Ìjọba, ẹ lu gbogbo báràkì ilégbèé ọlọ́pàá ní gbàǹjo - Ilé aṣòjú-ṣòfin

Ile igbimọ aṣoju-ṣofin niluu Abuja ti ke sí ijọba apapọ pe ki o lu gbogbo báráákì awọn ọlọpaa lorilẹ ede Naijiria ni gbanjo.

Awọn aṣofin naa ni igbesẹ yii jẹ ọna kan gboogi lati mu igbe aye idẹrun ba awọn ọlọpaa.

Awọn aṣoju-ṣofin fẹnu ko lori ọrọ yii lẹyin ti aṣofin kan, Murphy Omoruyi to wa lati ipinlẹ Edo mu aba naa wa.

Họnọrebu Omoruyi lara awọn kókó to wa ninu ofin ileeṣẹ ọlọpaa keji.

ọdun 2020 eleyii ti Ààrẹ Muhammadu Buhari buwọlu ni lati ṣètò igbe-aye irọrun fawọn ọlọpaa.

"Ijọba ti na owo to le ni N5bn lori atunṣe bárákì ọlọpaa laarin ọdun 2019 sí 2022

Họnọrebu Omoruyi ni iṣoro aisi ilegbe to bojumu si n koju awọn ọlọpaa titi di oni.

Omoruyi sọ pe "ijọba na owo to le ni biliọnu marun ùn naira lori atunṣe báráákì awọn ọlọpaa laarin ọdun 2019 sí 2022.

Amọ, pabo naa ni gbogbo rẹ jasi.

Ọpọ eeyan lo ti n beere fun ọlọpaa àwùjọ to mọ nipa agbegbe to ti n ṣiṣẹ daadaa.

Nitori naa, tàwọn ọlọpaa ba n gbe laarin awọn eeyan yatọ sí baraaki yoo ṣe iranwọ fun ọlọpaa àwùjọ, ati pe yóò jẹ ki eto abo to tun f'ẹsẹ mulẹ ṣii.

Fífi awọn ọlọpaa sí baraaki lati maa gbe jẹ aṣa awọn ijọba oyinbo amunisin eleyii ti awọn gan an ti kọ silẹ.

Lonii ni Naijiria, ogiri ile ti ọpọ ọpọ olopaa n gbe ti san, bẹẹ ni orule ọpọ ile bẹẹ ti n joo."

Aṣofin Omoruyi sọ pe ara nkan bayii lo jẹ ki iwa ibajẹ tàwọn eeyan maa n sọ nipa awọn ọlọpaa ni Naijiria wọ pọ.

''Aisi igbaye gbadun awọn ọlọpaa ko fun wọn ní iwuri lati ṣiṣẹ wọn daadaa''

Họnọrebu Omoruyi ni fifun awọn ọlọpaa lowo ilegbe lati rọ po baraaki ti wọn n gbe yoo jẹ anfaani nla fun gbogbo oṣiṣẹ ọlọpaa.

Lẹyin ti wọn gba aba wọle, ile rọ ẹka ijọba to n ri sí ọrọ abẹnu ati ileeṣẹ ijọba to n ri sí ọrọ ọlọpaa lati ṣiṣẹ pọ pẹlu ajọ BPE lati ṣe oṣuwọn iye ti awọn baraaki ọlọpaa kaakiri Naijiria le to.

Ile wa gbe igbimọ kan dìde lati ṣe afikun ofin atunṣe ileeṣẹ ọlọpaa ni Naijiria.

Bakan naa ni ile pàṣẹ fun igbimọ olutọpinpin lati rí pe owo ti ijọba ya sọtọ fun atunṣe baraaki ọlọpaa jẹ lílò fún nkan mii.

Ile wa rọ igbimọ naa lati ṣeto owo ilegbe fáwọn ọlọpaa to wa lẹnu iṣẹ, ki igbimọ naa si ri wí pe igbimọ to n ri sí ọrọ ọlọpaa tọ pínpín rẹ pe o wa sí imuṣẹ.

Ile sọ fun igbimọ naa lati jabọ laarin osẹ mẹrin.