Iléẹjọ́ tó ga jùlọ yóò bẹ̀rẹ̀ àgbéyẹ̀wò lórí bóyá Trump lè dupò ààrẹ America

Ile ẹjọ to ga julọ ni America sọ pe awọn yoo joko gbẹjọ kan to lamilaka lori boya Donald Trump le dije dupo aarẹ.

Awọn adajọ agba ile ẹjọ naa sọ pe awọn ṣetan lati gbọ ẹjọ kotẹmilọrun ti Trump pe tako idajọ ile ẹjọ to gajulọ nipinlẹ Colorado to sọ pe ko lẹtọ lati dupo aarẹ lọdun 2024.

Ni oṣu Keji ọdun yi ni wọn yoo gbẹjọ naa ti idajọ ti wọn ba si gbe kalẹ yoo fẹsẹ rinlẹ jakejado America.

Awọn igbẹjọ kan lawọn ipinlẹ meloo kan to ṣe pe wọn gbe kalẹ lati tako ifayegba Trump ko dupo aarẹ lori ẹsun pe o lọwọ ninu iwọde kan ti wọn ṣe si ile aṣofin America lọdun mẹta sẹyin.

Ọrọ ti wọn fẹ tu koko rẹ ni boya atunṣe ofin kan to waye nigba ogun abẹle le jẹ okunfa ki Trump fi ma le kopa ninu idibo naa.

Ipinnu ileẹjọ to gaju lọ yi lati ṣagbeyẹwo ẹjọ Trump waye lẹyin ti awọn kọmiṣana feto idajọ ipinlẹ mẹtadinlọgbọn pawọpọ kọwe pe ki ile ẹjọ yi wọgile idajọ ile ẹjọ Colorado to ni ki Trump ma dije.

Ninu iwe ipẹjọ yi, wọn ni yiyọ orukọ Trump kuro ninu awọn to le dije dupo aarẹ yoo da wahala silẹ.

Wọn sọ pe ''Lae si ani ani, yoo da wahala silẹ ninu eto idibo ti yoo gberasọ ni ọsẹ mẹta si asiko yi''

''Yatọ si eleyi,yoo doju ojusẹ ile aṣofin, ijọba ipinlẹ ati awọn ile ẹjọ bolẹ''

Ki lofin America sọ nipa ẹni ba ṣagbatẹru iditẹgbajọba?

Atunṣe ikẹrinla ti wọn mu ba iwe ofin America fofin de ''ẹnikẹni to ba lọwọ ninu iwa iditẹgbajọba lati le dije du ipo tabi ko di ipo ijọba apapọ mu'' ṣugbọn awọn agbẹjọro Trump sọ pe ọrọ yi ko kan aarẹ.

Awọn agbẹjọro rẹ fikun pe ''idajọ ile ẹjọ Colorado yi tunmọ si pe ọgọrọ ni wọn yoo fofin de lati ma le dibo ni Colorado ti eleyi si le mu ki ọkẹ aimọye padanu anfaani lati dibo jakejado America to ba di itẹwọgba labẹ ofin''

Bakan naa ni Ọgbẹni Trump ti kọwe ipẹjọ tako igbesẹ awọn oṣiṣẹ eleto idibpo to wa ni Maine ti awọn naa fẹ yọ orukọ rẹ kuro lori iwe idibo.

Lẹyin ti wọn gbe idajọ yi kalẹ lọjọ Ẹti, akọwe ijọba Colorado Jena Griswold sọ pe oun ti fontẹ lu iwe idibo fun idibo aarẹ to n bọ lọna ati pe orukọ Trump wa nibẹ.

Idibo abẹle ti yoo waye ni ipinlẹ kọọkan ni yoo jẹ ki wọn le mọ boya oludije ipo aarẹ yoo le kopa ninu idibo ti yoo waye ni oṣu Kọkanla ọdun.

Oṣu kẹta ni wọn yoo bẹrẹ idibo abẹle yi ni Colorado to ṣe deede igba ti ireti wa pe idajọ ẹjọ kotẹmilọrun ti Trump pe yi yoo jade.

Arabinrin Griswold sọ ninu atẹjade kan pe ''ile ẹjọ to ga julọ ti gba lati joko lori igbẹjọ naa orukọ Trump yoo si wa lori iwe idibo nitori eyi''

Idajọ to waye ni Colorado jẹ igba akọkọ ti wọn yoo fi iyipada ikẹrinla si iwe ofin America ṣe atẹgun lati le yọ orukọ oludije ipo aarẹ kuro lori iwe idibo.

Igba akọkọ naa ree ti ile ẹjọ to ga julọ ni America yoo ṣagbeyẹwo alaye lori ohun ti abala ofin yi tunmọ si.

Trump ni o lewaju labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Republican to si n palẹmọ lati koju aarẹ Joe Biden nigba keji ninu idibo oṣu Kọkanla.

Awọn ileẹjọ ni ipinlẹ Minnesota ati Michigan ti wọgile igbiyanju lati yọ ọwọ Trump lawo ninu idibo aarẹ.

Awọn ẹjọ mii to fi mọ ti ipinlẹ Oregon ṣi wa ni ipamọ.

Awọn adajọ ileẹjọ to ga julọ ni adajọ mẹta ninu wọn ti Trump yan sipo lasiko to wa lori oye gẹgẹ bi aarẹ America.