N1.3trn l‘ọmọ Nàíjíríà sọnù sínú okoòwò CBEX, a ṣetán láti fojú àwọn aṣebi hàn - EFCC

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 8

Ajọ to n tanna wadi iwa ọdaran ni orilẹede Naijiria, EFCC ti fidi rẹ mulẹ pe oun ti n se iwadi si ẹsun kiko owo to to Trilliọnu kan ati biliọnu lna ọọdunrun naa jẹ lati ipasẹ eto idokowo ori ayelujara CBEX.

CBEX, tawọn ọmọ ilẹ okeere kan, ni ifọwọkọwọ pẹlu awọn ọmọ orilẹede yii lo la in ani ọjọ Aje eyi to ko ironu ba ọpọ oludokowo ti owo wọn wọ igbo atuu.

Nigba to n fidi isẹlẹ naa mulẹ fun iwe iroyin Punch, agbẹnusọ fun ajọ EFCC, Dele Oyewale ni ajọ naa yoo fọwọsowọpọ pẹlu ajọ ọtẹlẹmuyẹ Interpol lati fi oju awọn asebi yii

O ni aayan ti n lọ lati mu awọn eeyan naa to sisẹ ibi yii labẹle ati loke okun.

EFCC salaye pe "Ki CBEX to la ina, la ti n se iwadi wa amọ ni bayi to ti kogba wọle, gbogbo awọn eeyan to sisẹ gbajuẹ yii ni yoo fi imu ko ata ofin.

"A maa ri pe a gba awọn ọmọ Naijiria silẹ lọwọ awọn iwa lilu jibiti to ni I se pẹlu okoowo sogun dogoji. Ẹ ma gbagbe pe a ti kọkọ sekilọ saaju fawọn ọmọ Naijiria nipa awọn ileesẹ olokoowo ori ayelujara bii mejidinlọgọta ti ọwọ wọn ko mọ.

A si tun n se iwadi abẹnu lati mọ awọn okoowo ori alejujara sogun di ogoji to n sisẹ yika orilẹede yii."

Owo to to Trilliọnu kan ati biliọnu lọna ọọdunrun naira ni awọn ọmọ Naijiria padanu sọwọ awọn onijibiti naa.

"Owóyàá $500 ni mo fi bẹ̀rẹ̀ okòòwò CBEX, wọ́n lérí fún mi pé owó mi yóò di $11,000 àmọ́ òfò ló já sí"

Ọpọlọpọ awọn eeyan to kowo le atẹ okoowo sogundogoji lori ayelujara, ti ọpọ eeyan mọ si CBEX, ti n gbarata lẹyin ti iroyin lu sita wi pe owo wọn ti wọgbo.

BBC Yoruba ba eeyan mẹta ọtọọtọ to ta kalokalo naa sọrọ, lẹyin ti owo wọn di awati, wọn si sọ ohun ti oju wọn ri lori ọrọ naa.

Ẹni akọkọ to ba wa sọrọ, Arakunrin Musiliu (kii ṣe orukọ rẹ gangan) ṣe alaye fun akọroyin wa wi pe, ọkan lara awọn ọrẹ oun lo fi CBEX lọ oun, ni nnkan bii oṣu mẹrin sẹyin.

O ni ẹẹdẹgbẹta Dollar, $500 ni oun si fi bẹrẹ okoowo naa nitori wọn ṣe ileri fun oun pe owo naa yoo di ẹgbẹrun mọkanla Dollar, $11,00 laarin oṣu mẹfa.

Musiliu ni, "Ọrẹ mi to ṣi CBEX fun mi ti n gba ọpọlọpọ owo jade nibẹ lati ọdun kan sẹyin.

O ti gba oju owo ati ọpọlọpọ ere nibẹ.

Eyii lo mu ki emi naa lọ wa owo ya lati le jẹ ere gẹgẹ bii ọrẹ mi."

Owo Arakunrin yii ti le ni ẹgbẹrun meji Dollar, $2,000 ko to di pe ọrọ bẹyin yọ.

" Mo ti gba owo jade ni igba mẹta ọtọọtọ ní apo CBEX, mo tun ta ilẹ mi kan lati kowo le CBEX, ati ilẹ̀, ati owo, o di pafe"

Ẹni ikeji to ba wa sọrọ jẹ oniṣowo to n ṣe karakata.

Alaye to ṣe ni pe awọn alabaṣiṣẹpọ oun lo fi okoowo CBEX lọ oun, ki oun to kowo le e.

O si ti gba owo jade ni igba mẹta ọtọọtọ, ki o to wa ta ilẹ kan to ni ni ipamọ pẹlu igbagbọ wi pe oun yoo ra ilẹ tuntun mii pada, ti owo CBEX ba de tan.

Ati ilẹ ti owo, gbogbo rẹ ti di pafe bayii nitori ko si apẹrẹ wi pe owo naa yoo ṣe e gba pada.

Bakan naa ni akọroyin wa tun ba arabinrin kan ti ko fẹ ki a da orukọ oun sọrọ.

O ni ọjọ ti oun fẹ yọ lara ẹgbẹrun mejidinlaadọta Dollar, $48,000 to n bẹ ninu apo asunwọn CBEX oun, ni wọn so apo naa rọ.

O ni ẹnikẹni ko si le gba owo jade, ki o to wa di pe wọn fa gbogbo owo naa lọ bayii.

Inu wahala ati idamu yii ni ọpọlọpọ eeyan to kowo le CBEX wa lọwọlọwọ bayii nitori gbogbo ileri ti awọn alakoso atẹ idokowo naa ṣe, ni wọn ko muṣẹ.

"Awọn to da CBEX silẹ sọ fun awọn oludokoowo wọn pe awọn fẹ mu adinku ba oṣi ati iṣẹ nilẹ adulawọ ni pẹlu ida ọgbọn"

Saaju asiko yii ni awọn to da CBEX silẹ ti n sọ fun awọn oludokoowo wọn pe awọn fẹ mu adinku ba oṣi ati iṣẹ nilẹ adulawọ ni iwọn ida ọgbọn, 30%.

Ileri mii tun ni wi pe ẹni to ba ko ọpọlọpọ ero wa, to si gba oye VIP 9, yoo ni anfani lati rin irinajo lọ si orilẹede ti o ba wuu, yoo si tun mu mọlẹbi rẹ meji dani.

Awọn alakoso atẹ sogundogoji naa kọkọ fi da wọn loju pe awọn o da owo naa pada, ṣugbọn lẹyin wakati kan ti wọn ṣe ileri yii ni wọn tun yi ohun pada.

Wọn ni wi pe ki ẹni to ba fẹ gba owo rẹ pada kọkọ lọ san ọgọrun tabi igba Dollar si apo asunwọn rẹ.

Eyii gan an lo mu ki o han si awọn to kowo le CBEX pe ko si atunṣe mọ.

Labẹ bẹẹ si ni awọn oludokoowo to n fi apa janu fi yawọ ofisi CBEX to n bẹ ni agbegbe Oke Ado niluu Ibadan lọjọ Ẹti, ti wọn si ko ọpọlọpọ ẹru lọ.

Kí ló ń jẹ́ CBEX, okoòwò ayélujára tó kò àwọn ọmọ Naijiria sínú gbèsè apanilẹ́kún?

Lati bii ọsẹ kan bayii ni ọpọ eeyan ti n pariwo nipa okoowo sogun di ogoji kan ti wọn se lori ayelujara, ti wọn n pe ni CBEX.

Ọpọ ọmọ Naijiria to n fi ika hanu lasiko yii lori ayelujara ni wọn si ko ọpọlọpọ owo sinu ileeṣẹ yii.

Ṣugbọn ọrọ bẹyin yọ ni ana ode nigba ti ileeṣẹ naa ṣadede la ina, ti wọn si ko owo gbogbo awọn onibara wọn lọ.

Bi owo naa se n sọ ogun di ogoji ni ko ye ọpọlọpọ eeyan sugbọn ọrọ nipa CBEX bayii ti ń gba omije loju ọpọ eeyan.

Ki ni wọn n pe ni CBEX gangan?

Gẹgẹ ohun ti o a ri ka, Ileeṣẹ CBEX ni wọn da silẹ tí ni ọdun 2022, eyiun ọdun mẹta sẹyin.

Cripto Currency ni wọn ni awọn n ṣe, ti wọn sọ owo awọn eeyan di ilọpo meji.

Ṣugbọn ni ọsẹ to kọja, CBEX ko jẹ ki awọn eeyan gba owo wọn sita ,ti ariwo si sọ.

Kete ti ileeṣẹ CBEX ko owo awọn eeyan ni awọn ọdọ kan yawọ ọfisi wọn niluu Ibadan, ti wọn si bẹrẹ si ni ko gbogbo ẹru wọn lọ.

Fọnran kan to lu sita lori ayelujara safihan bi awọn ọdọ kan ṣe binu yawọ ọfisi naa to wa niluu Ibadan, ti wọn si n da gbogbo nnkan ru, koda wọn ji ọpọlọpọ awọn nnkan ini wọn lọ.

Bakan naa ni ana ode yii ni Ileeṣẹ CBEX ko gba wọle, ti wọn si tun sọ fun onibara pe ẹni to ba ni apapọ owo to din ni ẹgbẹrun kan Dọla, san owo ọgọrun un Dọla, ti awọn to ni apapọ owo to le ni ẹgbẹrun kan Dọla, lọ san owo to jẹ igba Dọla.

Eyi lo bi ọpọlọpọ ninu sugbọn CBEX ni wọn ko ni anfani si owo wọn, ti wọn ko ba san owo tuntun ti wọn ni ki wọn san.

Ki ni awọn ọmọ Naijiria n sọ nipa bi CBEX ṣe lulẹ?

Ni ọsẹ to kọja ni Man of Letters (@Letter_to_Jack) gbe sori ayelujara pe oun gbọ nipa eeyan kan to ko ẹgbẹrun kan Dọla sinu CBEX, to si ti gba ẹgbẹrun marun un jade sita.

"Lẹyin ọpọ ayẹwo, mo ri pe sogun di meji ni ileeṣẹ wa nipa.

"O ti tọ ni pe awọn eeyan n gba owo jade lia padanu nnkan."

Ẹlomiran aust;n (@0kparam), bu ẹnu atẹlu awọn eeyan to n lo CBEX, to si jẹ ko di mímọ pe opin rẹ ti de tan.

@drpenking ni "bayii CBEX ti pari, wọn titi gbogbo oju opo wọn. Wọn ko gbogbo owo awọn eeyan to ba wọn dowo pọ."

@alameen ni"O ki n ṣe onisowo to ba jẹ pe o ko owo sinu CBEX.

"Ole ni ẹ to ba ṣe bẹẹ, to si fẹ fi ọna ẹru wa owo. N ko banujẹ fun ẹnikẹni to padanu owo wọn.

"To ba tun ṣe diẹ si, ti omiran ba tun jade, awọn ọmọ Naijiria yoo tọwọ bọ."

Bakan naa ni onibara sọ pe CBEX ti ba aye oun jẹ nitori gbogbo owo rẹ lo ko sinu CBEX.

Ajọ eleto aabo SEC sọrọ nipa CBEX

Ajọ eleto aabo SEC ti sọrọ nipa CBEX, ti wọn si jẹ ko di mímọ ileeṣẹ naa ko fi igba kankan forukọ silẹ pẹlu ajọ eleto aabo.

Saaju ni Ọga ajọ eleto aabo, Emomotimi Agama ti kilọ fun awọn ọmọ Naijiria pe ki wọn ma dowo pọ pẹlu ileeṣẹ kankan ti wọn ko forukọ pẹlu ijọba.

"Laipẹ yii ni a ri ọrọ kan lori ayelujara nipa ileeṣẹ yii ti iroyin nipa bi ileeṣẹ naa ṣe tí lulẹ si gba ori ayelujara.

"Koda mo rí atẹjiṣẹ kan ti wọn fi ransẹ si mi. Mo n fi gbogbo ẹnu sọ pe ileeṣẹ ti wọn ko ba fi orúkọ silẹ pẹlu ijọba, ayederu ni wọn.