Wo àwọn àgbà òṣèré tó fi àgbà ara kàwé gboyè fásitì

Ní ọjọ́rú, ọjọ́ Kẹẹ̀dógún, oṣù Kọkànlá ọdún 2023 ni gbajúmọ̀ olórin Fuji nnì, Akorede Babatunde Okunola tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Saheed Osupa kéde pé òun ti kẹ́kọ̀ọ́ gboyè ní ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì Ibadan.

Saheed Osupa tó fi ìkéde náà sórí ayélujára Instagram rẹ̀ ní ẹ̀ka ìmọ̀ nípa òṣèlú ìyẹn Political Science ni òun ti kẹ́kọ̀ọ́ gboyè náà.

Ó ní Second Class Honour, Upper Division ni òun gbé jáde nílé ẹ̀kọ́ ọ̀hún.

Osupa tí wọ́n bí ní ọdún 1969 ń kẹ́kọ̀ọ́ gboyè nílé ẹ̀kọ́ gíga fásitì lẹ́ni ọdún mẹ́rìnléláàdọ́ọ̀ta.

Ó fi àwòrán ayẹyẹ ìkẹ́kọ̀ọ́jáde rẹ̀ sórí ayélujára náà.

“Mo fẹ́ kí àwọn ènìyàn mọ̀ pé èmi, Ọba (Dr) Saheed Osupa Akorede ti di kẹ́kọ̀ọ́ gboyè ní ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì Ibadan.”

Ó ní òun dúpọ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún ìrìnàjò òun lórí ètò ìkẹ́kọ̀ọ́ náà.

Yàtọ̀ sí Saheed Osupa ọ̀pọ̀ àwọn òṣèré ló fi àgbà ara lọ sí ilé ẹ̀kọ́ gíga nínú ìgbìyànjú wọn láti fi ìmọ̀ kún ìmọ̀ wọn.

Lára wọn ni:

Odunlade Adekola

Ní ọjọ́ Kẹsàn-án, oṣù Karùn-ún ọdún 2018 ni gbajúmọ̀ òṣèré yìí parí ẹ̀kọ́ rẹ̀ nínú ìmọ̀ ètò káràkátà ní ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì Eko ìyẹn Unilag.

Ṣáájú ní oṣù Kọkànlá ọdún 2017 ni Odunlade tí kọ́kọ́ kéde rẹ̀ pé òun kò ní pẹ́ gba ìwé ẹ̀rí òun lẹ́yìn tó parí ìdánwó àṣekágbá rẹ̀.

Odunlade tó ti bẹ̀rẹ̀ eré ṣíṣe láti ọdún 1996 ní ìfẹ́ tí òun ní sí ẹ̀kọ́ ló jẹ́ kí òun padà sílé ẹ̀kọ́ gíga láti tẹ̀síwájú nínú ẹ̀kọ́ òun.

Ó ní òun máa ń ri dájú láti lọ sí yàrá ìkẹ́kọ̀ọ́ láti gbọ́ ẹ̀kọ́, òun máa ń ṣe àwọn ìdànwó bó ṣe tọ́ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun kìí sábà rí àyè tó bẹ́ẹ̀.

Ó fi kun pé òun kò fi ìgbà kankan sá ní kíláàsì títí òun fi parí.

Bákan náà ló rọ àwọn òṣèré tó ń bọ̀ lẹ́yìn rẹ̀ láti mú ẹ̀ka ní òkúnkúndùn.

Bolaji Amusan (Latin)

Ní ọjọ́ Kẹẹ̀dógún, oṣù Kẹwàá ọdún 2022 ni gbajúmọ̀ òṣèré, Bolaji Amusan tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Mr Latin kẹ́kọ̀ọ́ yege ní ilé ẹ̀kọ́ aládàni kan ní ìpínlẹ̀ Ogun.

Ìdùnnú ṣubú layọ̀ fún Mr Latin tó jẹ́ alága ẹgbẹ́ òṣèré TAMPAN ní ọjọ́ yìí ni nítorí ọjọ́ náà gan ni ọjọ́ ìbí rẹ̀.

Baba Latin bí ọ̀pọ̀ ṣe máa ń pè é ti máa ń ṣo pé òun gbàgbọ́ pé òun kò bá ti rìn jìnà nínú iṣẹ́ tí òun yàn láàyò ká ní pé òun bá kàwé ni.

Lẹ́yìn ọdún márùndínlógójì tí Latin ti bẹ̀rẹ̀ eré tíátà ni ó tó pinnu láti padà sílé ẹ̀kọ́.

Ebun Oloyede (Olaiya Igwe)

Ebun Oloyede ní kíkẹ́kọ̀ọ́ gboyè ní ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì jẹ́ ohun ìdùnnú fún òun.

Ó ní inú òun dùn gan láti máa kẹ́kọ̀ọ́ gboyè pẹ̀lú àwọn akẹgbẹ́ òun lẹ́nu iṣẹ́ tíátà.

Ní ilé gíga fásitì Crescent University, Abeokuta ni Olaiya náà ti kẹ́kọ̀ọ́ gboyè.

Owolabi Ajasa

Owolabi Ajasa tó gbajúmọ̀ fún ṣíṣe ọlọ́pàá nínú eré náà parí ẹ̀kọ́ pẹ̀lú àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ – Latin àti Olaiya ni ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì Crescent University.

Òun náà wà lára àwọn gbajúmọ̀ òṣèré tó fi àgbà ara lọ sí ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì.