaju ni awọn ọdọ akẹkọọ naa ti n foju ba ile-ẹjọ nilu Paris lorilẹ-ede Faranse lọjọ Aje fun ipa ti wọn ko ninu iku to pa olukọ wọn, Samuel Paty, ti wọn si gee lori ni ọdun 2020.

Awọn afurasi ọun, ti awọn kan ninu wọn de igo dudu soju, tawọn toku si wọ iboju, ni wọn da aṣọ bori lati le gbe oju wọn pamọ bi wọn ṣe n wọle sile-ẹjọ awọn ọmọde ti igbẹjọ naa ti waye.

Igbẹjọ ọhun ni wọn n ṣe ni bonkẹlẹ nitori ọjọ ori awọn ọmọ naa ti ko ju ọdun mẹtala si marundinlogun lọ lakoko ti iṣẹlẹ naa waye.

Awọn ti ọrọ naa kan gbangban nikan ni wọn gba laaye lati wọ ile-ẹjọ, bẹẹ ni won gba kawọn akọroyin o wọle ni bi awọn ọlọpaa ṣe ro wamuwamu niwaju ile-ẹjọ naa.

Awọn mọlẹbi Paty wa lara awọn to wọle sile ẹjọ, ti awọn akẹgbẹ rẹ bii mẹwa si wi pe awọn yoo yọju sibẹ.

Paty, ọmọ ọdun mẹtadinlaadọta, to n ṣe olukọ nipa itan ati ẹkọ agbegbe ni wọn gun pa ti wọn si gee lori lẹba ile-ẹkọ girama to ti n ṣiṣẹ ni Conflans-Sainte-Honorine, nilu Paris.

Ẹni ọdun mejidinlogun to ṣe akọlu ọun, to jẹ ogunlende lati Chechen lorilẹ-ede Russia, Abdoullakh Anzorov, ni awọn ọlọpaa pa sibi ti iṣẹlẹ naa ti waye.

Ẹṣẹ wo gan ni Paty ṣẹ?

Abdoullakh, ti wọn juwe bii alakatakiti ẹsin Islam, lo ṣekupa Paty lọjọ kẹrindinlogun oṣu kẹwa, ọdun 2020 lẹyin ti iroyin tan kiri lori ẹrọ ayelujara pe olukọ naa fi aworan ẹfẹ anọbi Mohammed ti Charlie Hebdo gbe jade han awọn ọmọ kilaasi rẹ.

Wọn ni Paty lo aworan ọhun ninu idanilẹkọ rẹ lati ṣe apejuwe igbalaaye lati sọ ohun to ba wuni nilẹ Faranse ati pe ofin ko de sisọ ọrọ odi nipa ẹsin, bẹẹ si ni o pẹ ti awọn eeyan ti n fi adari ẹsin ṣe yẹyẹ nibẹ.

Iṣekupa Paty lo waye lọsẹ diẹ si akoko ti Charlie Hebdo gbe aworan ọhun jade lẹẹkeji, bo tilẹ jẹ pe awọn mejila ni awọn agbebọn pa ni ọfiisi ileeṣẹ iroyin lọdun 2015 ti wọn kọkọ gbee jade.

Oṣu to kọja ni alakatakiti ẹlẹsin musulumi kan tun pa olukọ miran, Dominique Bernard, ni apa ariwa ilẹ naa.

Ẹni ti wọn furasi pe o ṣekupa Bernard, Mohammed Moguchkov, lo tun wa lati apa ariwa Russia tawọn musulumi pọ si bii Anzorov.

Ipa wo ni awọn akẹkọọ to n jẹjọ yii ko?

Marun-un ninu awọn akẹkọọ naa to jẹ ọmọ ọdun mẹrinla si marundinlogun lakoko iṣẹlẹ naa ni wọn jẹjọ ilẹdiapopọ lati huwa ika ati ninii lọkan lati ṣe laabi.

Wọn fẹsun kan wọn pe awọn ni wọn n wo ọna fun Anzorov, ti wọn si tun tọka Paty fun-un nitori owo.

Ẹnikẹfa ninu wọn to jẹ ọmọ ọdun mẹtala nigba naa ni wọn fẹsun kan pe o parọ mọ oloogbe naa pe o le awọn ọmọ musulumi jade ni kilaasi rẹ ko too fi aworan naa han awọn akẹkọọ to ku.

Louis Cailliez, to jẹ agbẹjọro fun mọlẹbi Paty wi pe oun n reti kawọn agbẹjọro awọn olujẹjọ o waa wi pe ọmọde lo ṣe awọn afẹsunkan naa.

O wi pe igbẹjọ naa ni lati mọ “ohun gan to mu ki awọn akẹkọọ naa o ṣe iṣẹ aburu ọhun”.

Ẹwẹ, agbẹjọro ọkan lara awọn afẹsunkan naa, Antoine Ory, lo wi pe onibara oun ti kabamọ ohun ti o ṣe.

O ni “ẹru n baa, o si n kọminu bi yoo ṣe ri ti oun ba foju kan awọn mọlẹbi Paty”.

Awọn akẹkọọ ọun, lakoko ifọrọwanilẹnuwo wi pe ero ọkan awọn ni pe wọn yoo sọ Paty di ẹni yẹyẹ lori ẹrọ aayelujara abi ki wọn dunkoko mọọ, amọ awọn ko mọ pe yoo di ti iṣekupani.

Awọn akẹgbẹ Paty to wa nibi igbẹjọ naa lo wi pe awọn wa lati waa mọ idi ti iṣẹlẹ naa ṣe waye ati pe awọn ko ri bakan naa mọ lati igba ti Paty ti lọ.

Awọn akẹkọọ naa lee lo to ọdun meji abọ lọgba ẹwọn ti wón ba jẹbi ẹsun ti wọn fi kan wọn.

Agbalagba mẹjọ ti ẹsun naa tun kan ni igbẹjọ ti wọn yoo bẹrẹ ni ọdun 2024.