Israel pàṣẹ fún àwọn èèyàn Gaza láti fí ilé wọn sílẹ̀ ṣáájú ikọlù tí yóò wáyé

Ileeṣẹ ologun Israel ti sọ fawọn olugbe agbegbe meje to wa ni Gaza Strip pe ki wọn wa bi gba lọ ṣaaju ki awọn to bẹrẹ ikọlu si awọn ibudo ọmọ ogun Hamas.

Olugbe agbegbe naa kan to ba BBC sọrọ s pe niṣe lawọn olugbe agbegbe yi n sa asala kuro ni ile wọn lati wa aabo lawọn ile ẹkọ kan ti ajọ isọkan agbaye kọ.

O kere tan eeyan to le ni igba lo ti ku tawọn to le ni ẹgbẹrun kan naa si farapa lẹyin ti ikọ Hamas ṣe ikọlu si Israel.

Ikọlu yi lo lagbara julọ laarin ọdun meloo kan ti awọn mejeeji ti n koju ija si ara wọn.

Israel ti ṣe ikọlu si awọn ibudo ologun Hamas

Awọn ọmọ ogun ofurufu Israel ti fi fidio kan ṣọwọ to ṣe afihan bi awọn ado oloro wọn ṣe balẹ lori awọn ile kan ni Gaza.

Wọn sọ pe awọn ọmọ ogun Hamas lo wa ni awọn ile wọnyi.

Bẹẹ naa ni Israel sọ pe awọn baalu awọn ko ni jawọ lati maa ṣe ikọlu si Hamas lara awọn eto ogun to wa nilẹ.

Bẹẹ la tun gbọ pe ikọlu waye lawọn aaye mii bi ile alaja giga Watan Tower to wa laarin aaye karakata Gaza.

Saaju asiko yi ni a jabọ pe o kere tan eeyan 250 lo padanu ẹmi wọn ni Gaza ti awọn ọmọ ilẹ Palestine to le ni ẹgbẹrun kan si farapa lẹyin ikọlu ti Israel ṣe si wọn.

Ikọlu to n lọ lọwọ yi lo buru julọ ninu akọsilẹ lẹnu lọọlọ yi.

O bẹrẹ nigba tawọn ọmọ ogun Hamas yọ wọle mọ Israel larra lagbege Guusu ilẹ naa ti awọn ọmọ ogun ofurufu si ṣatilẹhin wọn pẹlu ado oloro.

Awọn ọmọ ogun ri bi ko awọn ọmọ Israeli ati ologun wọn lẹru ninu ikọlu yi.

Eyi mu ki Israel fesi pada pẹlu ikọlu ti wọn naa.

Ado oloro ti wọn ju lu Gaza mu ẹmi eeyan 232 lọ tawọn ẹgbẹjọ si farapa gẹgẹ bi awọn oṣiṣẹ ilera ṣe wi.

Ìjà tuntun bẹ̀rẹ̀ láàrin Israel àti Palestine ìbí tí ọ̀rọ̀ dé dúró réè

O kere tan eeyan aadọjọ ni iroyin lo ti padanu ẹmi wọn ti awọn to le ni ẹgbẹrun kan mii si ti farapa lẹyin ti awọn ọmọ ikọ Hamas ṣe ikọlu si Israel.

Ikọlu yi lo ṣi lagbara julọ ninu akọsile eyi ti wọn n ṣe si Israel lẹnu lọọlọ yi.

Awọn ọmọ ogun Hamas yi ti wọle si iwọ Guusu Israel pẹlu iranwọ awọn nkan ija ogun ti ikọ naa fi n sọwọ loju ofurufu,

Awọn ikọ Hamas naa si ti n ji awọn ọmọ ogun Israel ati araalu gbe.

Israel fesi pada pẹlu nkan ija ogun oloro tawọn naa fi sọwọ gbaofurufu ti o si ṣeku pa awọn ọmọ ilẹ Palestine ijilenigba din mẹjọ 232 tawọn ẹgbẹjọ si farapa gẹgẹ bi nkan tawọn oṣiṣẹ ilera ṣe sọ.

Olootu ijọba Israel Benjamin Netanyahu sọ pe ipo ogun ni awọn wa bayii ati pe Hamas to n dari agbegbe Gaza yoo gburo awọn.

Ileeṣẹ ologun Israel ti kesi awọn ọmọ ogun rẹ ti ireti si wa pe wọn yoo ṣe ikọlu ilẹẹlẹ si awọn ọmọ ogun Hamas.

Ikọlu yi lo lagbara julọ ni bi nkan bi ọdun meloo kan sẹyin yala lagbegbe Gaza tabi ni ori ilẹ awọn Israel.

Niṣe la ri bawọn ọmọ ogun Palestine ṣe n sọda gba ibode idina ti Israeli fi lelẹ wọ ọdọ wọn lowurọ oni.

Eyi n waye lasiko kanna ti Hamas n ju ado oloro lati Gaza si Israel ti imi ninu awọn ado olor yi si n de awọn ilu bi Tel Aviv ati Jerusalem.

Ko si iroyin pato bayii lori iye awọn ọmọ ogun Hamas to ribi fo ibode Israel tọ jẹ ọkan lara awọn ibode ti wọn ṣọ julọ lagbaye wọle.

Israel sọ pe awọn baalu ogun rẹ ti ju ado oloro si awọn aaye Hamas ni Gaza ti wọn si lawọn ribi ṣawari awọn ibudo ọmọ ogun Hamas mẹtadinlogun.

Awọn ado oloro tawọn ọmọ ogun Israel sọ lu ilu Gaza mu ki ile alaja mọkanla kan dawo ni Gaza.

Ibi ile yi lawọn ileeṣẹ redio Hamas ti n kede iroyin jade,

Ajọ ẹlẹyinju aanu Medecins Sans Frontieres, sọ pe nọọsi kan ati awakọ ti wọn fi n gbe alaare kan padanu ẹmi wọn ninu ikọlu ado oloro ti Israel ju lu ile iwosan meji ni Gaza.

Israel sọ pe awọn ọmọ ogun Hamas ji awọn Jew gbe

Iroyin to tẹ BBC lọwọ sọ pe awọ ikọ Hamas naa ti ji awọn aimọye ọmọ ogun Israel ati awọn araalu ninu ikọlu to n waye lọwọ laarin ikọ mejeeji.

Awọn kan sọ pe ni awọn ilu kan to sunmọ agbegbe Gaza ni wọn ti ri wọn ko.

Amọ awọn alaṣẹ Israel ti sọ pe ko sootọ ninu iroyin yi tohun ti pe a n gbọ pe ọgagun agba ilẹ Israel kan wa lara awọn ti ọwọ Hamas tẹ.

Hamas n sọ pe awọn ri awọn eeyan mẹtalelaadọta mu ninu ogun yi.

Ileeṣẹ ologun Israel ko fesi pada lati yannana ọrọ lori nkan ti Hamas sọ yii