'Ọ̀pọ̀ ọdún ni ọkọ mi fi lòògùn oorun fún mi kó lè baà ráàyè máa fipá bá mi lò pọ̀'

    • Author, Jane Deith and Emma Forde
    • Role, BBC File on 4 Investigates
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 8

Nigba ti obinrin kan, Kate, ati ọkọ rẹ jokoo nirọlẹ ọjọ kan lati sọrọ, Kate ko ro o pe ohun to jade lẹnu ọkunrin naa le jade.

"Mo ti n fipa ba ẹ lo pọ tipẹ. Mo n lo oogun oorun fun ẹ mo si maa n ya fọto rẹ fun ọdun pipẹ."

Kate (orukọ rẹ gan-an kọ niyẹn) ko le sọ nnkan kan. O n wo ọkọ rẹ pẹlu iyanu. Ohun ti ọkọ n sọ ko tilẹ ye e

"Bo tiẹ ṣe sọrọ yẹn fun mi ko jọ ti nnkan to lagbara rara, afi bii keeyan maa beere pe ṣe spaghetti la fẹẹ jẹ lalẹ yii ni tabi burẹdi?''

Kate lo fi iyalẹnu rẹ han bẹẹ.

Ikilọ: Awọn ọrọ to ni i ṣe pẹlu ibalopọ lọna ipa lo wa ninu iroyin yii.

Fun ọpọlọpọ ọdun, nigba ti wọn ba wa ninu ile, ọkọ Kate maa n ṣe bo ṣe wu u ni.

O hu iwa ipa ninu ibalopọ, bẹẹ lo maa n lo oogun nilokulo yatọ si bo ṣe yẹ ko lo o.

Awọn igba kan wa ti Kate yoo ji ti yoo si ba ọkunrin naa lori rẹ, ti yoo maa ba a lo pọ lai jẹ pe o tilẹ beere boya iyawo fẹẹ ṣe.

Oju oorun ni Kate maa n wa nigba tọkọ rẹ ba n ba a lo pọ. Ifipabanilopọ ni a mọ eyi si.

To ba ṣe e tan ṣaa, yoo wa maa bẹbẹ, yoo ni oun paapaa ti sun tẹlẹ, oun ko mọ bo ṣe jẹ ti oun fi de ori iyawo oun. O sọ fun iyawo rẹ pe ara oun o ya, ati pe o jọ pe kinni kan n daamu oun ni.

Bayii ni Kate naa ba tun bẹrẹ si i ran an lọwọ lati ri itọju gba latọdọ awọn akọṣẹmọṣẹ dokita.

Ohun ti Kate ko mọ ni pe oogun oorun lọkọ n ju sinuu tii fun un lalẹ, ki obinrin naa le sun lai mọ ohun to n ṣẹlẹ layika rẹ.

'Bí mo bá fi lè sọ f'ọlọ́pàá, ikú dé'

Lẹyin to jẹwọ fun iyawo rẹ nipa ibalopọ tulaasi naa tan, o sọ fun un pe ko gbọdọ fi ọrọ naa to ọlọpaa leti.

Ọkọ Kate sọ pe to ba sọ f'ọlọpaa, iku ni fun un. Bẹẹ ni iyawo naa si ṣe yaa dakẹ, ko sọ nnkan kan.

Kate n ro pe baba awọn ọmọ oun naa n ṣaisan, o si n ṣoro fun un lati gba pe ẹni ti oun ti lo pupọ ninu aye oun pẹlu lo n ṣe oun radarada bẹẹ.

Ṣugbọn lẹyin oṣu diẹ, aṣiri ti ọkọ ni ko gbọdọ tu yii bẹrẹ si i daamu ọkan obininin naa, o si bẹrẹ si i han ninu igbesi aye rẹ.

Kate sọ pe aarẹ ara lo kọkọ kọlu oun, nigba to ya lo bẹrẹ si i rù, ijaya si wọle si i lara.

Nigba to ku diẹ ki ọdun kan pe ti Kate ti n mu ọrọ naa mọra, ti ọkan rẹ ko si balẹ, bo ṣe sọ gbogbo ẹ fun aburo rẹ obinrin kan niyẹn.

Biyẹn ṣe gbọ lo ṣalaye ẹ fun mama wọn, ti mama naa si pe ọlọpaa, wọn si mu ọkọ Kate, wọn fọrọ wa a lẹnu wo.

Ṣugbọn lẹyin ọjọ kerin, Kate funra ẹ pe awọn ọlọpaa Devon ati Cornwall, o loun ko fẹẹ tẹsiwaju ninu ẹjọ naa mọ.

"Emi nikan kọ ni idaamu ọrọ yii ba, o kan awọn ọmọ mi naa. Baba wọn paapaa ko le ri bii ti tẹlẹ mọ."

Kate lo ṣalaye bẹẹ.

Ṣugbọn ko fẹ ki ọkunrin naa maa ba oun gbele bii ọkọ mo, idi niyẹn ti ọkọ fi ko jade nilee wọn.

Lẹyin eyi, Kate bẹrẹ si i ronu si i nipa ohun to ṣẹlẹ, lẹyin oṣu mẹfa, o tun gba ọdọ awọn ọlọpaa lọ.

Iwadii bẹrẹ, ẹni to lewaju iwadii naa ni Det Con Mike Smith.

Kate ṣalaye pe awọn ọtẹlẹmuyẹ naa ran oun lọwọ gan-an, wọn jẹ ki oun mọ pe ọpọ iwa ọdaran lọkọ oun hu ti oun si la kọja, ifipabanilopọ si ni iwa to hu si oun, ṣugbọn oun ti gba ominira ati igboya oun pada lẹyin lilọ rẹ.

Ọrọ̀ dé kóòtu lẹ́yìn ọdún márùn-ún

Lẹyin ọdun marun-un ti ọkọ Kate jẹwọ ẹṣẹ ni ọrọ naa de kootu, iyẹn ni 2022.

Lasiko igbẹjọ, ọkunrin naa sọ pe Kate fẹran ki eeyan de e mọlẹ to ba n sun, to ba si ji, o maa n fẹ ki ọkunrin ba oun lo pọ ni.

O ni loootọ ni oun maa n kun un loorun, ṣugbọn ki oun baa le de e mọlẹ lai jẹ pe o ji ni oun ṣe n kun un loorun, o ni i ki i ṣe ki oun ba a le fipa ba a lo pọ. Ṣugbọn adajọ ko gba a gbọ.

"Mo ri ọrọ rẹ bii eyi ti ko ba laakaye mu, ohun to buru ju laye rẹ lo ṣe fun obinrin yii, o si bẹrẹ si i juwee rẹ bii ẹni to fẹran ipa ki o too le ba a lo pọ"

Adajọ Det Con Smith lo sọ bẹẹ."

Lẹyin ọsẹ kan igbẹjọ, ile-ẹjọ sọ pe ọkọ Kate tẹlẹ jẹbi ifipabanilopọ, ifiyajẹni nipa ibasun, ati mimọ-ọn-mọ lo oogun fun ẹlomii.

Ninu idajọ rẹ, Adajọ ṣapejuwe ọkunrin yii bii ẹni to mọ ti ara rẹ nikan, ti ko ro ti ẹnikeji mọ tirẹ, ti ko si tun fi han pe oun kabaamọ iwa oun.

Adajọ paṣe ẹwọn ọdun mọkanla fun un kia, pẹlu aṣẹ pe ko gbọdọ de ọdọ iyawo rẹ tẹlẹ naa mọ laye..

Bi ohunkohun to jọ mọ ohun to wa ninu iroyin yii ba ti ṣẹlẹ si ọ ri , o le ri alaye kikun ati iranlọwọ ni BBC's Action Line.

Ọdun mẹta lẹyin iṣẹlẹ yii, Kate naa bẹrẹ mu iyoku aye rẹ, o si dojukọ awọn ọmọ to bi lati tọju wọn bo ṣe yẹ.

Iṣẹlẹ yii fa aarẹ si i lara, dokita si sọ pe o ti ni aisan ti a mọ si 'Post-traumatic stress disorder (PTSD), iyẹn ailera to maa n ṣẹlẹ lagọ ara lẹyin ti eeyan ba koju wahala kan.

Iṣoro naa jẹ ti ọpọlọ, ogooro ẹyin ati awọn ẹya miran to n gbe eeyan ro, ohun to si fa a ni idaamu ọkan to la kọja.

Kate ṣe afiwe ohun to ṣẹlẹ si i bii ti obinrin ọmọ ilẹ Faranse kan, Gisèle Pelicot, ẹni ti ọkọ rẹ tẹlẹ maa n kun loorun ti yoo si ba a sun, ti yoo si tun pe ọkunrin bii mejila wa pe ki wọn waa ko ibasun fun iyawo oun loju oorun.

"Mo ranti nigba yẹn, niṣe ni mo maa n ba a nireti pe yoo ri iranlọwọ to nilo gba." Kate lo wi bẹẹ.

"Chemical control", ni orukọ ti wọn n lo fawọn to ba n lo oogun lati ba eeyan sun labele bayii, iwa naa si ti n tan kalẹ."

Ọjọgbọn Marianne Hester, lati Yunifasiti Bristol's Centre for Gender and Violence Research lo sọ bẹẹ.

Ifipabanilopọ ko ṣee dakẹ si

Awọn ẹsun bi eyi ki i ri oju ọjọ lawọn apa ibo mi-in, nitori iyatọ to de ba ọna tawọn ọlọpaa n gba ṣe akọsilẹ ṣeun bawọnyi.

Dame Nicole Jacobs, Kọmiṣanna fun ifiyajẹni labẹle ni England ati Wales lo sọ bẹẹ.

"Bi awọn minisita ba fẹ ki igbiyanju wọn lori awọn to n fipa ba obinrin lo pọ so eso rere, a gbọdọ ṣalaye awọn iṣẹlẹ ifiyajẹni labele yii bo ṣe yẹ fawọn ọlọpaa.

" Ki i ṣe nitori ati mu awọn to jẹbi ẹsun yii nikan, bi ko ṣe kawọn obinrin le ri iranlọwọ ti wọn nilo lẹyin ifiyajẹni naa."

Iwa ọdaran leyi kaakiri UK, ofin si koju rẹ, titi kan ti ọdun 1861 to tako o.

Labẹ ofin tuntun yii, ni England ati Wales, ẹni tọwọ ba tẹ yoo fi ẹwọn ọdun mẹwaa jura.

Jess Phillips, Minisita to n ri si aabo awọn obinrin ati ọmọdebinrin,ṣapejuwe iwa ipa nibi ibalopọ bii ohun to n ṣakoba fun igboya ati aabo awọn to ba ṣẹlẹ si.

Igbesẹ ti bẹrẹ lati jẹ ki ofin yii de Northern Ireland naa.

Ijọba sọ pe oun ko ni ipinnu ati ṣeto fun iwa ọdaran ara ọtọ bi eyi, ṣugbọn agbeyẹwo n lọ lorii rẹ.

Kate pada gba idajọ ododo, ṣugbọn ọkọ rẹ ko ba mu iwa ẹṣẹ naa jẹ gbe bi iyawo ko ba fi to awọn agbofinro leti.

"Mo fẹ kawọn eeyan mọ pe ifiyajẹni maa n ṣẹlẹ labẹle ju bi a ṣe n ro lọ, mo ṣi n kẹkọọ lara ohun to ṣẹlẹ si mi ati bo ṣe nipa laye mi."

Kate lo sọ bẹẹ.

Get in touch

Have you been a victim of spiking? Have you or someone you know been personally affected by the issues raised in this story? If you feel able to do so, get in touch.