You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Wo bí Efcc ṣé gba ẹ̀tọ́ ₦19m padà farábìnrin ilẹ̀ Amẹrika tí ọmọ yahoo lu ní jìbìtì
Didun ti pada kẹhin adun ewuro fun arabinrin ọmọ ilẹ Amẹrika kan ti o ko sọwọ ọmọ yahoo to lu ni jibiti tori pe o n wa ori ade.
LỌjọbọ to kọja yi ni ajọ to n gbogun ti iwa jẹgudujẹra ni Naijiria Efcc da ẹtọ rẹ ti wọn gba lọwọ ogbologbo gbajuẹ kan Aisosa Kelvin Ohue pada fun arabinrin Cherlydene Cook.
Ninu awọn nkan ti Efcc da pada fun ni iye owo miliọnu mọkandinlogun Naira, ile ibugbe fulaati oniyara mẹta kan to wa ni Amagba ni ijọba ibilẹ Oredo ni ipinlẹ Edo.
Bakan naa ni wọn gba ọkọ ayọkẹlẹ Lexus E350 kan, foonu meji, iPhone 13 Pro Max ati Samsung A31 pada lọwọ ọmọ yahoo yi fun arabinrin naa.
Ni ilu Abuja ni wọn ti da awọn dukia wnyi pada fun arabinrin Cheryldene toati Amẹrika wa gba awọn nkan ini rẹ yi pada.
Ṣaaju ni adajọ C.E Nwecheonwu ti ile ẹjọ giga Kuje ni Abuja ti gbe idajọ kalẹ ki wọn gba awọn dukia yi pada lọwọ Orhue.
Eyi waye lẹyin ti ile ẹjọ fidi rẹ mulẹ pe o jẹbi ẹsun onigun mẹta to da lori fifi ọna eru gba owo lọdọ arabinrin Cherlydene Cook.
Irọ banta ni arakunrin ọdaran yi pa fun arabinrin naa to si pe ara rẹ ni orukọ gbajugbaja oṣere Fredrick Leonard lati le fi gba owo lọwọ rẹ.
Ẹsun alakọkọ ti ile ẹjọ ka sọ pe ''irẹ Aiosa Kelvin Orhue ti inagijẹ rẹ n jẹ Fredrick Leonard fi ọna ẹburu gba owo miliọnu mẹrinlelọgọrun lọwọ Cherlydene Cook pe o nifẹ rẹ ati pe o ṣetan lati fẹ ẹ. O parọ fun debi pe o gbagbọ ninu rẹ pe lootọ lo fẹ fi ṣaya ti eleyi si tako ofin to de wiwu iwa ajẹbanu''
Arakunrin Orhue bẹ adajọ pe oun jẹbi ẹsun ti wọn fi kan ti adajọ si ni ko lọ ṣẹwọn ọdun kan pẹlu anfaani lati san owo itanran miliọni kan Naira.
Ni oṣu kẹta ọdun yi lo foju ba ile ẹjọ ti iroyin si kan kaakiri lori iṣẹlẹ yi.
Koda oṣere tiata tolo orukọ ati aworan rẹ fi lu arabinrin yi ni jibiti dasi ọrọ naa loju opo Instagram rẹ.
Fredrick Leonard to jẹ ojulowo sọrọ pe kawọn obirin ya oju wọn silẹ daada ki wọn ma ba ko si panpẹ awọnonijibiti.
O tun wa ṣe alabapin aworan onijibiti ti ọwọ Efcc tẹ to n fi orukọ rẹ pa awọn obinrin lẹkun jayẹ.