Ọba tó bá fẹ́ fọnrere ẹ̀sìn Islam àti Krìstẹ́nì lórí oyè, kó lọ sí Mecca tàbí Jerusalem – Olówu ti ìlú Kuta

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ọba Adekunle Oyelude to jẹ Olowu ti ilu Kuta ti ilu Kuta ni awọn ọbalaye ni ilẹ Yoruba ti gbagbe ohun ti wọn jẹ ọba le lori, idi si niyi ti aṣa Yoruba ko fi jọ ọpọ loju mọ.

O lo sọ eyi nibi ayẹyẹ ti Aarẹ na Kakanfo ilẹ Yoruba , Iba Gani Adams gbe kalẹ nibi ajọdun Ọṣun Oṣogbo to waye lọjọ Ẹti.

Ọba Oyelude ni ihuwasi awọn ọbalaye kan si aṣa ilu ti wọn jọba le lori tabi ilẹ Yoruba lapapaọ ku diẹ kaato to si to akoko fun wọn lati mọ pe ko si Ọba ilẹ Yoruba ti wọn fi ẹsin kankan gbe gori oye yatọ si ẹsin abalaye ilẹ Yoruba.

“Ko si ọba ilẹ Yoruba ti wọn fi ade le lori ni ọọṣi o. ko si ọba ilẹ Yoruba ti wọn fi ade le lori ni mọṣalaṣi.”

O wa rọ aarẹ Ọna kakanfo Iba Gani Adams lati fi oṣelu silẹ ko si gbajumọ didaabo bo aṣa ilẹ Yoruba ki o ma ba a parun.

Ọba Adekunle Oyelude tun tesiwaju wi pe, ọba ilẹ Yoruba ko gbọdọ gbe ẹṣin Kristẹni tabi ti musulumi lori, ko wa ma tapa si isẹse ati asa ilẹ Yoruba.

“Ọba to ba fẹ fọnrere Islam lori oye ko lọ si Jerusalem. Ọba to ba fẹ fọnrere Islam lori oye ko lọ si Mẹka. Ade Yoruba ni gbogbo wa de.”

Olowu ti ilu Kuta wa ke si Iba Gani Adams lati pe fun atunse awọn Ọba ilẹ Yoruba ti wọn ko asa ati iṣese ilẹ Yoruba danu

Ṣaaju, lasiko ti ayẹyẹ ọdun ọsun osogbo ti ọdun 2024 lọ lọwọ, Ọba Jimoh Olanipekun, Ataoja ti ilu Osogbo ti pe fun iṣọkan laarin awọn oniṣẹṣe ki aṣa ati iṣe ilẹ Yoruba ma baa parun.

Ọba Jimoh Olanipekun tun parọwa si ijọba apapọ ati ti ipinlẹ lati tun ọrọ asa ilẹ̀ Yoruba to ti fẹ́ di ohun igbagbe gbe yẹ wo.

Ẹ jẹ kí Ogunjọ Oṣu Kẹjọ jẹ ọjọ ayajọ ọdun isẹse nilẹ Yorùbá- Iba Gani Adams

Iba Gani Adams pe fun sisọ ogunjọ oṣu kẹjọ ọdọdun gẹgẹ bii ọjọ ayajọ ọdun iṣẹse ki aṣa Toruba ma ba le parun

Bakan naa ni Aarẹ tun gbe oriyin fun Ogbeni Rafiu Aregbesola to ti fi igba kan ri jẹ Gomina Ipinle Osun fun igbesẹ akin to gbe lasiko n to ṣe ìjọba rẹ nipinle Osun lati ya Ogunjọ oṣù Kẹjọ ọdọdun sọ tọ fun ayajọ ọdun isẹs

Iba Gani Adams tun tesiwaju ninu ọrọ rẹ wi pe, asiko yii lo yẹ ki ilẹ Yoruba ko dìde si asa wọn lati le fi doju kọ isoro to n doju kọ ilẹ Yoruba lasiko yii.

Gani Adams tun salaye wi pe, ki awọn Gomina ilẹ Yoruba ko dide si asa Yoruba ati wi pe, ki wọn ko se ara wọn lọkan lati le da asa ilẹ Yoruba pada, kii Yoruba le bọ loko ẹru.

Gani Adams tun pe fun isọkan awọn Ọba ilẹ Yoruba lati le se ara wọn lọkan ati lati le da asa ilẹ Yoruba pada ki isoro toun doju kọ ọmọ Yoruba ko ba le lọ si oko igbagbe.

Gani Adams parọwa si gbogbo ọmọ Yoruba nile loko lati fi ọwọ so ọwọ pọ ki ohun to ti kuro ni ilẹ Yoruba ko le di dida pada.

Gbogbo ọrọ yii lo waye lakoko ayẹyẹ asekagba ọdun ọsun osogbo ti ọdun 2024 yii.