You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ẹ máa retí ẹ̀kún omi ní ìpínlẹ̀ mẹ́sàn án ní Naijiria láìpẹ́ – NEMA
Ajọ to n risi iṣẹlẹ pajawiri ni Naijiria, NEMA, ti kilọ fun awọn ọmọ Naijiria lati maa reti ẹkun omi ni ipinlẹ mẹsan an ọtọtọ.
Ikilọ yii ko ṣẹyin bi orilẹ-ede Cameroon ṣe n mura lati ṣi omi adagun omi ‘Lagdo Dam.’
Awon ipinlẹ ti ọrọ naa kan ni Adamawa, Taraba, Benue, Nasarawa, Kogi, Anambra, Edo, Delta ati Bayelsa.
Adari agba NEMA, Mustaph Ahmed lo sọrọ naa lasiko to n ba awọn akọroyin ṣọrọ niluu Abuja.
O ni awọn ipinlẹ mẹsan an ti ọrọ naa kan, ti wọn sunmọ eti odo ‘River Benue’ le maa ba iṣẹlẹ omiyale finra titi di opin oṣu Kẹwaa.
Ahmed sọ pe igbesẹ orilẹ-ede Cameroon naa le ba awọn ohun ọgbin atawọn ohun amayederun miiran jẹ.
O ni “Lati nnkan bii ọjọ meji sẹyin ni NEMA ti n ṣe itaniji lori ohun to le ṣẹlẹ si awọn to n gbe lagbegbe ti omi wa atawọn ilẹ to sunmọ odo Niger nipinlẹ Adamawa, Taraba ati Benue.
“Siwaju sii, awọn ohun ọgbin, ilẹ ati awọn ohun amayederun to niyelori wa ninu ewu latari pe wọn le ba omi lọ.
“O tun ṣeeṣe ki iṣẹlẹ omiyale waye ni awọn ipinlẹ mii mii bii Taraba, Benue, Nasarawa, Kogi, Anambra, Edo, Delta ati Bayelsa bi odo Benue ba darapọ mọ odo Niger, tp fi mọ alagbalugbu omi Atlantic.”
O fi kun pe, titi di asiko yii, awọn eniyan 159,157 ni ẹkun omi ti ṣe akoba fun ninu ọdun yii.
Gẹgẹ bii ohun to sọ, eeyan 28 lo ti padanu ẹmi wọn nigba ti eeyan bi 48,168 ti di alarile gbe ni awọn ipinlẹ bii mẹtala ni Niajiria.
O pari ọrọ rẹ pe NEMA yoo tẹsiwaju lati maa ṣe itaniji fun araalu siwaju sii.