Olóòtú ìjọba, Keir Starmer kéde àtìlẹ́yìn UK fún Palestine láti dá dúró

Oríṣun àwòrán, Alberto Pezzali - WPA Pool/Getty Images
Olootu ijọba ilẹ Gẹẹsi, Sir Keir Starmer ti kede pe ilẹ Gẹẹsi ti gba ilẹ Palestine gẹgẹ bii orilẹede to da duro gedegbe
Olotu ijọba, Starmer kede eyi ninu atẹjade kan to fi sita lọjọ Aiku.
Starmer sọ ninu oṣu keje pe UK yoo kẹyin si Israel ayafi ti orilẹede Israel ba ṣe ohun to yẹ, paaapa dida ọwọ ogun duro ni agbegbe Gaza Strip, ti wọn si fọwọ si adehun alaafia ọlọjọ pipẹ ti yoo jasi ajọsepọ nla laaarin orilẹede mejeeji.
Awọn olori ijọba Israel ti wọgile eyi lati igba ti ikọ Hamas ti kọlu wọn ni ọjọ keje, oṣu kẹwaa ọdun 2023, nibi ti eeyan to le ni ẹgbẹrun kan ti padanu ẹmi wọn, ti wọn si tun ji ọpọ eeyan gbe lọ.
Igbesẹ olootu Ijọba UK ni ko dun mọ inu ijọba Israel ninu ati awọn mọlẹbi awọn eeyan ti ikọ Hamas jigbe lasiko ikọlu ni Gaza.
Olootu ijọba Israel, Benjamin Netanyahu sọ ṣaaju pe idanimọ Palestine gẹgẹ bii ilu to da duro tumọ si pe ki fun iwa ibajẹ ni ẹbun.
Igbesẹ olootu ijọba UK ni igbagbọ wa pe o da lori fifi aye silẹ fun alaafa lati ijọba laaarin orilẹede mejeeji.
Akitiyan lati ri pe ogun Israel-Palestine wa sopin ni eyi jẹ. Orilẹede Israel n koju ọpọ eebu lati ọwọ orilẹede agbaye lẹyin ikọlu to kọlu ikọ Hamas ni orilẹede Qatar lasiko jiroro.
Ikọlu ti Israel ṣe si Gaza laipẹ tun le ọpọ eeyan kuro ni agbegbe ti wọn wa.
Igbakeji olootu ijọba, David Lammy ni "Asiko yii ni a ni lati dide fun ọna abayọ laaarin orilẹede mejeeji."
Lammy ni awọn mọmọ gbe idanimọ yii si asiko yii nitori ohun to sẹlẹ lọwọ.
Ni ibẹrẹ oṣu yii ni ikọ ologun Isreali gbe ikilọ tuntun kalẹ fun wọn lati kuro niluu naa kia.
Oju opo X ni agbẹnusọ IDF lẹka ede Larubawa, Avichay Adraee, ti kilọ pe:
"Si gbogbo olugbe ati gbogbo eeyan to ba ṣi wa ni Gaza ati agbegbe rẹ, fun aabo yin, ẹ kuro nibẹ lẹsẹkẹsẹ."
Atẹjade naa fi kun un pe, "o lewu gidi bi ẹ ba ṣi n duro lagbegbe naa".











