You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
‘Ẹgbẹ̀ òkùnkùn wù mí láti darapọ̀ mọ́ ni mo ṣe darapọ̀, wọn kò fi ipá mú mi’
Ọkunrin ẹni ọdun mọkanlelọgbọn kan ti orukọ ẹ n jẹ Damilare Saheed ti ṣalaye peko si ẹnikẹni to fipa mu oun lati wọ ẹgbẹ okunkun, ẹgbẹ naa kan wu oun lati wọ loun fi darapọ mọ wọn.
Damilare Saheed sọ eyi di mimọ ninu ọrọ to sọ lasiko ti awọn ọlọpaa fi n ṣe afihan oun atawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun miran twọ tẹ lolu ileeṣẹ awọn ọlọpaa ipinlẹ ogun to wa ni Eleweeran nilu Abẹokuta.
O ni nnkan bii ọdun kan abọ sẹyin loun darapọ mọ ẹgbẹ okunkun Ayee lagbegbe Ijoko Ọta ni ipinlẹ Ogun.
- Kélé òfin gbé arákùnrin tó lu ọlọ́pàá ní àlùbami ní'pínlẹ̀ Ondo
- Ṣé lóòtọ́ ní Sunday Igboho ti gba ìtúsílẹ̀? Ohun tí á mọ̀ réè
- Iléẹjọ́ dájọ́ ikú fún ọlọ́pàá tó pa Amòfin Bolanle Raheem lọ́jọ́ kérésìmesì
- A kò fìgbà kankan fi Mohbad sí àhámọ́ – NDLEA sí iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá
- Ilé ẹjọ́ pàṣẹ pé kí wọn gbé Naira Marley wá jẹ́jọ́ ẹ̀sùn lílu jìbìtì wíwọ́ ike owó
Ọrẹ mi lo pe mi si ẹgbẹ okunkun mo si fi tayọtayọ darapọ - Afurasi ẹgbẹ okunkun ti ọlọpaa mu l'Ogun
O niiṣẹ atẹ aworan alarambara sara aṣọ, ike ati bẹẹ bẹẹ lọ, iyẹn Sign and Printing ni oun kọ
Damilare ṣalaye pe ọrẹ oun kan to n jẹ J.Boy lo pe oun sinu ẹgbẹ naa toun si da a lohun kiakia.
‘’O kan wu mi ki n darapọ mọ wọn naa ni, mo dẹ di ara wọn. Mo fi n ṣiṣẹ to ba yọju, igba mii iṣẹ awọn oloṣelu maa wa, mo maa tẹle wọn.
‘’ Wọn ko fipa mu mi lati di ara wọn o, o wu mi ni mo darapọ mọ wọn.’’
Àwọn kan ninu ahamọ ọlọpaa ti mo wa ṣi tun fẹ darapọ mọ ẹgbẹ okunkun bi wọn ba jade – Afurasi ẹgbẹ okunkun
Nigba to n sọrọ nipa anfani to ti jẹ ninu jijẹ ọmọ ẹgbẹ okunkun yii, Damilare sọ pe ko si ere kankan nibẹ.
O ni ere toun jẹ naa ni ibi toun ba ara oun yii, iyẹn ahamọ ọlọpaa, abamọ lo si jẹ foun gẹgẹ bo ṣe sọ.
O fi kun un pe oun ko le gba ẹnikẹni nimọran ninu awọn ọdọ boya ki wọn ṣe ẹgbẹ okunkun tabi ki wọn ma ṣe e, nitori bi oun ṣe n koju iṣoro toun lọwọ yii ni awọn mii ti awọn jọ wa ninu sẹẹli ṣi n gbero lati lọọ di ọmọ ẹgbẹ okunkun nita bi wọn ba jade.
O ni bi oun ba n gba wọn nimọran bayii, iyẹn ko ni ki wọn gbọ, ohun ti kaluku ba fẹẹ ṣe lo maa ṣe.
Ileeṣẹ ọlọpaa ti ni ọmọkunrin yii atawọn yooku rẹ yoo foju baleẹjọ laipẹ.