You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Wo Gabriel Attal ọ̀dọ́mọkùnrin ẹni ọdún 34 tó di Olóòtú ìjọba orílẹ̀-èdè France
Ọdọmọkunrin ẹni ọdun mẹrinlelọgbọn, Gabriel Attal ti di olootu ijọba orilẹ ede France bayii.
Aarẹ orilẹ ede naa, Emmanuel Macron lo yan Attal si ipo naa pẹlu ero rẹ lati sọ ìṣèjọba rẹ ji.
Ni ẹni ọdun mẹrinlelọgbọn, Ọgbẹni Attal ni Olootu ijọba to kere julọ ninu itan orile-ede France.
Ọgbẹni Attal ti gba ipo olootu ijọba orilẹ ede France to kere julọ mọ Laurent Fabius ti ẹgbẹ Socialist to jẹ olootu orilẹ ede naa lọdun 1984 leni ọdun mẹtadinlogoji.
Attal rọpo Èlisabeth Borne to kọwe fipo silẹ gẹgẹ bi Olootu ijọba France lẹyin ọdun kan ati oṣu mẹjọ ni ọfiisi.
Borne tiraka ni ipò rẹ lasiko to fi wa lori aleefa tori awọn ọmọ ẹgbẹ rẹ ko pọ to nile aṣofin.
Minisita eto ẹkọ ni Attal jẹ ki o to di olootu ijọba France bayii.
Didari orilẹ ede France fun eto idibo ile igbimọ aṣofin ilẹ Yuroopu loṣu kẹfa ọdun yii wa lara awọn iṣẹ to wa niwaju Attal.
Oludamọran lasan ni Attal jẹ nile iṣẹ ijọba to n ri si eto ilera, amọ ojulowo ọmọ ẹgbẹ oṣelu Socialist ni i ṣe.
Oun tun ni "gay" akọkọ ti yoo di ipo olootu ijọba mu.
Ninu ọrọ rẹ nipa iyansipo Attal, aarẹ Macron ni "mo ni igboya pe o koju osunwon lati ṣe itaji awọn akanṣe eto ijọba ti mo kede."
Attal naa fesi pe "orilẹ ede France ko ba ifasẹyin dọgba bi ko ṣe isọdọtun ati igboya."