You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
O fẹ́ Jápa lọ́dún 2023? Wo àwọn nǹkan tó yẹ kó o mọ̀?
Ọpọlọpọ awọn ọdọ lorilẹede Naijiria ni wọn gba ladura pe ki awọn kuro lọ si oke okun fun idi kan tabi miiran.
Bí awọn kan ṣe n Japa lati lọ kawe, ní awọn kan lọ sisẹ, koda awọn miiran kuro ni agbegbe Naijiria patapata.
Ṣugbọn o ṣe koko ki awọn eeyan wọnyi ṣe iwadi lori ibi ti wọn lọ ati pato ohun tí wọn fẹ lọ ṣe nibẹ.
Ileeṣẹ BBC News Yoruba ṣe akojọpọ awọn ohun pataki ti yoo wulo fun ẹnikẹni to be fẹ JAPA lọdun 2023.
Mọ nnkan to fẹ ṣe
Ki eeyan mọ ohun to fẹ ṣe ko to rile oke okun ṣe pataki. Gbogbo awọn Orilẹede wọnyi lo ni anfani ti wọn pese fun awọn arinrin ajọ.
Ṣe iwadii daradara
O ṣe pataki pe ki ẹnikẹni to ba fẹ Japa, ko se iwadi lori ibi to n lọ. Máa gbinyanju lati lọ sọ Orilẹede ti o ko mọ ohunkokun nípa ibi ti oun lọ
Ọpọlọpọ lo ti di ẹni awati nitori pe wọn ko ni oye to peye lórí Orilẹede tí wọn lọ.
Yala fun eto ẹkọ ni tabi lati lọ sisẹ, o ṣe koko pe.
Iwadii to pe peye lori agbegbe ti ẹniyan lọ ṣe pataki nitori o le sọ eeyan lọwọ aburu.
Mọ nipa iwe irinna rẹ ati eto to rọ mọ ọ.
O ṣe pataki ko mọ nípa iwe irinna rẹ nitori orisirisi eto lo dero mọ iwe irinna.
Awọn Orilẹede miiran fi aye silẹ làti mu eeyan dani, ti awọn miiran si lodi mu mu pelu rẹ wa so Orilẹede wọn.
Aṣa wa ko papọ rara
Ko to kuro lorilẹede Naijiria, mo pe dajudaju pe asa ati ise ibi to n lọ yatọ si ibi to ti n bọ, ti o si ṣe koko ko bọwọ fun asa ati ise won.
O ṣíṣe kí asa ati ise wọn ba rẹ laramu sugbọn o ṣe koko ko bọwọ fun asa wọn.
Àwọn asa tuntun ati ara me rírí ni yoo pọju sugbọn laipẹ, eeyan ma mọ nípa rẹ.
Ija ẹlẹyamẹya eeyan funfun sí dudu (Racism)
Gẹgẹ bii eeyan dudu, o sese ko ba ara rẹ ní awọn ilu ti wọn ko ti fẹran eeyan dudu rara sugbọn suuru le bori ohun gbogbo.
Kọ lati tẹle ofin ilu ti o n lọ
Ki o to kuro lorilẹede Naijiria, ó ṣe pataki ko mọ pe o gbọdọ bọwọ fun òfin ilu naa.
Ijiya nla wa fun ẹnikẹni to ba kọ lati tẹle ofin naa.
Awọn ofin wọnyi ni o ni ko ki n ṣe ẹsẹ lorilẹede Naijiria ti o ti bọ sugbọn ẹsẹ ni to ba de awọn ilu miiran.