Àbọ̀ ìwádìí rèé lórí ohun tó mú kí owó tòmátò gbẹ́nu sókè, táwọn àgbẹ̀ fi ń kérora gbèsè

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Awọn agbẹ to n gbin tomato lorilẹede Naijiria ti n kerora bayii latari Kokoro ajẹnirun kan to wọ oko nnkan ọgbin yii, to si n pa wọn.

Ibẹru gba ọkan awọn agbẹ lorii Kokoro naa ti wọn pe ni 'Tuta Absaluta'

Ohun ti awọn agbẹ ọlọgbin tomato n sọ ni pe Kokoro to wọ oko tomato kaakiri ilẹ yii le mu ko wọn gogo.

Ọpọ awọn agbẹ ni ọrọ yii ti kan, paapaa awọn ti wọn ti ko owo nla sinu ọgbin tomato ṣaaju ki kokoro too de.

Wọn ni awọn ti n ri ọwọja Tuta Absaluta, awọn tomato ko so daadaa mọ.

Gẹgẹ bi alaye awọn agbẹ yii, wọn ni lati ibẹrẹ oṣu Kẹta ọdun yii lawọn ti n ri apẹẹrẹ kokoro ajẹnirun naa, to n kọlu oko tomato lapa Ariwa ilẹẹ wa.

Awọn agbẹ kan si ti padanu ẹgbẹlẹgbẹ miliọnu nitori kokoro naa.

Kòkòrò tó ń jẹ tomato ti wà láwọn ìpínlẹ̀ yìí:

Gẹgẹ bi Alaaji Sani Danladi Yada-Kwari, Alaga awọn agbẹ onitomato ni Kano ṣe ṣalaye, o ni kokoro ọhun ti de :

Kano, Jigawa ati Bauchi.

Danladi to tun jẹ Akọwe apapọ ẹgbẹ onitomato, sọ pe:

"O ti kan mi, paapaa ni Kano yii. Ọpọ eeyan to gbin tomato ni ko ti i maa ka wọn.

Awọn to gbin in lati oṣu Kọkanla si Ikejia, pẹlu aṣẹ Ọlọun, wọn o ti i ri nnkan kan ṣà loko wọn.

"Ẹnikan tiẹ wa to ti pari iṣẹ loko tiẹ, to ti ro pe oun yoo ko ere oko, niṣe ni awọn tomato rẹ jona. Ọjọ mẹta pere ni aran yẹn fi pa gbogbo tomato naa."

O ni idi niyẹn tawọn fi n ro o pe tomato yoo wọn gan-an lọdun yii, nitori aran ti ba wọn jẹ mọ oko.

Nigba to n sọrọ nipa ọṣẹ́ ti kokoro naa ti ṣe, Alaaji Sani Yada-Kwari sọ pe awọn ṣi n ṣe onka rẹ lọwọ.

Ṣugbọn mo fi da yin loju pe ni Kano nibi, awọn agbẹ ti padanu owo to to biliọnu lọna ogun naira"(20 billion naira)

Aràn to buru jai ni kokoro ti wọn n pe ni Tuta Absaluta yii, o lewu gan-an bi wọn ṣe sọ.

Danladi Yada-Kwari rọ awọn onitomato , paapaa ni Kano lati tete gbe igbesẹ, bi wọn ba kẹẹfin kokoro naa loko wọn.

O tun rọ ijọba pẹlu lati dide iranwọ.