Russia rọ̀jò àdó olóró sórí Ukraine, èèyàn 34 kú, 117 míì farapa

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

O kere tan, eeyan mẹrinlelọgbọn lo ti jade laye, nigba ti awọn 117 mii, ti ọmọde marundinlogun wa lara wọn farapa lẹyin ti ado oloro Russia balẹ si Ukraine.

Nnkan bii aagọ mẹwaa kọja iṣeju marundinlogun aarọ ni ado oloro naa balẹ si ayika ile ẹkọ giga Sumy State University.

Awọn aworan ati fidio lati ibẹ ṣafihan awọn ẹya ara eeyan to ja wẹlẹwẹlẹ silẹ, ko din ni ọmọde meji to ba iṣẹlẹ naa lọ.

Aarẹ Volodymyr Zelensky sọ pe lara awọn to farapa ni ọmọ tuntun ti wọn ṣẹṣẹ bi ninu ọdun yii wa, amọ awọn adoola ẹmi n ṣiṣẹ takuntakun lati doola awọn ti ọrọ naa kan.

Zelensky ni "Aarin ilu gangan ni ado oloro naa balẹ si lọjọ Isinmi tọ jẹ ayajọ isinmi ọpẹ...."

Titi di asiko ti a n ko iroyin yii jọ, ijoba Russia ko tii sọ nnkankan nipa ikọlu ọhun.

Awọn alaṣẹ ni Ukraine sọ fun BBC pe ile to bajẹ to ogun.

Wọn fi kun ẹkọ mẹrin wa lara awọn ibi ti ikọlu ọhun pa lara.

Zelensky ti wa ke si awọn orilẹede mii lagbaye fun iranlọwọ latari pe Russia ko dawọ ogun naa duro bo tilẹ jẹ pe ijiroro alaafia n lọ lọwọ.

Zelensky ke si Trump lati bẹ Ukraine wo

Ẹwẹ, Aarẹ Volodymyr Zelensky ti ke si Aarẹ Amẹrika, Donald Trump pe ko bẹ orilẹede naa wo ṣaaju adehun kankan pẹlu Russia lati fopin si ogun naa.

Zelensky lo sọ ọrọ naa ninu ifọrọwerọ pẹlu ileeṣẹ iroyin CBS.

O ni "Jọọ, ki a tilẹ to gbe igbesẹ tabi ṣe idunadura kankan, mo fẹ mo fẹ ki o wa wo awọn araalu, awọn jagunjagun, ile iwosan, ile ijọsin, awọn ọmọde ti wọn ti farapa tabi jade laye."

Ifọrọwerọ naa lo waye ṣaaju ko ado oloro Russia tuntun yii to balẹ ni Ukraine.

Russia ko tii fesi si ọrọ ado oloro naa amọ Trump ni oun gbọ pe aṣiṣe ni ado oloro ọhun.