"Mò ń kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní ìmọ̀ ẹ̀kọ́ Kẹ́mísírì lédè Yorùbá, fún àgbéga akẹ́kọ̀ọ́ àti èdé abínibí"

"Mò ń kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní ìmọ̀ ẹ̀kọ́ Kẹ́mísírì lédè Yorùbá, fún àgbéga akẹ́kọ̀ọ́ àti èdé abínibí"

Fun ọpọlọpọ awọn akẹkọọ, imọ isiro ati ẹkọ nipa imọ sayẹnsi maa n jẹ ẹkọ to nira fun wọn lati mọ.

Koda, aimọye akẹkọọ ni ko lee se awọn isẹ to nii se pẹlu imọ sayẹnsi nitori bo se le fun mọ lati kọ imọ nipa ẹkọ Kẹmisiri (Chemistry).

Sugbọn ọpọ awọn onimọ nipa eto ẹkọ lo ti n pariwo saaju pe yoo dara ki awọn olukọ maa fi ede abinibi kọ awọn akẹ́kọọ nile ẹkọ , paa paa imọ isiro ati awọn ẹkọ to jẹ mọ imọ ijinlẹ sayẹnsi bii Physics, Chemistry ati Biology.

Boya eyi lo se iwuri fun olukọ imọ sayẹnsi kan, Ahmed Akanni Azeez, to se n fi ede Yoruba kọ awọn akẹkọ rẹ nipa imọ ẹkọ Kẹmisiri paapaa lori ayelujara.

"A bẹrẹ eto ẹkọ Kẹmisiri lori ayelujara naa nitori ibẹ ni awọn ọdọ pọ si"

BBC Yoruba kan si Azeez lati wa salaye idi to se sagbekalẹ oju opo naa ati lati mọ bo ti n so eso rere si.

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Ahmed Azeez ni erongba oun lati mase jẹ ki ede Yoruba lọ sokun igbagbe lo mu ki oun maa fi ede naa kọ awọn akẹkọọ ni imọ Kẹmisiri lori ayelujara.

"Awọn akẹkọọ ko gba ti imọ Kẹmisiri rara, wọn ri bi ẹkọ kan to le, idi ree ti mo se ni ka fi ede abinibi kọ wọn.

A bẹrẹ eto ẹkọ Kẹmisiri lori ayelujara naa nitori ibẹ ni awọn ọdọ pọ si.

Bakan naa, mo fẹ gbe asa ati ede Yoruba ni arugẹ lo jẹ ki n maa fi ede naa kọ im Kẹmisir.

Ni awọn orilẹede India, China, Korea ati bẹẹ bẹẹ lọ, ede abinibi ni wn fi n kọ awọn akẹkọọ nibẹ."

Azeez ni imọ ede Yoruba niye lori pupọ, a si le fi kọ̀ awn imọ sayẹnsi miran bii Physics ati Biology.

"Fifi ede abinibi kọ imọ sayẹnsi yoo ran awọn ọmọ Naijiria naa lọwọ lati se iwadii imọ ijinlẹ fun agbega igbe aye wa gẹgẹ bo se n waye loke oku.

Awọn akẹkọọ to w anile ẹkọ bayii nifẹ eto yii, ti imọ Kẹmisiri si n ye wọn si yekeyeke.

A fẹ ko jẹ pe ede Yoruba ni wọn yoo fi maa kọ awọn akẹkọ ni kilaasi, mo si ti n se iwe jade pẹlu ede Yoruba lori igbesẹ naa."