Adebutu fojú ba Ilé ẹjọ́ lórí ẹ̀sùn ríra ìbò àti àwọn ẹ̀sùn míì

Oludije fun ipo Gomina ipinlẹ Ogun labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP), Ladi Adebutu ti farahan niwaju Ile ẹjọ giga kan nipinlẹ Ogun lori ẹsun rira ibo ti wọn fi kan an lasiko eto idibo Gomina to waye ọdun 2023.

Ẹsun meje lo wa lọrun Adebutu, rira ibo ati awọn ẹsun mii pẹlu nọmba idanimọ AB/10c/2023 (FRN Vs Adebutu &Ors niwaju onidajọ Abiodun Akinremi.

Adebutu sọ fun ileẹjọ pe oun ko jẹbi eyikeyi ẹsun ti wọn fi kan oun.

Ẹsun ti wọn kan Adebutu ni pe o pasẹ fun ileeṣẹ ifowopamọ rẹ fi ẹgbẹrun mẹwaa ni apo owo kan, ti wọn si n pin kaadi to n pe owo jade, eyi ti wọn ni owo wa ni inu rẹ kaakiri lasiko eto idibo nipinlẹ Ogun.

Oun pẹlu awọn afurasi mẹfa ni Ileeṣẹ ọlọpaa wọ lọ si ile ẹjọ.

Agbẹjọro fun Adebutu, Goody Uche sọ fun ileẹjọ lati fun onibara rẹ ni anfani lati gba beeli nitori pe ọjọ isẹgun ni wọn fi iwe pe Adebutu, to si tun farahan ni ile ẹjọ.

Agbẹjọro fun ijọba apapọ, Rotimi Jacobs ko tako ipe naa.

Adajọ Akinyemi wa gba ipe Uche, to si fun Adebutu niu beeli pẹlu milọnu kan naira pẹlu oniduro kan

O wa sun igbejọ naa siwaju si Ọjọru, ọjọ kẹfa oṣu keji.

Nigba to n ba awọn akọroyin, Jacobs sọ pe oni Ọjọ Isẹgun ni wọn fi iwe pe Adebutu, to si wa fi ohun rẹ silẹ.

Uche salaye “Ọrọ yii ti wa ni ita tipẹ pe onibara mi salọ,

“Inu mi dun lonii pe o yọju fun ara rẹ. Koda o fa ara rẹ silẹ fun ile ẹjọ.

“O ti wi tẹnu rẹ, o ni oun ko jẹbi ẹsun meje ti wọn fi kan. Inu wa dun pe a wa ni ibi bayii lonii, ti a si ti gbaradi fun igbẹjọ yii.